Ní bíi ọdún kan tí ọlọ́pàá yìnbọn pa èèyàn mẹ́ta nibi ìsìnkú Olóòtú ìjọba Kenya tẹ́lẹ̀, ìwádìí BBC jáde nipa ìṣẹ̀lẹ̀ náà

Àkọlé fídíò, "Ọpọ eeyan lo wa nibi isinku naa, o se wa jẹ oun ni wọn pa"
Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Eeyan mẹta to n se ọfọ lo ku lasiko tawọn ọlọpaa ilẹ Kenya da ibọn bolẹ lasiko ayẹyẹ idagbere fun olootu ijọba tẹlẹ, Raila Odinga.

Iwadii ẹka ọtẹlẹmuyẹ BBC finmu-finlẹ lori isẹlẹ naa, ti a si ri daju pe awọn eeyan mẹtẹẹta to ku naa kii se ara awọn eeyan to n se iwọde eyi to mu ki awọn ọlọpaa maa yinbọn nibẹ.

Lasiko ti wọn n se ẹyẹ ikẹyin fun Odinga losu kẹwaa yii, eeyan mẹta ni ibọn pa lasiko ti wọn n gbe igbesẹ lati fi tipa raye aaye wọle si aaye ijoko awọn ọlọla ni papa isere Kasarani.

Alaye ikọ ọtẹlẹmuyẹ BBC latinu papa isere idaraya naa fihan pe ikọọkan awọn eeyan to ku naa lo rin jinna si bii ọgọta mita sibi ti iporogan ti n waye.

Minista fọrọ abẹle nilẹ Kenya, Kipchumba Murkomen sọ fun BBC pe bawọn ero se n ju okuta lo mu ko sediwọ fun isẹ tawọn ọlọpaa n se.

Ninu fidio ti BBC se atupalẹ rẹ, o fihan pe wọn n ju awọn eroja kan, to fi mọ aga onike amọ a ko ni ẹri pe okuta wa lara eroja ti wọn n ju.

BBC se agbeyẹwo awọn aworan ati fidio to to ẹẹdẹgbẹjọ lati mọ ibi tawọn eeyan ti ibọn pa naa duro si lọjọ Kẹrindinlogun osu kẹwaa ọdun 2025, ti a si tun ba diẹ lara awọn ẹbi wọn sọrọ.

Ayẹwo awọn onimọ ijinlẹ nipa isẹlẹ naa, ti BBC se agbatẹru rẹ daba pe o seesee ko jẹ pe ẹka awọn ọlaju ọlọpaa to n daabo bo aarẹ, lo yin awọn ibọn naa.

Skip podcast promotion and continue reading
BBC News Yorùbá ti wà lórí WhatsApp
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Olori ẹgbẹ alatako ati Olootu ijọba tẹlẹ to tii pẹjulọ nipo lo ku ni ọjọ keji asiko to n gba itọju nilẹ India.

O si tun jẹ ọkan lara awọn oloselu to laami laaka julọ ni orilẹede naa.

Lẹyin ọdun kan, ẹka ileesẹ ọlọpa ilẹ Kenya, the Independent Policing Oversight Authority (IPOA), si n se iwadi lọ lori iku awọn eeyan naa, ohun tawọn ọlọpaa sọ, ti ko si si ẹni ti wọn tii finmu rẹ jofin lori isẹlẹ naa.

Amọ Minisita fọrọ abẹle gbe ileesẹ ọlọpaa lẹyin isẹ ti wọ wọn lọrun pupọ ju, bi wọn se gbe wọn lọ sagbegbe mii lẹyin ti wọn ti sisẹ fun ọpọ wakati lai dawọ duro

"Ẹka to n se akoso ileesẹ ọlọpaa to ni ominira tiẹ lo n se iwadii isẹlẹ naa, a si ro pe abọ iwadii wọn yoo ran wa lọwọ lati gbe igbesẹ to yẹ labẹ ofin." Murkomen lo sọ bẹẹ.

Nigba to n dahun ibeere lori ihuwasi awọn ọlọpaa, o ni: "N ko ro pe ... eeyan kan joko sibẹ, ko si maa sọ pe: "Ẹ yinbọ bayii".

Ipinnu oju ẹsẹ lọdọ awọn osisẹ ọlọpaa ni igbesẹ naa."

Yvonne Akinyi, ti ọkọ rẹ wa lara awọn eeyan ti wọn yinbọn pa sọ fun BBC pe: "Awọn eeyan ti a n wo pe ki wọn daabo bo wa, lo wa n pada mu inira ba wa.

Awọn eeyan yii lo sọ wa di opo ni kekere aye wa lorilẹede yii, opo kekere ni orilẹede"

Iku Odinga lẹni ọgọrin ọdun lo mu ibanikẹdun ati ọfọ nla waye nilẹ Kenya.

Ẹgbẹlẹgbẹ ero si lo pejọ si papakọ ofurufu Jomo Kenyatta to wa nilu Nairobi nibi ti wọn ti fi baalu gbe oku rẹ de si.

Saaju ni wọn ti kede pe wọn yoo tẹ oku rẹ nitẹ ẹyẹ nile asofin apapọ, amọ obitibiti ero ati ibẹru dida eto aabo ru lo mu ki wọn yi ipinnu wọn pada nipa ibi ti eto naa yoo ti waye, lọ si papa isere idaraya Kasarani.

Awọn alasẹ naa ni awọn ko ni akoko to to lati gba ibudo to le gba to eeyan ẹgbẹrun lọna mejidinlaadọta, ti ẹgbẹlẹgbẹ si lọ sori papa igbabọọlu ati ibudo naa lai kọja labẹ abẹwo.

