Wó kókó méjìlá tó yẹ kí o mọ̀ nípa Temitope Osoba, òṣèré tíátà tó jáde láyé

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 10

Bo tilẹ jẹ pe kii ṣe iroyin tuntun mọ pe gbajugbaja oṣerebinrin nni, Temitope Kofoworola Osoba ti jade laye lẹni ogoji ọdun, sibẹ, ọpọ awọn akẹgbẹ ati ololufẹ rẹ ṣi n ṣedaro rẹ.

Ọpọlọpọ adojukọ ni oloogbe naa koju lati kekere rẹ, titi to fi dagba, to fi mọ nidi iṣẹ tiata to yan laayo.

Lara awọn adojukọ ojiji ti oṣerebinrin naa koju ni ti aisan jẹjẹrẹ ọmu to kọluu lọsan gangan.

Gbara ti Temitope Osoba ti ṣakiyesi koko to so si ẹgbẹ ọmu rẹ, lo ti gba ile iwosan lọ.

Sugbọn awọn oniṣegun oyinbo sọ pe ko sewu loko longẹ, lai mọ pe ewu nla ni longẹ funra rẹ.

Obinrin naa pada ṣiṣẹ abẹ lati yọ koko naa to jẹ jẹjẹrẹ ọmu kuro, to si gba oniruuru iwosan, ko to di pe o pada sidi iṣẹ tiata rẹ.

Temitope Osoba ko ipa takuntakun nidi iṣẹ tiata, eyi to jẹ ko maa wa loju iworan gbogbo awọn olulufẹ ere tiata ni gbogbo igba, ko to di pe o ki aye pe o digboṣe lọjọ karun-un, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026.

Ni bayii, ẹ wa wo awọn ohun mejila pataki nipa igbe aye Temitope Osoba.

Koko pataki aye nipa Temitope Osoba

Ilu to ti wa

Ọmọ bibi ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun ni Temitope Osoba

Ọjọ ibi rẹ

Ọjọ keji, oṣu Kejila, ọdun 1985 ni wọn bi oloogbe naa niluu Abẹokuta, nibẹ si lo ti bẹrẹ sii nifẹ si iṣẹ tiata, lati kekere.

Bo ṣe jade sita

Temitope Osoba tan mọ gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun, Oloye Olusegun Osoba, nitori pe inu idile kan naa ni Segun Osoba ati baba Temitope ti jọ jade.

Temitope ko duro lati maa lo orukọ naa fi gbe ara rẹ, ṣugbọn o jade sita, o si ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe oun ni orukọ toun, fun igbelarugẹ orukọ idile Osoba.

Eto ẹkọ rẹ

Ẹkọ imọ nipa okoowo (Business Education) ni Osoba ni, ni fasiti Olabisi Onabanjo to wa niluu Ago-Iwoye, ipinlẹ Ogun.

Imọ ẹkọ naa lo fi kun iṣẹ rẹ to yan laayo, eyi tii ṣe tiata, fun igbelarugẹ gbigbe ere jade, ati kikopa ninu ere.

Ṣaaju iṣẹ tiata

Temitope ko ṣa deede bẹrẹ iṣẹ tiata lojiji, tipẹtipẹ ko too bẹrẹ sii farahan ninu awọn ere agbelewo, lo ti n ṣiṣẹ alajota, to si tun n jo ninu awọn awo orin loriṣiriṣi.

Nigba to ṣiṣẹ alajota titi, lo ri anfaani lati wọnu iṣẹ tiata, to si ẹrẹ lẹkunrẹrẹ ni nnkan bi ọdun 2005. Gbara to wọle, lo ti bẹrẹ sii lokiki, to jẹ ki wọn maa lo o kaakiri.

Awọn iṣẹ fiimu agbelewo to ti kopa

Ọpọ ere agbelewo ti ko lonka ni Osoba kopa ninu rẹ nigba to wa laye, lara rẹ si ni Gucci Girls ti ọdun 2012, Accident to jade lọdun 2013, ati Ifedolapo to jade lọdun 2015, ati awọn miran ti a ko le mẹnuba tan.

Bi Osoba ṣe n kopa inu ere gẹgẹ bii jagidijagan, bẹẹ lo n kopa alawada ati iyaale ile, to fi mọ awọn miran.

Bo ṣe kofiri aisan jẹjẹrẹ ọmu

Ọdun 2024 ni Osoba ṣakiyesi koko kan lẹgbẹ ọmu rẹ. Kaka ko pa ẹnu rẹ mọ, ko si maa woran, niṣe lo.

O ṣeni laanu pe kaka ki awọn oniṣegun oyinbo fun un ni amoran, nipa bi yoo ṣe tete tọju ara rẹ, ko si ṣiṣẹ abẹ, niṣe ni wọn sọ pe ko si nnkan nibẹ.

Diẹdiẹ ni jẹjẹrẹ naa n dagba, ko to tun sare pada lọ, leyi to jẹ ko pada ṣiṣẹ abẹ.

Lasiko ti iṣẹ abẹ naa n lọ lọwọ, Osoba ṣe fọnran sita lati fi gba awọn obinrin lamọran nipa itọju ara ẹni, to si fi ara rẹ ṣe apẹẹrẹ.

