You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Wo bí ìwọ́de tako àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ṣe gbérasọ lórílẹ̀èdè South Africa, àtàwọn agbègbè tí yóò ti wáyé
Ọgọọrọ ọmọ orilẹede South Africa lo jade fun iwọde tako awọn ọmọ ilẹ okeere to gberasọ loni ọgbọnjọ oṣu Kẹfa lorilẹede naa.
Kaakiri orilẹede naa lawọn oluwọde ti ko ara wọn jọ fun ifẹhonuhan to lagbara ọhun.
Wamuwamu lawọn ẹsọ eleto aabo duro kaakiri gbogbo ilu ti iwọde naa ti n waye lonii.
Ileeṣẹ ọlọpaa ti da awọn agbofinro sawọn ẹkun bii Gauteng, KwaZulu-Natal ati Western Cape lati dena rogbodiyan to le ṣẹlẹ nibi iwọde naa.
Aarẹ Cyril Ramaphosa ti rọ awọn ọmọ ilu to n kopa ninu iwọde naa wi pe ki wọn rọra ṣe, ki wọn si ma dunkoko mọ ẹnikẹni.
Amọ, Aarẹ Ramaphosa gbagbọ pe o yẹ ki atunṣe wa lori igbeluu lorilẹede South Africa.
Ramaphosa sọ pe ''ọpọ awọn ọmọ ilẹ okeere to n gbe ni South Africa ni gbigbe wọn ko lodi sofin.
Wọn n ṣiṣẹ, wọn n kawe, awọn mii n dokowo, wọn si n ko ipa wọn ninu idagbasoke awujọ.
Irufẹ awọn eeyan bayii lẹtọọ si eto aabo lati ọdọ ijọba gẹgẹ bi ofin ṣe la a kalẹ.
Ẹtọ lati ṣe ifẹhonuhan ko fun ẹnikẹni laṣẹ lati dunkoko tabi huwa ipa si ẹnikẹni.''
Ọpọ ọmọ ilu okeere ni wọn ti kuro ni South Africa latari iwa ipa tawọn ọmọ oniluu n hu si wọn.
Ileeṣẹ ọlọpaa South Africa ni ko din ni ẹgbẹrun mẹẹdọgbọn ọmọ ilẹ okeere to ti filu naa silẹ, eleyii ti ọpọ ninu wọn jẹ ọmọbibi awọn orilẹede Afirika mii.
Awọn agbegbe ti iwọde tako ọmọ ilẹ okeere ti waye ni South Africa
Awọn alaṣẹ ijọba ti kede ibi ti iwọde naa yoo ti waye niluu Johannesburg lonii.
Iwọde naa ni a gbọ pe awọn oluwọde fi n pe fun idagbasoke awọn ọdọ atawọn eto amayedẹrun mii.
Awọn oluwọde bi ẹẹdẹgbẹta ni a gbọ pe wọn kora wọn jọ ni gbagede Beyers Naudé Square lati ibi ti wọn yoo ti rin lọ si Constitution Hill nibi ti wọn yoo ti ni gbolohun pẹlu ọga agba ileeṣẹ ọlọpaa Hillbrow.
Laarin ago mẹwaa owurọ si ago meji ọsan lawọn oluwọde naa yoo rin lati opopona Helen John lọ si opopona Troye, Twist, Kotze ati opopona Queen.
Ko din ni ẹgbẹrun kan ati igba oluwọde ti a gbọ pe wọn o peju sibi ifẹhonuhan ti ajọ oṣiṣẹ LACO ṣe agbatẹru rẹ.
Wọn fẹ lo iwọde naa gẹgẹ bi itaniji fun ileeṣẹ ijọba to n ri bawọn eeyan ṣe n wọle si orilẹede si orilẹede South Africa.
Ni Kotze lawọn olufẹhonuhan naa yoo kọkọ pejọ si ki wọn to kọwọọ rin lọ si Hillbrow.
Iwọde naa yoo waye laarin ago mẹsan an si ago mejila.
Ẹgbẹ ọdọ yoo tun ṣe agbatẹru iwọde mii lati pe fun iṣẹ ṣiṣe fawọn ọdọ ni Midrand.
Bi ẹgbẹrin oluwode ni a gbọ pe yoo pejọ lopopona Dale Road ati Modderfontein ki wọn to kọwọọ rin lọ.
Laarin ago mẹwaa si mejila ni iwọde yoo fi waye.
Awọn ẹṣọ eleto aabo duro wamuwamu lawọn agbegbe ti iwọde ti waye ni South Africa
Ileeṣẹ ọlọpaa ti ko awọn agbofinro si gbogbo ibi ti iwọde tako awọn ọmọ ilẹ okeere yoo ti waye lonii ni South Africa.
Iwọde naa ni wọn fi sọ ori gbedeke ọgbọnjọ oṣu Kẹfa yii ti wọn ni kawọn ọmọ ilẹ okeere ti ko ni iwe igbeluu kuro ni South Africa.
Ọpọ awọn ọmọ ilẹ okeree to wa ni South Africa ni wọn ti kuro ṣaaju gbedeke ọgbọnjọ oṣu Kẹfa yii.
Ọmọ orilẹede Malawi kan ti ko niwe igbeluu sọ fun BBC wi pe inu oun dun lati maa pada sile pẹlu ọmọ mẹrin.
Ileesẹ ọlọpaa sọ pe eeyan marun un lawọn fọwọ ofin mu ni Johannesburg lori ẹsun pe wọn fẹ jale lawọn ṣọọbu awọn eeyan ilẹ okeere kan ni Soweto.
Bakan naa ni wọn tun mu awọn marun un mii ni ẹkun Hammarsdale in KwaZulu-Natal.
Ọpọ ile itaja ni wọn gbe tipa laarin gbungbun ilu Durban.
Ọmọ ilẹ okeere to le ni miliọnu mẹta to wa ni akọsilẹ ijọba lo wa ni orilẹede South Africa.