Ológun àti ọlọ́pàá kojú agbébọn tó jí èèyàn mẹ́sàn-án gbé, wọ́n rí ọmọdé méje gbà padà, ẹ̀mí agbófinró méjì bọ́

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/X
Ninu igbiyanju lati gba awọn eeyan mẹsan-an kan ti awọn agbesunmọmi gbe lọ pada nipinlẹ Zamfara, ṣoja ati ọlọpaa kan ti padanu ẹmi wọn.
Ileeṣẹ ologun ilẹ Naijiria lo fidi eyi mulẹ ninu atẹjade ti wọn fi si oju opo X wọn lọjọ Aiku, ọjọ keji oṣu Kẹjọ ọdun 2026.
Ọgagun Olaniyi Osoba, Adele Adari lẹka ikede Operation FANSAN YAMMA, ṣalaye ninu atẹjade naa, pe Satide ọjọ kin-in-ni oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii ni awọn agbebọn naa gbiyanju lati yawọ ibudo awọn ologun to wa ni Kasuwan Daji.
Nnkan bii aago meji oru ku ogun iṣẹju lo ni wọn yade. Amọ awọn ologun naa koju wọn.

Oríṣun àwòrán, Others
Bawo ni ikọlu naa ṣe waye?
Atẹjade awọn ologun ṣalaye pe oru la a ṣeka ni awọn agbesunmọmi naa fi ṣe, amọ awọn ologun naa ko sun lori ọrọ wọn.
"Ikọ ologun ẹka keji, Operation FANSAN YAMMA, dari awọn ẹṣọ si ibudo to wa ni Kasuwan Daji, nijọba ibilẹ Kaura Namoda, ipinlẹ Zamfara, wọn si dena awọn agbesunmọmi naa lati ma wọle.
"Bi wọn ṣe koju wọn lo mu kawọn alatako yii fara gbọta, wọn si fọnka pẹlu idaamu to ba wọn.
"Eyi to jẹ ko ṣee ṣe fawọn ẹṣọ lati gba eeyan mẹsan-an ti wọn ji gbe kalẹ."
Ileeṣẹ ologun sọ pe awọn kofiri awọn agbesunmọmi naa, awọn si ṣigun si wọn bo ṣe yẹ.
Wọn fi kun un pe ikọ ologun kan lo kọkọ n ba awọn agbesunmọmi ọhun fa a, ko too di pe awọn ṣafikun ikọ ọmọ ogun si i.
"Lẹyin ti a koju ara wa lakọkọ, awọn ẹṣọ pupọ de si i wọn si le awọn agbesunmọmi to ti ji awọn eeyan ti a ko mọ iye wọn lọ naa.
Awọn ilu to wa lagbegbe ni wọn ti ji awọn eeyan naa gbe.
"Bi awọn ẹṣọ ṣe le wọn lai dẹyin lo jẹ ki wọn ri eeyan mẹsan-an gba pada lai farapa."
Pupọ ninu awọn ti wọn gba kalẹ naa ni wọn jẹ ọmọde.
"Ṣọja ati ọlọpaa kan ba a lọ"
Amọ bi wọn ṣe ri aṣeyọri ṣe nipa gbigba eeyan mẹsan-an pada lọwọ agbesunmọmi, ileeṣẹ ologun sọ pe oun padanu ṣọja kan sinu ija naa.
Bakan naa ni wọn ni ọlọpaa kan naa tun ku ninu rogbodiyan naa latari ibọn to ba a.
Atẹjade yii tẹsiwaju, pe awọn ṣọja meji mi-in tun fara gba ibọn, amọ wọn sare fi ọkọ ofurufu gbe wọn lọ sile iwosan fun itọju.
Ara wọn ti balẹ bi awọn ologun ṣe kede.
Fun awọn to n gbe iroyin kiri pe ṣọja mẹfa lo ku ninu iṣẹlẹ naa, Ọgagun Osoba sọ pe irọ gbuu leyi.
O ni ṣọja kan, ọlọpaa kan lo ba ikọlu naa lọ.
Wọn ṣapejuwe iṣẹlẹ yii bii ọkan lara idaamu to ti n ba awọn agbesunmọmi kaakiri aaye wọn ni Naijiria.
Bẹẹ ni wọn ni awọn yoo maa fin wọn lape lọ titi ti alaafia yoo fi jọba kaakiri Naijiria ni.





























