Èyí lohun tí MC Oluomo, Sego sọ̀rọ̀ lórí ikú tó pa Toba Ijaya, akọ̀wé NURTW ní ìpínlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, Facebook
Agbebọn ti yinbọn pa akọwe ẹgbẹ awọn awakọ, NURTW, nipinlẹ Eko, Toba Ajiboye, ti ọpọ eeyan mọ si Ijaya.
Iroyin ni asiko ti oloogbe naa n bọ lati ile ọrẹ korikosun rẹ kan ni adugbọ Fadeyi ni ikọlurẹ waye.
A gbọ pe awọn agbebọn naa kọlu Ajiboye loju ọna marosẹ Ikorodu nibi ti wọn ti ṣina ibọn fun ọkọ rẹ ti ọta ibọn si wa lara ọkọ ọhun.
Awọn fidio ati aworan to n milẹ titi lori ayelujara ṣafihan ọkọ naa pẹlu oniruru ọta ibọn lara n ati iwaju gilaasi rẹ.
A kọkọ gbọ pe Ijaya atawọn mii ti wọn wa ninu ọkọ naa moribọ ninu ikọlu ọhun amọ o fara gbọta ibọn.
Lẹyin naa ni a gbọ pe akọwe NURTW naa pada dagbere faye latari ọta ibọn to far agba.
MC Oluomo sọrọ lori ikọlu naa
Ẹwẹ, alaga gbogbogbo fun NURTW, ni Naijiria, to tun jẹ alaga ajọ NURTW nipinlẹ Eko tẹlẹ, Musiliu Akinsanya ti ọpọ mọ si MC Oluomo ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu ati iku ọkunrijn ọhun.
Oluomo juwe bi wọn ṣe gbẹmi rẹ gẹgẹ bii ohun to buru jai ati eyii ti ko ṣe itẹwọgba.
Lẹyin naa lo ke si ileeṣẹ ọlọpaa Naijiria lati ṣe iwadii ni kikun lori iṣẹlẹ naa ko si fi imu gbogbo awọn to ṣiṣẹ ọhun danrin.
Ninu iroyin kan naa, alaga NURTW nipinlẹ Eko, Mustapha Adekunle, ti ọpọ mọ si Sego naa tun ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa.
Ninu atẹjade kan to fi lede loju opo Facebook rẹ, o ni "Iroyin iku ojiji nipa Toba Ajiboye ba inu mi jẹ gidi. O ṣoro fun mi lati gbagbọ pe irufẹ eeyan bẹẹ to jẹ alabarao ati ẹni to ṣee gbọkan le ti lọ."
O juwe ọkunrin naa gẹgẹ bii ọrẹ oun, ẹni ti kii ja eeyan kulẹ ati ẹni to fi ara rẹ jin fun ẹgbẹ awọn awakọ, NURTW.
Ki ni ọlọpaa sọ?
BBC Yoruba gbiyanju lati kan si ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko lori ọrọ naa amọ gbogbo igbiyanju wa lo ja si pabo.
Amọ ṣa, ileeṣẹ iroyin Vanguard jabọ pe alukoro ileeṣẹ naa, Abimbola Adebisi sọ pe awọn alaṣẹ ti ke si awọn akọṣẹmọṣẹ ọlọpaa lati bẹrẹ iwadii lori ọrọ naa.
Iroyin Vanguard sọ pe ọlọpaa ni "Iwadii n lọ lọwọ lori awọn to ṣiṣẹ ibi naa, ileeṣẹ ọlọpaa tun ti fi awọn oṣiṣẹ rẹ ṣowọ si awọn ibi to ṣe pataki laarin ilu lati ri daju pe awọn kan ko da ilu ru."



