Awọn eeyan dide iranlọwọ

Ọpọ awọn ololufẹ ati ọrẹ rẹ ni wọn dide iranlọwọ fun un nigba to jade lati ṣalaye nipa iṣoro to n koju.

Lẹyin to pada ṣiṣẹ abẹ tan, ti wọn si gbe jẹjẹrẹ naa jade, awọn dokita sọ fun un pe o gbọdọ lo oogun fun ọdun kan, ti ko si gbọdọ loyun, depodepo wi pe yoo bimọ.

Eyi lo jẹ ko jade lati bẹbẹ fun iranlọwọ awọn araalu, paapaa awọn ololufẹ rẹ lori oogun ti awọn dokita ni ko maa lo loore-koore.

Si iyalẹnu, awọn ẹlẹyinju aanu dide kaakiri Naijiria ati lagbaye, ko to tun pada sidi iṣẹ tiata rẹ.

O pari iṣẹ abẹ

Lẹyin ọpọlọpọ ayẹwo ti Osoba ṣe lẹyin iṣẹ abẹ, awọn dokita sọ fun un pe jẹjẹrẹ naa ko tii tan kaakiri ara rẹ.

Eyi lo si ṣalaye lori ayelujara fun awọn ololufẹ rẹ, nibi to ti n dupẹ.

Bi ara rẹ ṣe pada bọ sipo, lo n jẹ iyalẹnu nla fun ọpọ awọn ololufẹ rẹ, ti wọn si n wo o gẹgẹ bi awokọṣe nipa awọn ti ori ko yọ lọwọ aisan jẹjẹrẹ.

Temitope pada oko ere

Lẹyin ti gbogbo wahala ati iṣoro naa d'opin, Temitope Osoba pada sidi iṣẹ tiata lọdun 2025 to yan laayo.

Kaka ko jẹ ki irẹwẹsi ọkan ba oun, nipa awọn ohun to ṣẹṣẹ la kọja, obinrin naa wo o pe ohun to tọ ni lati pada soju iworan gbogbo awọn ololufẹ oun.

O ṣapejuwe ara rẹ fun gbogbo eeyan gẹgẹ bi akikanju, to si loun ṣetan lati fi awọn alakoja ati iriri oun kọ awọn eeyan lẹkọọ kaakiri agbaye.

Ipolongo aisan jẹjẹrẹ ọmu

Temitope Osoba di ohun to ja geere fun ipolongo aisan jẹjẹrẹ ọmu fawọn obinrin.

Lẹyin to ti gbadun, ti ara rẹ ya, o bẹrẹ sii ṣe ipolongo fun awọn obinrin lati maa ṣayẹwo ara, paapaa ọmu wọn loore-koore, lati le tete kofiri aisan naa lara, ko too pẹ ju.

Bi ko ṣe fi ọrọ sabẹ ahọn sọ fawọn eeyan, lo fa a ti gbogbo bi awọn obinrin ṣe n bo ẹnu lati sọrọ jade, paapaa lagboole amuludun.

Iku Temitope

Bi iroyin Temitope Osoba ṣe jade sigboro aye lọjọ karun-un, oṣu Kẹjọ, ọdun 2026 to dakẹ, lẹni ogoji ọdun, lo ti jẹ kayeefi fun awọn eeyan, paapaa awọn to sunmọ ọn.

Bi awọn kan ṣe n gbera ṣanlẹ, lawọn miran n wa ẹkun mu, pẹlu bi iku naa ṣe ba wọn lọkan jẹ to.

Gbajugbaja oṣere kan ti wọn n pe ni Alesh Sanni lo kọkọ gbe iroyin naa jade sori ikanni ayelujara, leyi to ṣe ọpọ ni kayeefi.

Latigba naa lawọn akẹgbẹ rẹ ti bẹrẹ sii gbe e kaakiri, ti wọn si n ṣedaro iku rẹ.

Ipa to fi lelẹ

Yatọ si idi iṣẹ tiata, ipa rere ni Temitope Osoba fi lelẹ.

Awọn ipa to fi lelẹ yii ni ko le jẹ ki awọn eeyan tete gbagbe rẹ, paapaa loju iworan.

Osoba fi awọn igbe aye rẹ to ṣokunkun lati tan imọlẹ fun awọn obinrin bii tiẹ, to si fun awọn obinrin to n koju ipenija aisan jẹjẹrẹ ni ireti ọjọ iwaju rere.

O fun ọpọ obinrin ni igboya lati koju iṣoro aisan jẹjẹrẹ nigbakugba to ba wọle de.

Mò sọkún kíkorò bí dókítà ṣe sọ pé màá lo òògùn fún ọdún márùn-ún fún ìtọ́jú àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn, mi ò sì gbọdọ̀ bímọ́ lẹ́ni ọdún 39 – Tope Osoba

Iroyin ibanujẹ mii tun ti ṣẹyọ lagbo tiata Yoruba, Temitope Esther Koworola Osoba ti jade laye.

