'Àwọn dókítà yọ kíndìnrín mi lásìkò iṣẹ́ abẹ ìbímọ'

Oríṣun àwòrán, Zakaria Alhassan
- Author, Abubakar Maccido
- Published
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5
Obinrin kan ni ipinlẹ Gombe ti fẹsun kan ile ile iwosan Gombe State Specialist Hospital pe wọn yọ ọkan lara awọn kindinrin lasiko ti oun ṣiṣẹ abẹ lati fi bimọ ni ile iwosan naa.
Barira Alhassan sọ pe niṣe ni awọn kindinrin oun mejeeji pe pere ki oun to lọ sile iwosan fun iṣẹ abẹ lati bimọ amọ to ni awọn dokita yọ ọkan lara awọn kindinrin oun nigba ti wọn ṣe iṣẹ abẹ naa tan.
Amọ ile iwosan naa ti jiyan ẹsun ti obinrin naa fi kan wọn, wọn ni ẹsun naa ko lẹsẹ nilẹ ati pe Barira ko ni ẹri lati fi gbe ẹsun rẹ lẹsẹ.
Awọn ẹbi Barira sọ pe awọn ayẹwo ti Barira ṣe fi han pe kindinrin rẹ mejeeji pe pere ṣaaju ko to ṣiṣẹ abẹ ṣugbọn to bẹrẹ si ni ṣe aarẹ lẹyin to ṣise abẹ naa tan ti awọn ayẹwo si n fi han pe ko ni kindinrin kan mọ.
Nigba to n ba BBC sọrọ, Barira Alhassan sọ pe ọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹrin ni oun ṣe iṣẹ abẹ lati fi bimọ toun si bẹrẹ si ni ṣe aarẹ lẹyin ọjọ diẹ ti wọn ṣiṣẹ abọ ọhun.
"Lẹyin ọjọ diẹ t imo ṣiṣẹ abẹ, ara mi bẹrẹ si ni fa, mo n bi, inu bẹrẹ si ni dun mi, ara mi bẹrẹ si ni wu, niṣe ni idi maa n dun mi ti mo ba fẹ tọ.
"Mo bẹrẹ si ni beere lọwọ awọn obinrin mii ti wọn ti ṣe iṣẹ abẹ lati fi bimọ boya awọn naa koju iru awọn inira bẹẹ lẹyin ti wọn bimọ tan."
O ni bi o tilẹ jẹ pe oun ti bimọ mẹwaa tẹlẹ igba akọkọ niyi to n ṣe iṣẹ abẹ lati fi bimọ.
Barira sọ pe o jẹ oun iyalẹnu fun oun nigba ti dokita to kọkọ ṣayẹwo fun oun sọ pe kindinrin kan lo ku ti oun ni.
"Dokita naa beere boya mo ta kindinrin naa ni mo si sọ fun pe rara. Lẹyin naa lo ba mi sọrọ pe o ṣeeṣe ki eeyan gbe aye irọrun pẹlu kindinrin kan ṣoṣo, to si fun mi ni awọn ogun lati maa lo..́
O fi kun pe lẹyin ti awọn ọmọ iya oun beere pe ki wọn ṣalaye ohun to ṣẹlẹ gangan fun awọn, niṣe ni awọn alaṣẹ ile iwosan naa n ṣe bi ẹni pe wọn fẹ fi ọwọ bo ọrọ naa mọlẹ.
Lẹyin eyi ni awọn ẹbi Barira kọ iwe si ile iwosan pe awọn fẹ mọ nipa akọọlẹ ilera Barira to w anile iwosan naa ṣugbọn wọn ni ile iwosan naa ni awọn ko ni.

Oríṣun àwòrán, Zakaria Alhassan
Zakari Alhassan, ẹni to jẹ ọmọ iya Barira sọ pe awọn kọwe ranṣẹ sile iwosan naa nitori ayẹwo kan to ṣe lọdun 2015 fi han pe o ni kindinrin mejeeji to n ṣiṣẹ bo ṣe yẹ.