Lẹyin ti wọn duro fun ọpọ wakati lati wo oku naa labẹ oorun to mu hanhan to sẹntigiri ọgbọn, tawọn alasẹ ko si ba wọn sọ ohunkohun, se ni diẹ lara awọn ero naa bẹrẹ si ni ju awọn eroja kan, to fi mọ aga onike, mọ awọn agbofinro to n sọ ibi tawọn ọlọla joko si.

Amọ fidio kan to safihan awọn agbegbe miran ninu papakọ ofurufu naa lo fi han pe se lawọn ero naa wa nidakẹ jẹjẹ.

Ọkan lara wọn ni Evans Kiche, tii se aseounjẹ, ẹni ogoji ọdun, to si bi ọmọ meje.

Atupalẹ iroyin BBC afihan pe o to ọgọta mita sibi ti ọkunrin naa wa, ti rogbodiyan ọhun ti n waye, amọ ti ibọn lọ ba a lori, to si ku.

Awọn eeyan meji yoku to ku ni Vincent Ogutu ati Jidah Burka, ti wọn rin jinna kọju sira wọn bii ọgọjọ mita, lai sun mọ aarin papa ti iporogan ti n waye.

Aworan Evans Kiche, wọ asọ shaati alawọ pupa ati buluu, Vincent Ogutu wọ shaati alawọ eeru ati Jidah Burka wọ asọ isere bọọlu alawọ buluu, o de fila, to si ni irungbọn
Àkọlé àwòrán, Evans Kiche (apa osi) ati Jidah Burka (apa ọtun) ni wọn yinbọn fun lori, nigba ti Vincent Ogutu (to wa ni aarin) ni wọn yinbọn fun ni aya
Aworan agbegbe tawọn ọlọla n joko si ati ibudo mẹta ti awọn eeyan ti ibọn pa wa

Ayẹwo awọn oku naa fidi rẹ mulẹ pe Ogutu ku lati ipasẹ ọta ibọn to ba a laya, ti Burka, ẹni ọdun mejilelogoji si ku tori ọta ibọn to ba lori.

Ti a ba to awọn akoko ti isẹlẹ naa waye papọ, ẹka ọtẹlẹmuyẹ BBC, ti a mọ si BBC Africa Eye, le tọkasi ọlọpaa mẹjọ ti wọn n sisẹ papọ, ti wọn wọ asọ ọlọpaa ai Khaki ologun.

Awọn osisẹ yii lo gbe ibọn lọwọ, ti wọn ko si ni ami idamọ kankan lara wọn tabi bo oju wọn.

Asọ ẹgbẹjọda wọn ati irinsi wọn jọ tawọn ọlọpaa to n sọ aarẹ William Ruto atawọn eeyan pataki miran. O kere tan, ọlọpaa mẹta ni ẹka yii lo jọ pe wọn yin ibọn wọn.

BBC da mẹta ninu wọn mọ gẹgẹ bii ara ọlọpaa to n sọ awọn eeyan pataki, ti wọn si wa lati daabo bo aarẹ.

BBC ko le fidi awọn ọta ibọn to pa ikọọkan awọn oloogbe mẹtẹẹta mulẹ, ti a ko si le fi ọrọ rọ sẹyin pe awọn ọlọpaa miran ninu papa isere idaraya naa, le yinbọn.

Ileesẹ ọlọpaa nilẹ China sọ fun BBC pe: "Ẹkọ nla wa ti a kọ lati ara isẹlẹ naa," eyi to "se agbekalẹ ẹkọ nla fun wa lati sisẹ wa nilana akọsẹmọsẹ lọjọ iwaju."

Amọ ẹka ọlọ̀paa to n sọ awọn eeyan pataki, IPOA ko fesi si ibeere wa lati jẹ ki wọn fesi lori isẹlẹ naa.

Aworan to gbooro nipa papa isere idaraya naa. Ọpọlọpọ awon eeyan lo doju bolẹ tabi maa sare kiri ori papakọ naa
Àkọlé àwòrán, Ibọn yinyin naa lo da ibẹru bo awọn omilẹgbẹ eeyan to wa ninu papa isere idaraya naa

Ogutu, tii se ẹni ọdun mẹrindinlogoji ati baba ọmọ mẹta ni ko ni lero saaju lati lọ si papakọ isere idaraya Kasarani , gẹgẹ bi iyawo rẹ ti sọ fun BBC.

Aarin gbungbun ilu Nairobi lo wa laarọ ọjọ kẹrindinlogun osu Kẹwaa pẹlu awọn ọrẹ rẹ, ki wọn to wa dara pọ mawọn obitibiti ero to n lọ si papa ere idaraya naa.

Laarin wakati diẹ si asiko naa, lo si ku.

Opo oloogbe naa, Yvonne Akinyi sapejuwe bi ipaniyan naa se sọ idile rẹ sinu ibanujẹ, tawọn ọmọ wọn si di alainibaba.

Nibayii to n palẹmọ lati sami ọdun kan ti ọkọ rẹ ku, ko tii ye Akinyi idi ti ọkọ rẹ fi ku lasiko to lọ sibi ayẹyẹ ikẹyin tijọba seto rẹ.

"Mo n tiraka lati jẹ akọni obinrin. Alagbara pupọ. Amọ ninu mi, iho nla wa nibẹ."

"O jẹ ohun irora nla fun mi ntori nigba miran, maa kan jokoo, maa maa bi ara mi leere pe, sebi ni papa isere idaraya Kasarani, ọpọlopọ eeyan lo wa nibẹ. Ki wa de to fi jẹ ọkọ mi ni iku pa."