Kókó ohun tó wà nínú owó oṣù tuntun fáwọn ológun tí Ààrẹ Tinubu buwọ́lu

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Lati fi imọriri han si akọ iṣẹ ti awọn ẹṣọ alaabo bii ologun ilẹ, ti ori omi ati ti ofurufu n ṣe lorilẹede yii, Aarẹ Bola Tinubu ti buwọlu afikun owo oṣu wọn.

Afikun owo oṣu naa wa laaarin ida ọgbọn si ọgọrin (30-80%) gẹgẹ bi Oludamọran pataki fun aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, ṣe fi lede lọjọ Iṣẹgun.

O kere tan, awọn ologun ti iye wọn to ẹgbẹrun lọna aadọtalenigba (250,000) ni yoo jẹ anfaani afikun owo oṣu naa gẹgẹ bi atẹjade ti Onanuga fi sita lorukọ Aarẹ Tinubu ṣe sọ.

Igba wo ni afikun naa yoo bẹrẹ, awọn wo lo kan, bawo ni wọn ṣe pin in?

Eto owo oṣu tuntun yii yoo bẹrẹ lati ọjọ kin-in-ni oṣu Kẹsan-an ọdun 2026.

Awọn ologun ti ipo wọn ju eyi ti a mọ si 'colonel' lọ yoo lẹtọ si afikun owo oṣu ìdá ọgbọn.

Awọn wọnyi ni awọn ọgagun bii Brigedia-Jẹnẹra, Mejọ -Jẹnẹra, Lieutenant Jẹnẹra atawọn Jẹnẹra lasan.

Awọn ti ipo wọn bẹrẹ lati colonel titi kan awọn ti a mọ si warrant officer yoo gba afikun ida aadọta (50%), nigba tawọn to wa nipo Sajẹnti yoo gba ida ọgọrin (80%).

Eyi tumọ si pe awọn onipo kekere yii ni afikun ba owo wọn ju.

Afikun yii ni ileeṣẹ aarẹ sọ pe o mu ki owo oṣu awọn ologun lọdun kan to maa n wa ni N660 billion tẹlẹ di N924 billion bayii.

"Gbogbo igba ni Aarẹ Tinubu maa gboriyin fawọn ologun bi wọn ṣe n koju awọn bandiiti,ajinigbe atawọn agbesunmọmi"

Atẹjade ileeṣẹ Aarẹ Tinubu naa tẹsiwaju pe igba gbogbo ni aarẹ n mọ riri iṣẹ awọn ologun to si maa n gboriyin fun wọn fun iṣẹ takuntakun ti wọn n ṣe.

"Awọn ọkunrin ati obinrin to n ran wa lọwọ lati wa ni alaafia nilee wa yẹ lati ṣe atilẹyin fun, ka si mọ riri wọn fun iṣẹ ti wọn n ṣe fun orilẹede.

"Ijọba wa yoo tẹsiwaju lati maa mu igbayegbadun awọn ologun ni koko, bẹẹ la o si maa pese awọn nnkan ija igbalode ti wọn nilo lati fi ṣe iṣẹ wọn."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade naa ka.

Wọn tẹsiwaju pe iṣakoso yii yoo maa mu ọrọ awọn ologun ni pataki, wọn yoo si maa fun wọn ni nnkan ija igbalode ti wọn nilo, pẹlu awọn imọ ẹrọ ti wọn nilo lati fi ṣiṣẹ wọn.

"Iṣakoso wa mọ pe ko si orilẹede to le debi giga bi ko ba si aabo. Idi ẹ niyẹn ti a ṣe duro pe a maa ko gbogbo awọn ologun jọ ṣẹggun iṣoro aabo, ka si da aabo bo ẹmi ati dukia awọn ọmọ Naijiria."

"Lakootan ọrọ naa, Aarẹ rọ awọn ologun lati ri afikun owo oṣu yii bii fifi ẹmi imoore han fun iṣẹ ti wọn n ṣe fun Naijiria ti i ṣe ilẹ baba wa.