Owurọ kutu Ọjọru, ọjọ karun-un oṣu Keje ọdun 2026 yii ni oṣere tiata bii tiẹ, Alesh Sanni, kede iku Tope Osoba loju opo Instagram rẹ.

Lasiko ti a n kọ iroyin yii, a ko ti i le fidi ohun to pa gbajumọ oṣerebinrin naa mulẹ.

Amọ saaju lo ti kede pe oun ni aisan jẹjẹrẹ ọyan, o se isẹ abẹ ni igba meji, to si n lo oogun, koda o beere fun iranwọ owo lasiko naa.

"Mi o le sun latigba ti mo ti gbọ iku rẹ lale ana"

Bi Alesh to kede iku naa ṣe gbe e jade lo kọ ọrọ aro soju opo naa pe:

"Mi o le sun latigba ti mo ti gbọ iku rẹ lalẹ ana, ko buru o. Sun ire o, arabinrin mi ọwọn, Temitope Osoba."

O fi kun un pe awọn jọ lo igba, awọn si jọ ni awọn iriri ti ko ṣee gbagbe. Amọ o ti tan bayii, oun ko tiẹ mọ ohun ti oun le sọ.

"N ko ronu pe iru iṣoro aisan jẹjẹrẹ ọyan le kan mi laye, paapaa lẹyin ti mo kọ awọn iwa kan silẹ, ti n ko si jẹ ijẹkujẹ tabi mu imukumu kankan mọ"

Lasiko ifọrọwerọ ti BBC ṣe pẹlu Temitope Osoba nigba aye rẹ, lo ti ṣalaye kikun nipa ohun ti awọn Dokita sọ fun un lasiko iṣẹ abẹ naa fun aisan itọju jẹjẹrẹ ọyan.

Oloogbe Tope Osoba, ti ko ti i bimọ kankan, ṣalaye nigba naa pe dokita sọ pe oun gbọdọ maa lo oogun lọ fun ọdun marun-un, oun ko si gbọdọ bimọ laarin asiko naa.

O fi kun un pe oun sunkun kikoro, oun si n ro o pe ṣe wọn yoo ge ọyan naa kuro ni, abi oun ti yoo tilẹ pa oun niyẹn.

Oṣerebinrin naa sọ pe oun ko ronu pe iru iṣoro bẹẹ le kan oun laye, paapaa nigba toun ti kọ awọn iwa kan silẹ, ti oun ko si jẹ ijẹkujẹ tabi mu imukumu kankan mọ.

Amọ lẹyin ti wọn ṣiṣẹ abẹ naa, o ni oun bẹrẹ si i gbe igbe aye alaafia, ara oun si le daadaa.

Titi di asiko ti Tope Osoba papoda yii, lo fi jẹ oniṣowo, bo ṣe n ta irẹsi apo lo n ta awọn nnkan jijẹ to n ṣe funra rẹ, to si maa n polowo rẹ lori ayelujara.

Awọn ohun to maa n gbe jade loju opo Whatsapp ẹ maa n kun fun ipolowo ọja rẹ to n ta, abi nibi to ba ti n jọsin ninu ijọ Sele to n lọ.

Bakan naa ni Tope, ẹni ogoji ọdun maa n ṣe adura lati di ọlọmọ laye, paapaa nigbakugba tawọn eeyan ba kede pe awọn di ọlọmọ lori ayelujara.

Lojiji ni iroyin iku rẹ balẹ gudẹ lowurọ ọjọ karun-un oṣu Kẹjọ ọdun 2026 yii, lẹyin ti ọpọ eeyan ti ro pe o ti ṣẹgun jẹjẹrẹ, o si ti n gbe igbesi aye alaafia, amọ iku pa oju Esther Kofoworola Temitope Osoba de, gbajumọ oṣere naa ki aye pe o di gba o ṣe .

Ta a ni Tope Osoba?

Gbajumọ oṣere ni Oloogbe Temitope Osoba, ọmọ ilu Abeokuta nipinlẹ Ogun si ni.

O ti kopa ninu ọpọlọpọ iṣẹ ori itage lede Yoruba ati oyinbo, bẹẹ lo si n ṣe pupọ ninu ere igbalode ti a mọ si Skit.

Nnkan bii ọdun meji sẹyin ni Tope Osoba lugbadi aisan jẹjẹrẹ ọmu, nigba to kede pe oun ri apẹẹrẹ koko kekere kan ninu ọmu naa.

Oṣere naa kede pe oun lọ sileewosan, wọn si fidi ẹ mulẹ pe wọn ni lati yọ koko ọyan naa pẹlu iṣẹ abẹ.

O pada bẹbẹ owo lọwọ awọn ọmọ Naijiria lati fi ṣiṣẹ abẹ naa, wọn si yọ ọ .

Loṣu Keji ọdun 2025 ni BBC News Yoruba ṣe ifọrọwanilẹnuwo fun Oloogbe Tope Osoba, o si ṣalaye nigba naa pe ko wu oun lati tọrọ owo nita gbangba, amọ nigba ti ko si ọna miran, ti owo naa si gbọdọ pe lo mu oun gbe bẹbẹ iranlọwọ naa.