"Ìjọba, olùkọ́, àwọn ọmọ wa ń fi ẹsẹ̀ gbálẹ̀, tẹ̀lé Eléégun kiri, ẹ ṣí ilé ẹ̀kọ́ padà"

Ilé ẹ̀kọ́ kan tí wọn ti pa nipinlẹ Oyo

Oríṣun àwòrán, OyoStategovernment

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ọ̀pọ̀ òbí àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó wà làwọn ilé ẹ̀kọ́ alákọ́bẹ̀rẹ̀ àti ti girama to jẹ ti ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo lo tí ń fapa janu báyìí.

Èyí kò si sẹ́yìn bí ilé ẹ̀kọ́ wọn ṣe wá ní titipa láti bíi ọ̀sẹ̀ mẹta sẹ́yìn.

Bẹẹ si ni àwọn akẹẹgbẹ́ wọn làwọn ilé ẹ̀kọ́ aladani ń lọ sílé ẹ̀kọ́ tiwọn.

Bi ẹ kò bá gbàgbé, ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ nílẹ̀ wa, NUT, ẹka tí ìpínlẹ̀ Oyo, lo pàṣẹ pe ki wọn gbé àwọn ilé ẹ̀kọ́ ìjọba tipa torí eto aabo to mẹhẹ.

Ìkéde náà lo wáyé lásìkò tí ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ náà gùnlé ifehonuhan nipinlẹ Oyo lórí báwọn agbébọn ṣe kó àwọn olùkọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n nilu Esinele àti Yawota nijoba ìbílẹ̀ Oriire nipinlẹ Oyo.

Èyí si lo mú kí BBC News Yorùbá bá àwọn òbí àti olùkọ́ sọ̀rọ̀ láti mọ ipa tí ìgbésẹ̀ títí ilé ẹ̀kọ́ ìjọba pa ń ní lára wọn.

"Inú wa kò dùn sí báwọn ọmọ wa ṣe ń fi ẹsẹ rìn igboro, nígbà táwọn akẹẹgbẹ́ wọn nílé ẹ̀kọ́ aladani ń kẹ́kọ̀ọ́"

Awọn obi ti o ba akọroyin ile iṣe BBC News Yorùbá sọrọ ṣalaye wi pe, gẹgẹ bi obi, kii ṣe idunnu awọn bii awọn ọmọ awọn ti n fẹsẹ rin kiri adugbo.

‎"Awọn ọmọ ti tẹle awọn elegun lọ tan, ti wọn ba wa ni yara ikẹẹkọ wọn, iwọnba ni akoko ti wọn yoo fi tele Egungun lẹ́yìn.

Ti wọn ba tie fẹ tẹle eleegun, yóò ni akoko igba ti wọn yoo ṣe bẹ́ẹ̀, sugbọn lọwọ bayii, wọn ti sọ ile awọn eleegun di ile báyìí.

‎" Lootọ a ko le ni ki àwọn olùkọ́ máṣe yàn isẹ lòdì, ṣugbọn ki awọn olukọ ati ijọba wo ṣe fun ara wọn, gbogbo nkan ti awọn olukọ fẹ. bíi eto aabo to péye, ní ki ijọba naa pese rẹ fun wọn".

"Ọwọ́ tó bá dilẹ ni Èṣù ń bẹ lọwẹ, ẹ bá wà gba àwọn ọmọ tó wà ní akata ajínigbé padà, kí àwọn tó wà nile, le padà sile ẹ̀kọ́"

Obi miran to bá BBC News Yorùbá sọ̀rọ̀, Peter Owoyemi, ní o ṣe pataki ki awọn ọmọ pada si ile ẹkọ wọn, nitori awọn ọmọ yii ni ọjọ ọla awọn obi wọn.

‎Owoyemi ni awọn ọmọ ati awọn olukọ to wa ni àhámọ́ awọn agbébọn naa jẹ obi ati ọmọ awọn kan, o si rọ ijọba ipinlẹ Oyo lati pese ààbò to yẹ ni gbogbo ile ẹkọ jakejado ipinlẹ Oyo.

‎Owoyemi ni "ọmọ meji ni mo ni nile ẹkọ girama, awọn ọmọ yii náà ni ọjọ ọla wa.

Àmọ́ ó ṣe ní laanu pe awọn ile ẹkọ wa wa ni titipa, ọwọ to bá si dilẹ, ni Eṣu n bẹ niṣẹ.

A bẹ ìjọba pe ko bá wà wa awọn ọmọ to wa pẹlu awọn ajinigbe ki awọn ọmọ to joko sile le pada sẹnu ẹkọ wọn".

Laipẹ, laijinna, awọn ile ẹkọ yoo wa ni ṣiṣi padà - Alága ẹgbẹ́ Olùkọ́ ṣèlérí

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

‎Hassan Abimbola, tíí ṣe alaga ẹgbẹ olukọ ni ipinlẹ Oyo ṣalaye pe àwọn olùkọ́ tí setan lati pada si ẹnu ìṣẹ ṣugbọn, wọn gbọdọ tẹlẹ awọn ilana kan.

‎Hassan ni "Láti olu ọ́ọ́fìsì awọn olukọ ni Abuja ni wọn ti kede wi pe ka yan iṣẹ lodi, ìjọba ti gbé awọn ijiroro wa ro, wọn si ti yanju awọn ohun kọọkan, pàápàá julọ, àwọn ohun to niise pẹlu eto aabo.

‎"Gẹgẹ bi ileri ti ijọba ṣe fun wa, gbogbo ile ẹkọ to wa ni igberiko ati awọn to wa ni aarin ilu ni eto aabo to peye yoo wa.

O si da wa loju wi pe dundun ni ọsan yoo so, laip, laijinna, awọn ile ẹkọ wa ma wa ni ṣiṣi padà.

A ti gbé ₦8.7bn kalẹ láti ra àwọn ohun eelo ikẹkọọ, ẹyin olùkọ́, ẹ padà sile ẹ̀kọ́ - Ìjọba Oyo

‎Ijọba Ipinlẹ Oyo ti rọ awọn oṣiṣẹ ile ẹkọ alákọ́bẹ̀rẹ̀ ati girama to n yansẹ lodi láti wọ isẹ padà.

Ìjọba Oyo ni òun ti ya owo to N8. 7bn sọtọ lati ra awọn ohun elo ikẹẹkọ fun awọn ile ẹkọ ni ipinlẹ Oyo.

‎Ijọba ipinlẹ Oyo ninu atẹjade kan ti Kọmisona fun eto iroyin, ọmọoba Dotun Oyelade fi síta, lo fọwọ ẹbẹ naa lede.

‎Oyelade ṣalaye wi pe, lootọ idi ti awọn olukọ fi yansẹlodi nipinlẹ Oyo jẹ idi to lẹṣẹ nlẹ, ṣugbọn ọpọ ipalara ni aisi ni ile ẹkọ ń ṣe fun awọn ọmọ ile ẹkọ to wa nile.‎

‎O ni ijọba ń sá gbogbo agbara rẹ lati ri wi pe, awọn akẹkọọ ati olukọ to wa ni àhámọ́ awọn agbébọn gba itusilẹ laipẹ.

‎Tẹ ba gbagbe, ọjọ kinni oṣu kẹfa ni awọn olukọ nipinlẹ Ọyọ ti bẹẹrẹ si ni wosẹ niran nitori bii awọn afurasi agbébọn ṣe ṣọṣẹ ni agbegbe Ahoro Esinele ati Yawota to wa ni ijọba ibilẹ Orire nipinlẹ Ọyọ.