Ṣé lóòótọ́ ni NYSC fẹ́ẹ́ pín àwọn agùnbánirọ̀ tí wọ́n jígbé ní Imo padà sí ẹkùn Gúúsù Ìwọ̀-Oòrùn? Ohun tí a mọ̀ rèé

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Latigba ti awọn agunbanirọ ogun ti awọn agbebọn jigbe nipinlẹ Imo ti gba itusilẹ, ti wọn si ti pada si ipinlẹ Oyo, ni awọn obi awọn agunbanirọ naa ti n rọ ajọ NYSC lati da wọn pada si ẹkun Guusu Iwọ-Oorun.

Awọn obi naa n sọ pe aabo to pe ye wa ni ẹkun Guusu Iwọ-Oorun ju awọn agbegbe yooku lọ nilẹ Naijiria, ati pe abojuto gidi yoo wa fun wọn.

Lara awọn obi awọn agunbanirọ ọhun sọ pe idunnu nla lo jẹ fun wọn pe wọn ko foju sunkun awọn ọmọ wọn, latari pe wọn n lọ sin ilẹ baba wọn.

Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ajọ NYSC ko tii fidi rẹ mulẹ, ṣugbọn sibẹ, a gbọ pe igbagbọ wa wi pe wọn yoo pin awọn akẹkọọjade tuntun naa si gbogbo ipinlẹ mẹfa to wa lẹkun Guusu-Iwọ-Oorun.

Ọkan lara awọn akẹkọọjade ti wọn jigbe naa to ba BBC sọrọ, sọ pe awọn ṣi n foju sọna fun NYSC lati pin awọn pada sibi ti aabo yoo ti wa fun awọn.

Akẹkọọjade ọhun ti ko fẹẹ darukọ rẹ sọ pe iriri nla ni ijinigbe naa jẹ foun, to si loun ko le gbagbe lailai.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe, "A ṣi wa ni kampu, o digba ti a ba ṣetan ka too mọ boya wọn yoo pin wa si ipinlẹ ti a n fẹ lootọ," o sọ bẹẹ fun BBC.

Obi kan naa to tun sọrọ, ṣalaye pe NYSC ti fun awọn ọmọ wọn laaye lati yan ipinlẹ ti wọn ba fẹ lati lọ ṣeto agunbanirọ wọn.

"NYSC ti fun wọn lanfaani lati mu ipinlẹ kan ni ẹkun Guusu Iwọ-Oorun Naijiria, lati le tẹsiwaju ṣiṣe agunbanirọ nibẹ," obi naa sọ bẹẹ.

Àwọn agùnbánirọ̀ tí wọ́n gba ìtúsílẹ̀ ti dé sí ìlú Ibadan

Gbogbo awọn agunbanirọ ti wọn jigbe nipinlẹ Imo, ṣugbọn ti wọn gba itusilẹ ni wọn ti de siluu Ibadan, ipinlẹ Oyo bayii.

Olu ileeṣẹ ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti a mọ si DSS, eyi to wa lagbegbe Aleshinloye nijọba ibilẹ Guusu-Iwọ-Oorun Ibadan ni wọn ko gbogbo awọn agunbanirọ ọhun lọ, ni kete ti wọn de siluu Ibadan.

Awọn agunbaniro ogun naa lo wa lara awọn ọgbọn ti wọn kuro niluu Ibadan, lati maa lọ si ipinlẹ Abia, nibi ti wọn yoo ti sin ilẹ baba wọn, ko to di pe awọn agbebọn da wọn lọna lopopona Owerri si Onitsha, iyẹn niluu Umunoha, ipinlẹ Imo.

Ọjọ kinni, oṣu Kẹwaa, 2026 ni awọn agbebọn da awọn agunbanirọ naa lọna ninu bọọsi meji ọtọọtọ ti wọn fi n rin irin ajo.

Mẹwaa ninu awọn agunbanirọ naa ni wọn moribọ, nigba ti wọn sa asala fun ẹmi ara wọn ninu igbo, ti onikaluku wọn si gba inu igbo naa de ibi ti wọn n lọ.

Ọjọ meje gbako ni awọn agunbanirọ naa lo lahaamọ awọn agbebọn wọnyi, ko to di pe wọn lanfaani lati gba itusilẹ.

Ọjọru, ọsẹ yii ni awọn agunbanirọ ọhun de si ọgba awọn ọtẹlẹmuyẹ, ti awọn obi wọn si lọ sibẹ lati pade wọn.

Aṣoju awọn obi awọn agunbanirọ naa ni awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ti a mọ si DSS yii gba laaye lati wọle sinu ọgba wọn, nigba ti awọn obi yooku duro siwaju ita.

Iroyin ti a gbọ ni pe miliọnu lọna aadọta naira ni awọn agbebọn naa n beere lọwọ mọlẹbi agunbanirọ kọọkan, ṣugbọn ti wọn pada fẹnuko lori miliọnu marun-un niara, ẹnikọọkan.

Olubadan kéde ìtúsílẹ̀ àwọn agùnbánirọ̀ ọ̀hún

Ninu awọn obi awọn agunbanirọ wọnyi ni wọn ti lọ rawọ ẹbẹ si Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Rashidi Adewolu Ladoja lati dide iranlọwọ, iyẹn lọjọ Abamẹta to kọja.

Latigba naa ni kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Oyo, Olugbenga Abimbola ati Ọba Sefiu Adeyeri, Aseyin tiluu Iseyin naa ti dide lori ọna ti wọn yoo gba lati tu awọn agunbanirọ wọnyi silẹ lahaamọ awọn agbebọn.

Olubadan, Ọba Ladoja lo pada kede wi pe awọn agunbanirọ ọhun ti gba itusilẹ, iyẹn lẹyin to ti ri ẹri gba lọdọ Gomina Hope Uzodinma ti ipinlẹ Imo.

"Awọn agunbanirọ ti wọn jigbe naa ti ri itusilẹ gba. Gomina ipinlẹ Imo, Hope Uzodinma, lo fidi rẹ mulẹ fun mi lasiko ti a jọ sọrọ lori foonu ni nnkan bi agogo marun-un irọlẹ," Ladoja sọ bẹẹ ninu atẹjade ti Adeola Oloko to jẹ agbẹnusọ rẹ fi lede.