You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àkìtàn ya bo ilé ní Guinea, pa èèyàn 31
O kere tan, eeyan mọkanlelọgbọn (31) lo ti dagbere faye bayii lasiko ti a n kọ iroyin yii lorilẹede Guinea, latari akitan kan ti wọn n da ẹgbin si to ya lulẹ to si mu ọpọ ẹmi lọ.
Ọjọ Aiku ana ti i ṣe ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 ni iṣẹlẹ naa waye, ni nnkan bii aago meji si mẹta oru, lẹyin ojo arọọda kan to rọ.
Gẹgẹ bi ijọba orilẹede naa ṣe wi, olu ilu Guinea ti i ṣe Conakry ni akitan naa wa.
Bo ṣe ya lulẹ lo yabo awọn ile to wa nitosi, eyi to di ijamba to mu ẹmi awọn eeyan lọ.
Bakan naa ni eeyan mejilelogun miran tun farapa ninu ijamba naa, mẹfa ninu awọn wọnyi ni ijamba ṣe pupọ nigboro Dar- es-Salam, ti wọn si n gba itọju lọwọ.
Obinrin kan sọ fun awọn oniroyin ibẹ pe ọmọ oun marun-un lo ku sinu iṣẹlẹ naa.
Bẹẹ ni oye foju han pe o ṣee sẹ ki onka awọn to ku tun ṣi pọ ju eyi to gbode bayii lọ.
"A ti da awọn ẹṣọ sita lati wa awọn eeyan ti ijamba naa kan"
Ninu atẹjade ti awọn alaṣẹ orilẹede Guinea fi sita ni wọn ti ṣalaye pe awọn ti da awọn ẹṣọ alaabo sita, titi kan awọn ologun lati wa awọn eeyan ti ijamba naa kan amọ ti wọn moribọ.
Nibi akitan naa ni awọn to n ri si iṣẹlẹ pajawiri peju si, ti wọn n fi ẹrọ katakata tu ilẹ, ti awọn eeyan si pejọ wo bo ṣe n lọ.
Olootu ijọba Guinea; Mamadou Oury Bah, ti ṣabẹwo sibudo ijamba naa lati wo bi ọṣẹ́ ọhun ṣe to.
Ṣaaju ni olori agbegbe naa, Lancine Sylla, ti sọ fun ẹka iroyin AFP pe awọn n wo o pe o ṣee ṣe ki onka awọn to ku naa tun pọ si i.
O ni awọn ti yọ oku mẹrindinlogun jade labẹ ilẹ naa, awọn si ti ko wọn lọ sile igbokuusi.
Eyi kọ ni igba akọkọ ti iru iṣẹlẹ yii yoo ṣẹlẹ ni Guinea
Iru iṣẹlẹ yii ti waye ri lorilẹede Guinea,eeyan mẹwaa lo padanu ẹmi nigba naa.
Ibudo idalẹnu kan naa ti eyi ti waye ni ijamba ọhun ti waye ni 2017, to fi gba ẹmi eeyan mẹwaa naa.
Laipẹ yii ni ijọba orilẹede naa kilọ, pe kawọn eeyan to n gbe lagbegbe ori akitan naa kuro nibẹ, amọ ọpọ awọn eeyan ọhun ko fibẹ silẹ titi dasiko yii ti ijamba tun ṣẹlẹ yii.