Ẹṣin mọ́kàndínláàádọ́ta ni mo ti pàdánù ní iléeṣẹ́ mi - Ibrahim Chatta

Oríṣun àwòrán, Others
Gbajumọ oṣere tiata, Ibrahim Chatta ti sọrọ lori awuyewuye to n waye lori ọrọ to sọ pe oun padanu ọpọlọpọ awọn ẹṣin ti oun ni ni abule rẹ ti wọn ti n ṣe fiimu to w ani ilu Oyo.
Chatta ninu fidio kan to fi sori ikanni Instagram rẹ, sọ pe oun sọrọ sita lori iṣẹlẹ naa lẹyin ti awọn eeyan n fi oun ṣe yẹyẹ lori ọrọ naa lori ayelujara.
Ni ọjọ diẹ sẹyin ni ẹnu bẹrẹ si ni kun Ibrahim Chatta lori ayelujara lẹyin to sọ pe oun ti padanu ẹsin mejidinlaaadọta ni ilu ti ileeṣẹ rẹ ti wọn ti maa n ṣe fiimu.
Lati igba to ti sọrọ naa ni oniruuru awuyewuye ti n waye lori ayelujara, tawọn eeyan si n jiyan pe ko ni owo to fi le ra iye ẹṣin bẹẹ sinu ọgba ileeṣẹ rẹ.
Amọ Ibrahim Chatta ti wa sọrọ bayii to si sọ pe iye ẹṣin ti oun ti padanu ninu ileeṣẹ oun ti di mọkandinlaaadọta.
O ni ẹṣin kan mii tun ti ku lẹyin ti oun sọrọ nipa awọn ẹṣin 48 ti oun ti kọkọ darukọ sẹyin ati pe ẹṣin meji ni oun ti padanu ninu ọdun yii nikan.
Agba oṣere naa sọ pe ọdun yii ni awọn ni akọọlẹ ẹṣin ti ko ku pupọ to jẹ pe meji pere lo ku.
O ni oun mọọmọ lati ma sọ ohunkohun nipa nnkan tawọn eeyan ti n gbe kiri lori iroyin naa tẹlẹ nitori oun ti ni oun ko fẹ maa sọrọ nipa nnkan ti wọn ba n sọ nipa oun lori ayelujara mọ.
O ṣalaye pe ọpọlọpọ fiimu Yoruba to jẹ ti ibilẹ ti wọn maa n ṣe lo jẹ pe ileeṣẹ oun ni wọn ti maa n ya ẹṣin.
O sọ pe eeyan to fẹran nnkan ọsin paapaa ẹṣin ni oun ati pe ọpọ awọn ẹṣin naa lo jẹ ohun ti oun fi n ṣowo, ti oun si maa n ya awọn akẹgbẹ oun lati fi ṣe ere.
Nigba to n sọrọ nipa nnkan to n ṣokunfa iku awọn ẹṣin naa, Chatta ṣalaye pe bi ẹsin ṣe lagbara ti wọn maa n ṣiṣẹ to naa ni wọn ṣe maa n tete ku si.
Chatta sọ pe Kokoro kan wa to maa n jẹ ẹṣin nigba ti wọn ba ti ni egbo lara, to si jẹ pe awọn ẹṣin maa n ba ara wọn ja, ti wọn maa n da egbo sira wọn lara.
O fi kun pe kii ṣe aitọju awọn ẹṣin oun bo ṣe yẹ lo n ṣokunfa bi wọn ṣe n ku lera, o ni awọn ẹṣin jẹ ẹranko ti wọn kii saba lagbara mọ lẹyin ibimọ tabi ti wọn ba ti n dagba.
O tẹsiwaju pe ẹṣin to ku ti oun ni ninu ọgba oun bayii ko ju mẹtadinlọgbọn lọ mọ nitori oun ko ra ẹṣin lodun yii rara.
Chatta ni ọpọ awọn oṣere ni ko fẹ lọ ya iṣẹ ni ileeṣẹ oun mọ lasiko yii nitori ipenija aabo to waye ni ilu Esinele nibi ti awọn ajinigbe ti ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe lọ.
O ni awọn akẹgbẹ oun bẹru lati lọ si ipinlẹ Oyo fun ere nitori ibẹru ijinigbe nitori naa ni oun ko ṣe ra kun awọn ẹṣin ti oun ni lọwọ.
Ibrahim Chatta jẹ ẹni to gbajumọ fuun ifẹ to ni si ẹṣin, to si maa n lo wọn ninu ere, to si tun maa n gbe wọn soju opo ayelujara rẹ.
Ni ọdun 2024 lo gbe atẹjade kan sita nigba ọkan lara awọn ẹṣin to fẹran julọ jade laye to si ni iku ẹṣin naa dun oun gidi.
Oun lo ni ileeṣẹ Africhatta Film Village and Resort to w ani ipinlẹ Oyo nibi ti wọn ti maa n ya fiimu lọkanojọkan.
Bakan naa ni wọn ni awon ẹran isin bii ẹṣin, rakunmi ati maluu ninu ọgba naa eyi ti wọn maa n lo ninu ere.
Lara awọn fiimu ti wọn ti ṣe ninu ọgba naa ni Labake Olododo, Lisabi, ati bẹẹ bẹẹ lọ.



























