WhatsApp gbé ètò tuntun jáde pẹ̀lú lílo orúkọ fáwọn oníbàárà dìpó nọ́mbà ìbáraẹnisọ̀rọ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oju opo ayelujara ti a mọ si Whatsapp ti n gbe igbesẹ tuntun bayii, eyi ti i ṣe lilo orukọ lati le ba ẹnikeji sọrọ, dipo nini nọmba ẹni ti a fẹ ba sọrọ nipasẹ atẹjiṣẹ ori aago.
Igbesẹ tuntun yii ni ẹka naa n gbero lati jẹ ko kan eeyan to le ni biliọnu mẹta ti wọn n lo Whatsapp kaakiri agbaye, eyi ti wọn ni yoo bẹrẹ laipẹ.
Whatsapp fi lede pe awọn onibaara le bẹrẹ si i ronu orukọ ti wọn fẹ lo lati ọsẹ yii lọ loju opo, bo tilẹ jẹ pe ki I ṣe dandan.
Bakan naa ni oju opo yii fi kun un pe eeyan le yọ orukọ naa kuro nigba to ba wu u, o si le paarọ rẹ si orukọ mi-in.
Bawo ni yoo ṣe ri gan-an?
Nigba to ba gbera sọ tan, ẹka yii ṣalaye pe awọn eeyan to fẹ fi atẹjiṣẹ ba ara wọn sọrọ yoo le ṣe bẹẹ lẹyin ti wọn ba ti gba orukọ ara wọn tan (bii igba ti eeyan gba nọmba ara ẹni).
Wọn ni aaye yoo si wa bii ti tẹlẹ lati di ẹni ti eeyan ko fẹẹ ba sọrọ pa (Block).
Bẹẹ ni eeyan si le fi ẹjọ ẹni to ba fi ohun ti a ko fẹ ranṣẹ si eeyan sun (Report unwanted messages).
Nipa bi orukọ ti eeyan fẹ lo ṣe gbọdọ ri, Whatsapp sọ pe ko gbọdọ gun ju ọrọ marundinlogoji (35) lọ.
Wọn ni awọn alaṣẹ tabi awọn gbajumọ nla ni awọn ko ni i jẹ ki orukọ wọn maa han fun ẹlomi-in lati ri.
Fun idi eyi, ẹnikan lasan ko le ji ko ni oun ni Donald Trump, fun apẹẹrẹ.
Ileeṣẹ Meta to ni Whatsapp sọ pe nnkan adani ti ọ̀wọ̀ wa fun ni lilo orukọ loju opo naa to fẹẹ bẹrẹ.
Nigba to n ṣalaye si i lori igbesẹ yii, Alice Newton-Rex, olori lẹka WhatsApp, sọ pe oun ti gbọ tawọn onibaara n sọ pe ki i wu awọn lati maa fi nọmba awọn silẹ nitori ati ba ẹlomiran sọrọ.
Wọn ni paapaa lawọn oju opo ti ero ti pọ,(Group chat) ti ki i ṣe ibasọrọ ẹnikan ṣoṣo.
Ilana tuntun yii lo ni oun ro pe yoo fun awon eeyan naa lanfaani lati yan ohun ti wọn ba fẹ ko maa han loke oju opo wọn.
Bawo ni mo ṣe le ya orukọ kan sọtọ fun lilo?
Gẹgẹ bi Meta ṣe ṣalaye, wọn yoo maa gbe awọn orukọ jade lọkọokan ejeeji lawọn oṣu to n bọ niwaju yii, wọn yoo si fi to awọn onibaara leti lọgan to ba ti ṣee lo.
Fun awọn ti wọn fẹ ya orukọ kan sọtọ, wọn yoo ri ilana loju opo wọn bi wọn ba lọ si abala ti oyinbo n pe ni profile setting.
Meta fi kun un pe ohun ti wọn yoo tẹ̀ ti wọn yoo fi fi aaye orukọ naa silẹ fun wọn yoo jade to ba ti wa nibẹ.
Eyi ko ṣee ṣe lori WhatsApp Web tabi Desktop bi wọn ṣe kede.
Wọn tẹsiwaju pe aaye yoo wa fun awọn olokoowo kereje ati ileeṣẹ lati lo orukọ ti wọn n lo ni ni Instagram tabi Facebook, fun idanimọ.
Ṣugbọn ẹni to ba fẹ ki orukọ to n lo ni WhatsApp ba ti awọn oju opo mi-in mu yoo ni lati so o pọ mọ eyi ti wọn n lo lọwọ labala ti wọn n pe ni Accounts Centre.
Fun awon ti wọn ni wọn ko ti i gbe orukọ tawon fẹ lo jade, ileeṣẹ Meta ni ki wọn ri i daju pe WhatsApp to ba igba mu ni wọn n lo, (Latest version), ki wọn si maa ṣọ oju opo naa fun ikede.



