O ni a jọ maa ba ero awọn ọta to fẹẹ fa aṣọ iyi Naijiria ya ni jẹ ni.

Àfiwé owó oṣù àwọn ṣọ́jà Nàìjíríà pẹ̀lú àwọn akẹgbẹ́ wọn lórílẹ̀èdè míràn ní Áfíríkà

Agbẹnusọ nigbakan ri fun ileeṣẹ ọmọogun orilẹede Naijiria, Ọgagunfẹyinti John Enenche ti pe fun afikun owo oṣu awọn ọmọogun lorilẹede Naijiria, o ni owo oṣu ọmọogun to kere julọ yẹ ko jẹ ẹgbẹrun lọna igba ati aadọta Naira, N250, 000 ni ibamu pẹlu bi nnkan ṣe ri lọwọ yii lorilẹede Naijiria ati bi wọn ṣe n fori laku .

Minisita fun eto abo, Ọgagunfẹyinti Chris Musa lo kọkọmu ọrọ nipa igbayegbadun awọn ṣọja wa si ojutaye laipẹ yii nigba to kede pe wọn ti ṣe afikun owo oṣu awọn ṣọja to kere julọ si ẹgbẹrun lọna ọgọrun Naira, (N100, 000) lati ẹgbẹrun mọkandinlaadọta (N49, 000) to wa tẹlẹ.

Nibayii ọrọ ti Ọgagunfẹyinti Enenche sọ nipa owooṣu tuntun yii ti n fa ọpọ awisọ lori ayelujara ti wọn si n kọminu lori owo oṣu awọn ologun pẹlu iṣẹ ifaraẹnijin ti wọn n ṣe lẹnu i'sẹ lati daabo bo ilu, paapaa fifi ori la iku lati koju awọn agbebọn ati agbesunmọmi kaakiri tibutoro Naijiria.

Afiwe laarin Owo oṣu awọn ṣọja lorilẹede Naijiria ati awọn akẹgbẹ wọn lawọn orilẹede yoku nilẹ Afirika

Ko si akọsilẹ apapọ kan gboogi fun afiwe owo oṣu awọn ologun ati igbayegbadun wọn ni Afirika. Ni awọn orilẹede kan, ko tilẹ si iroyin to kuna nipa rẹ ni ita gbangba fun araalu lati mọ.

Amọ, awọn ajọ kan wa ti ojuṣe wọn duro lori akojọ awọn iroyin wọnyi niwọba eyi ti wọn ba le ri kojọ.

Eyi ni iye owo to kere ju gẹgẹbi owooṣu ologun ni Naijiria, South Africa ati Ghana gẹgẹbi ajọ ako iṣiro iwadi jọ Statisense lorilẹede Naijiria ṣe fi sita.

Fun ṣọja ti ipo rẹ jẹ 'Private' –

Naijiria: ₦104,000 ($64)

Ghana: GHS 1,000 to 1,500 (₦157,000 – ₦235,000)

South Africa: R8,000 to R12,000 (₦704,000 – ₦1.06 Million)

Bakan naa ni Statisense tun ṣalaye lori owo oṣu awọn ọgagun onirawọ meji (Major General) eyi ti wọn fi si Miliọnu kan o le ẹẹdẹgbẹjọ Naira, (N1.15m).

Owo oṣu akẹgbẹ wọn lorieede South Africa ju eyi lọ ni ilọpo mẹjọ pẹlu R120,000 tabi ₦9,999,600 iyẹn owoto din diẹ ni miliọnu mẹwaa Naira ni ibamu pẹlu odiwọn owo Naira lode oni.

BBC News Yoruba ko tii fi idi awọn owo wọnyi mulẹ ni iha ọdọ tiwa o, amọṣa. orilẹede Naijiria ati South Africa wa lara awọn orilẹede marun un ti ọrọ aje wọn ṣe jọmujọmu julọ ni Afirika.