Mò sọkún kíkorò bí dókítà ṣe sọ pé màá lo òògùn fún ọdún márùn-ún fún ìtọ́jú àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn, mi ò sì gbọdọ̀ bímọ́ lẹ́ni ọdún 39 – Tope Osoba

Oríṣun àwòrán, Tope Osoba/Instagram
Iroyin ibanujẹ mii tun ti ṣẹyọ lagbo tiata Yoruba, Temitope Esther Koworola Osoba ti jade laye.
Owurọ kutu Ọjọru, ọjọ karun-un oṣu Keje ọdun 2026 yii ni oṣere tiata bii tiẹ, Alesh Sanni, kede iku Tope Osoba loju opo Instagram rẹ.
Lasiko ti a n kọ iroyin yii, a ko ti i le fidi ohun to pa gbajumọ oṣerebinrin naa mulẹ.
Amọ saaju lo ti kede pe oun ni aisan jẹjẹrẹ ọyan, o se isẹ abẹ ni igba meji, to si n lo oogun, koda o beere fun iranwọ owo lasiko naa.
"Mi o le sun latigba ti mo ti gbọ iku rẹ lale ana"
Bi Alesh to kede iku naa ṣe gbe e jade lo kọ ọrọ aro soju opo naa pe:
"Mi o le sun latigba ti mo ti gbọ iku rẹ lalẹ ana, ko buru o. Sun ire o, arabinrin mi ọwọn, Temitope Osoba."
O fi kun un pe awọn jọ lo igba, awọn si jọ ni awọn iriri ti ko ṣee gbagbe. Amọ o ti tan bayii, oun ko tiẹ mọ ohun ti oun le sọ.

Oríṣun àwòrán, Alesh Ola Sanni/Instagram
"N ko ronu pe iru iṣoro aisan jẹjẹrẹ ọyan le kan mi laye, paapaa lẹyin ti mo kọ awọn iwa kan silẹ, ti n ko si jẹ ijẹkujẹ tabi mu imukumu kankan mọ"
Lasiko ifọrọwerọ ti BBC ṣe pẹlu Temitope Osoba nigba aye rẹ, lo ti ṣalaye kikun nipa ohun ti awọn Dokita sọ fun un lasiko iṣẹ abẹ naa fun aisan itọju jẹjẹrẹ ọyan.
Oloogbe Tope Osoba, ti ko ti i bimọ kankan, ṣalaye nigba naa pe dokita sọ pe oun gbọdọ maa lo oogun lọ fun ọdun marun-un, oun ko si gbọdọ bimọ laarin asiko naa.
O fi kun un pe oun sunkun kikoro, oun si n ro o pe ṣe wọn yoo ge ọyan naa kuro ni, abi oun ti yoo tilẹ pa oun niyẹn.
Oṣerebinrin naa sọ pe oun ko ronu pe iru iṣoro bẹẹ le kan oun laye, paapaa nigba toun ti kọ awọn iwa kan silẹ, ti oun ko si jẹ ijẹkujẹ tabi mu imukumu kankan mọ.
Amọ lẹyin ti wọn ṣiṣẹ abẹ naa, o ni oun bẹrẹ si i gbe igbe aye alaafia, ara oun si le daadaa.
Titi di asiko ti Tope Osoba papoda yii, lo fi jẹ oniṣowo, bo ṣe n ta irẹsi apo lo n ta awọn nnkan jijẹ to n ṣe funra rẹ, to si maa n polowo rẹ lori ayelujara.
Awọn ohun to maa n gbe jade loju opo Whatsapp ẹ maa n kun fun ipolowo ọja rẹ to n ta, abi nibi to ba ti n jọsin ninu ijọ Sele to n lọ.
Bakan naa ni Tope, ẹni ogoji ọdun maa n ṣe adura lati di ọlọmọ laye, paapaa nigbakugba tawọn eeyan ba kede pe awọn di ọlọmọ lori ayelujara.
Lojiji ni iroyin iku rẹ balẹ gudẹ lowurọ ọjọ karun-un oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii, lẹyin ti ọpọ eeyan ti ro pe o ti ṣẹgun jẹjẹrẹ, o si ti n gbe igbesi aye alaafia, amọ iku pa oju Esther Kofoworola Temitope Osoba de, gbajumọ oṣere naa ki aye pe o di gba o ṣe .

Oríṣun àwòrán, Osoba Temitope/Instagram
Ta a ni Tope Osoba?
Gbajumọ oṣere ni Oloogbe Temitope Osoba, ọmọ ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun si ni.
O ti kopa ninu ọpọlọpọ iṣẹ ori itage lede Yoruba ati oyinbo, bẹẹ lo si n ṣe pupọ ninu ere igbalode ti a mọ si Skit.
Nnkan bii ọdun meji sẹyin ni Tope Osoba lugbadi aisan jẹjẹrẹ ọmu, nigba to kede pe oun ri apẹẹrẹ koko kekere kan ninu ọmu naa.
Oṣere naa kede pe oun lọ sileewosan, wọn si fidi ẹ mulẹ pe wọn ni lati yọ koko ọyan naa pẹlu iṣẹ abẹ.
O pada bẹbẹ owo lọwọ awọn ọmọ Naijiria lati fi ṣiṣẹ abẹ naa, wọn si yọ ọ .
Loṣu Keji ọdun 2025 ni BBC News Yoruba ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun Oloogbe Tope Osoba, o si ṣalaye nigba naa pe ko wu oun lati tọrọ owo nita gbangba, amọ nigba ti ko si ọna miran, ti owo naa si gbọdọ pe lo mu oun gbe bẹbẹ iranlọwọ naa.





























