Àbọ̀ ìwádìí ọlọ́pàá rèé lórí afurasí agbénipa tó fẹ́ gbẹ̀mí Kábíyèsí Ataoja ìlú Osogbo láàfin

Oríṣun àwòrán, Theataojaofosogboland/Instagram
Ileeṣẹ ọlọpa ipinlẹ Osun ti kede abọ iwadii rẹ lori ọrọ afurasi agbenipa to fẹ gbẹmi Kabiyesi Ataoja ilu Osogbo, Ọba Jimoh Oyetunji Olanipekun, Larooye Keji.
Ikede yii jade lẹyin ti igbimọ oluwadii eyi ti igbakeji kọmiṣọna ọlọpaa, DCP Suleiman Kafar Bayonle, to n ri si iwadii iwa ọdaran dari jabọ iwadii wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, DSP Abiodun Ojelabi, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe lọjọ kẹta oṣu Kẹfa yii ni ileeṣẹ ọlọpaa gba ipe kan pe ọkunrin kan ti wọn n pe ni Semilola Odunayo Monday ti inagijẹ rẹ n jẹ Ankara fo odi wọ inu aafin Ataoja niluu Osogbo.
DSP Ojelabi ni bi ọkunrin naa ẹni ọdun mẹrindilọgbọn ṣe bẹ silẹ lawọn oṣiṣẹ inu aafin atawọn araadugbo gbe ija koju ọkunrin naa.
''Bayii ni Semilola fẹsẹ fẹẹ tawọn eeyan si sare tẹle e lẹyin, nibi to ti n sare lọ lo ti fara ṣeeṣe.
Eyi lo mu un dero ile iwosan ẹkọṣẹ iṣegun UNIOSUN nibi to ti gba itọju.
Lẹyin ti Ankara gbadun diẹ lawọn ọlọpaa fọrọ wa a lẹnu wo ti o si jẹwọ pe loootọ loun fo odi wọ inu aafin Ataoja.
Amọ, afurasi naa sọ pe oun ko ni erongba lati ṣe Kabiyesi Ataoja ni ibi.
O jẹwọ wi pe apọju ogun oloro toun mu lo fa a toun fi lọ fo odi aafin wọle,'' Ojelabi lo sọ bẹẹ.
''Ko si ibọn tabi ohun ija oloro kankan lọwọ afurasi to wọ aafin Ataoja''
DSP Ojelabi fikun ọrọ rẹ pe ko si ibọn tabi ohun ija oloro kankan lọwọ afurasi naa nigba to wọ aafin.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe ọkunrin naa ti foju ba ile ẹjọ, o si ti wa ni atimọle lọgba ẹwọn bayii.
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun ti wa rọ araalu to ba mọ ohunkohun nipa iṣẹlẹ naa lati wa sọ nnkan ti wọn ba mọ fun ọlọpaa ki o le ṣe iranwọ fun iṣẹ iwadii to n lọ lọwọ.
Ileeṣẹ ọlọpaa tun ṣeleri pe awọn ko ni kaarẹ ninu akitiyan awọn lati daabo bo araalu ati dukia wọn, ati lati ri pe iwa ọdaran dikun nipinlẹ Osun.

