O ni baba awọn lọ si ile iwosan naa lati lọ beere oun to ṣẹlẹ gangan amọ wọn ko da baba naa lohun.
O fi kun pe awọn ri pe naa mu ifura dani nitori ile iwosan naa sọ pe awọn ko ni akọọlẹ Barira kankan lọwọ to si jẹ pe ibẹ lo maa n lo koda to bimọ sibẹ.
"Eyi jẹ ka maa fura pe wọn ṣe nnkankan fun ẹgbọn wa."
Ẹbi Barira ni ọpọlọpọ iwe ẹsun ni awọn ti kọ sile iwosan naa, ti awọn si tun ti kọ si ileeṣẹ to n ri si eto ilera ni ipinlẹ Gombe.
O ni ileeṣẹ naa ti ranṣẹ pe Barira, ọkọ rẹatawọn oṣiṣẹ ile iwosan naa.
O sọ pe ileeṣẹ naa ni kawọn ma jẹ ẹ ki ọrọ naa lu sita titi ti iwadii fi maa pari ṣugbọn awọn ko faramọ bi iwadii naa ṣe n lọ.
Barira sọ pe iwadii kikun lori oun to mu oun padanu kindinrin kan lojiji ni oun fẹ mọ, ki idajọ ododo si waye lori iṣẹlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, Zakaria Alhassan
Ile iwosan jiyan ẹsun yiyọ kindinrin Barira
Awọn alaṣẹ ile iwosan Gombe State Specialist Hospital ti jiyan ẹsun pe dokita kankan yọ kindinrin Barira Alhassan lasiko to ṣiṣẹ abẹ ibimọ.
Atẹjade kan ti ile iwosan naa fi lede sọ pe irọ to jina si ootọ ni ẹsun naa ati pe lai si ẹri kankan ti wọn le fidi ẹsun naa mulẹ.
Ile iwosan naa ni akọọlẹ Barira ti awọn ni pe o ṣe iṣẹ abẹ lati fi bimọ lai ṣe iṣẹ abẹ mii to niiṣe pẹlu kindinrin rẹ.
"Ko si ninu akọọlẹ kankan pe awọn dokita to ṣiṣẹ abẹ fun Barira lasiko ibimọ fọwọ kan ibikibi to niiṣe pẹlu kindinrin rẹ."
Wọn ni lẹyin ti awọn ẹbi Barira fẹsun ile iwosan naa ni wọn ti bẹrẹ iwadii lati fidi ohun to waye gangan mulẹ.
Atẹjade ile iwosan naa ni ayẹwo ti awọn ṣe ni ile iwosan Federal Teaching Hospital fi han pe o ṣeeṣe ki wọn bi Barira pẹlu kindinrin kan ṣoṣo, pe kii ṣe pe o padanu kindinrin naa lasiko to bimọ.
Ile iwosan naa ni awọn san owo iwadii naa lati ri daju pe awọn fidi ootọ mulẹ.
Wọn ṣalaye pe awọn ti ṣepade pẹlu Barira atawọn ẹbi rẹ lati ṣalaye esi ayẹwo naa fun wọn.
Wọn ni Barira atawọn ẹbi rẹ ni awọn fẹ ṣe ayẹwo ni ile iwosan mii eyi ti awọn fọwọ si pe ki wọn lọ ṣe.
Ile iwosan naa sọ pe awọn n reti esi ayẹwo ti awọn ẹbi Barira lọ ṣe.
Wọn fẹsun kan fifẹ ọrọ naa loju lori ayelujara jẹ biba ile iwosan naa lorukọ jẹ, ti wọn ko si ni jẹ kawọn eeyan ni igbagbọ ninu awọn ile iwosan atawọn oṣiṣẹ eto ilera.
Wọn tẹnumọ pe awọn ko yọ kindinrin Barira nigba to n ṣe iṣẹ abẹ lati bimọ rara.



























