À ti tún àwọn ẹ̀rọ̀ BVAS wa ṣe láti dènà kí èèyàn kan lo káàdì ìdìbò ẹlòmíràn nínú ìdìbò gómìna l‘Osun - Alága INEC

Àkọlé fídíò, Àwọn ẹ̀rọ̀ BVAS wa yóò ṣiṣẹ́ dáadáa láti dènà kí èèyàn kan lo káàdì ẹlòmíì nínú ìdìbò gómìna l‘Osun - Alága INEC
À ti tún àwọn ẹ̀rọ̀ BVAS wa ṣe láti dènà kí èèyàn kan lo káàdì ìdìbò ẹlòmíràn nínú ìdìbò gómìna l‘Osun - Alága INEC
Published

Ọjọ kẹẹdogun osu Kẹjọ ọdun 2026 ni eto idibo gomina yoo waye jakejado ipinlẹ Osun.

Koda, ipalẹmọ naa ti doju ọgbagade bayii laarin ẹgbẹ oselu to n kopa ninu idibo naa, to fi mọ ileeọ̀ẹ ọlọpaa ati awọn araalu.

Ipalẹmọ naa ko si yọ ajọ eleto idibo nilẹ wa, INEC, to n se kokari eto idibo gomina naa silẹ bo se kede pe oun ti n saayan lati ri daju pe eto idibo naa kẹsẹjari lai lọwọ magomago idibo ninu.

Eyi si lo gbe alaga ajọ INEC nilẹ wa, Ọjọgbọn Joash Amupitan lọ se abẹwo sipinlẹ Osun lati mọ ibi ti isẹ de duro lori ipalẹmọ fun eto idibo naa.

BBC News Yoruba naa wa nikalẹ lati ba Amupitan sọrọ, ka le mọ ọpọ ipalẹmọ ti ajọ INEC n se lati ri daju pe eto idibo nipinlẹ Osun lọ bo se yẹ.

Alaga ajọ eleto idibo INEC, Joash Amupitan wọ asọ toke tilẹ alawọ miliki, o si de fila alawọ goolu ati sokoleti

"A ti bawọn lọbalọba atawọn eeyan ti ọrọ idibo gomina naa kan, se ipade tori ọrọ ija, janduku ati ipaniyan to n waye"

Nigba to n ba BBC News Yoruba sọrọ, alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Joash Amupitan ni oun wa sipinlẹ Osun lati mọ bawọn osisẹ INEC ti palẹmọ silẹ fun eto idibo naa.

"A ti lọ kaakiri awọn ileesẹ INEC ni olu ileesẹ titi de ẹka ileesẹ wa lawọn ijọba ibilẹ, ka le mọ pe a ti setan feto idibo gomina to n bọ yii.

A ti bawọn lọbalọba atawọn eeyan ti ọrọ idibo gomina naa kan, se ipade tori ọrọ ija, janduku ati ipaniyan to n waye.

A ti bẹ wọn, ba wọn sọrọ pe ibo ko le dara nibi ti ija ba wa tabi ti wọn ti n paayan.

Bakan naa, a ti bawọn agbofinro naa se ipade, lati ri pe gbogbo wahala wọnyi la mu kuro.

A ti gbe igbesẹ lati ri daju pe gbogbo wahala to n waye lo ti dinku, o si maa tun dinku si ni, ko to di ọjọ ibo."

"Awọn kaadi idibo to ti pẹ, ti wọn ti gba lati 2011, ti fọto oludibo to wa lori ẹrọ naa n se idiwọ, awọn onimọ ẹrọ wa ti tun wọn se, ti wọn si ti n sisẹ bayii"

Nigba to n sọrọ lori igbara ajọ INEC lati mu ki eto idibo gomina ipinlẹ Osun kẹsẹjari, Amupitan ni awọn ti lọ se ayẹwo awọn ẹrọ eto idibo lati mọ bi wọn se dangajia si.

"A ti lọ se ayẹwo ẹrọ to n se ayẹwo orukọ oludibo, BVAS wa laarin ilu, eyi ti a n pe ni Mock Accreditation lati mọ bawọn BVAS wa se n sisẹ si.

A fẹ ni idaniloju pe awọn ẹrọ BVA wa maa sisẹ perepere lọjọ idibo bo se yẹ tori bawọn ẹrọ yii ko ba sisẹ daadaa, a ko le dibo.

Awọn ẹrọ yii la maa fi n se ayẹwo orukọ awọn oludibo wo, ki wọn to dibo.

Eyi yoo dena pe wọn n lo akọsilẹ idamọ awọn eeyan kan fun ẹlomiran, a si ri pe awọn ẹrọ naa sisẹ daadaa.

A tun ri pe awọn ti kaadi idibo wọn ti pẹ, ti wọn ti gba lati 2011, ti fọto oludibo to wa lori ẹrọ naa n se idiwọ, awọn onimọ ẹrọ wa ti tun wọn se, ti wọn si ti n sisẹ bayii.

A wa n mu da gbogbo eeyan loju pe INEC ti setan lati se eto idibo gomina nipinlẹ Osun."

Ọjọgbọn AMupitan wa rọ awọn araalu ati oloselu lati mase jẹ ki ija wa lọjọ idibo amọ ki wọn jẹ ki ohun gbogbo lọ nirọwọ-rọsẹ.