Obìnrin tí wọ́n ṣàwárí Ebola lára rẹ̀ ní Nàìjíríà ti balẹ̀ sí Switzerland fún ìtọ́jú tó péye

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba Switzerland ti sọ pe awọn eeyan orilẹ ede rẹ ko si ninu ewu itankalẹ aarun Ebola lẹyin ti eeyan ti ọmọ orilẹ ede naa ti wọn ṣawari Ebola lara rẹ ni Naijiria balẹ si Switzerland.
Ijọba naa sọ pe ọjọ Aje ni wọn gbe obinrin naa to ni ẹya Ebola Bundibugyo ati ọkọ rẹ balẹ si orilẹ ede naa ti obinrin naa si ti wa nile iwosan Geneva University Hospital nibi to ti n gba itọju.
Wọn ni ọkọ obinrin ọhun, ti awọn mejeeji jọ jẹ ọmọ oniluu, ti wa ni ile iwosan Zurich University Hospital nibi ti wọn ti n mojuto.
Ijọba ni awọn ile iwosan mejeeji ni wọn ni gbogbo ohun elo lati tọju aarun Ebola, ti wọn si ni aabo awọn oṣiṣẹ daju.
Atẹjade ti ijọba Switzerland fi lede sọ pe awọn eeyan orilẹ ede naa ko si ninu ewu lati ko aarun naa nitori wọn tip ese gbogbo ohun to ye lati dena itankale rẹ.
Wọn fi kun pe awọn eeyan naa w ani ilera pipe bayii, ti wọn si maa wa ni aaye ọtọ titi ti ara wọn fi maa fidi rẹ mulẹ pe wọn ti le dara pọ mọ awọn eeyan.
Ni owurọ ọjọ Aje ni ijọba Naijiria kede pe obinrin ti wọn fidi rẹ mulẹ pe o ni Ebola ni wọn ti fi ranṣẹ si orilẹ ede Switzerland lati lọ gba itọju to peye gẹgẹ bi minisita fun eto ilera Naijiria, Muhammad Ali Pate ṣe sọ.
Adari ajọ to n ri si eto ilera agbaye, World Health Organization, WHO tẹka ekun Africa, Ọjọgbọn Mohamed Janabi sọ pe ko si aarun Ebola mọ ni Naijiria bayii pẹlu bi wọn ṣe tig be obinrin naa lọ si ilẹ okeere.
Obinrin Uganda, ẹni ọdun mejilelogoji, ẹni ti Naijiria fidi rẹ mulẹ pe o ni Ebola nigba to wa Naijiria leyin to kuro ni Uganda.
Awọn alaṣẹ ṣi n ṣewadii ibi ti obinrin naa ti ko aarun naa bi ijọba Uganda ṣe n se agbejade awọn ilana tuntun mii jade lati fi dena itankale aarun Ebola.
Ileeṣẹ eto ilera Switzerland ni awọn n ṣiṣẹ pelu awọn ile iwosan ti obinrin naa ati ọkọ rẹ wa, tawọn si n mojuto wọn.
Ile iwosan mejeeji yii ni ijọba Switzerland ti ya sọtọ lati ọdun 2019 lati maa mojuto Ebola.
Bí arábìnrin tó kó Ebola wọ Nàìjíríà ṣe rìnrìnàjò afẹ́ lọ sí Uganda, àtàwọn ohun míràn tí a mọ̀ nípa àrùn Ebola àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà láti ọdún 2014
Ẹniyan akọkọ ti Naijiria tii fidi rẹ mulẹ p e o laarun Ebola lorilẹede Naijiria lati igba ti aarun ọhun ti bẹrẹ loṣu karun un ọdun yii lẹkun ila oorun Africa ni wọn sọ wi pe o jẹ iyawo oṣiṣẹ ileeṣẹ aṣoju ijọba ilẹ okeere kan to rin irinajo lọ gba afẹ ni olu ilu Uganda.
Dokita agba ajọ to n mojuto ajakalẹ arun ni Africa, Africa CDC lo sọ eyi fun BBC.
Dokita Jean Kaseya to jẹ adari ajọ Africa CDC ṣalaye pe Ọmọ orilẹede Uganda ni arabinrin naa, ṣugbọn ilu Abuja lo fi ṣe ibugbe, nibẹ lo si ti dubulẹ aisan fun ọjọ mẹta lẹyin to de si olu ilu Naijiria ni ọjọ kẹta oṣu kẹwaa.
Minisita fun eto ilera lorilẹede Naijiria, Muhammad Ali Pate pẹlu fi idi rẹ mulẹ pe ọsẹ meji abọ ni arabinrin ẹni ọdun mejilelogoji naa lo ni ilu Kampala, o si duro fun wakati meji ni olu ilu Ethiopia lasiko to fi n pada bọ ni Naijiria.
O ni "ara rẹ ti n balẹ"
O fi kun un pe kii ṣe gbogbo awọn mẹrẹrinlelogoji to farakinra pẹlu arabinrin naa ni wọn fi ara kan an pẹkipẹki, bẹẹni ko tii si eyikeyi ninu wọn to tii ni ami pe aisan naa ti wọ ara wọn.
Bawo ni irinajo obinrin naa ṣe jẹ?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dokita Kaseya sọ wi pe ọjọ kẹfa oṣu kẹwaa ni arabinrin naa kọkọ fi ami han pe aarun naa wa lara rẹ.
"O lọ si ileewosan aladani akọkọ ni ireti pe aisan iba lo n ba oun finra, o tun lọ si ikeji ki wọn to daa duro si ileewosan keji yii ni ọjọ kọkanla oṣu kẹwaa."
Minisita feto ilera, Pate sọ pe, nigba ti ara rẹ ko yipada ni wọn ke gbajare si awọn alaṣẹ ni ọjọ kọkandinlogun oṣu kẹwaa ti esi ayẹwo rẹ lọjọ keji si fidi rẹ mulẹ pe o ni aarun Ebola.
Ọrọ irinajo alaisan naa di arinyanjiyan pẹlu Uganda

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Alaye ti minisita feto ilera ni Naijiria ati dokita agba fun ajọ to n mojuto ajakalẹ arun ni Africa, Africa CDC ṣe lori bi arabinrin naa ṣe rinrinajo rẹ ko ba awọn alaṣẹ ijọba orilẹede Uganda lara mu rara ni. Wọn ni arabinrin naa ko wa si Uganda rara.
Ninu atẹjade ti wọn fi sita wọn ni ọmọ orilẹede Naijiria ni arabinrin naa ati pe o rinrinajo lọ si orilẹede DR Congo fun ọrọ aje ni, o kan gba orilẹede Uganda kọja ni.
Uganda n faake kọri pe ko si ẹnikẹni to laarun Ebola lorilẹede naa lọwọ yii nitorinaa ko si bi arabinrin naa ṣe le ko arun ọhun nibẹ.
Minisita fun eto ilera ni Naijiria ni awọn oṣiṣẹ ilera ni Naijiria ti n sọrọ pọ pẹlu Uganda, Ethiopia ati ajọ Africa CDC lati fi idi okodoro ọrọ naa mulẹ.
Bakan naa ni Dokita Paseya to jẹ adari agba fun ajọ to n gbogun ti ajakalẹ arun nilẹ Africa, Africa CDC rọ awọn orilẹede Africa lati fi awọn iroyin to ba wa larọwọto wọn to awọn oluwadii leti lati lee yannana bi irinajo arin naa ṣe lọ si ati ibi ti o ṣeeṣe ko ti ko arun naa.



























