Egúngun tó lé obìnrin kan láì dẹ̀yìn jìyà àjẹpọ́nnulá; Obìnrin náà ṣíṣọ lójú rẹ̀ níta gbangba ló bá di ọkọ rẹ̀

Aworan eegun kan to fi ewe ọgẹdẹ gbigbẹ bo ara rẹ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Ko si ohun to gbọdọ ṣe eegun ti awọn oju rẹ yoo fi ṣi nita gbanga. Eewọ ni wọn ka a si nibi gbogbo ti wọn ba ti mọ nipa ọ̀jẹ̀.

Eyi ri bẹẹ nitori igbagbọ awọn to mọ ọn ni pe oriṣa to ti ode ọrun wa ni eegungun jẹ, aṣiri rẹ ko si gbọdọ tu debi ti yoo fi di eeyan lojude gbangba.

Amọṣa ki lẹ o ṣe ti eegun kan ba n ko ọrẹ boyin ti ẹ si n sa fun un ṣugbọn ti ko sinmi?

Lootọ awọn agba bọ wọn ni ti egungun ba n le ni ka maa rọju, bo ṣe n rẹ ara aye lo n rẹ ara ọrun, ṣugbọn nigba ti ẹda ba sare fun egungun tiegungun naa ko dẹyin, bo pẹ boya yoo doju kọ eegun bẹẹ ni o.

Ohun to ṣẹlẹ si arabinrin abilekọ kan ree laipẹ yii to fi ba eegun wọ iya ija, lẹyin - o - rẹyin to si ja irawọ eegun kan nita bayii. O ba eegun wọya ija nikan kọ, o tun ṣi awọn oju rẹ pẹlu.

Amọ nigba to ṣi agọ ori egungun naa tan, kayeefi lohun to ri.

Nibo ati bawo lo ṣe ṣẹlẹ gan-an?

Ilu kan ti wọn n pe ni Uhunowerre, nijọba ibilẹ Ariwa Igbo-Eze, Nsukka nipinlẹ Enugu ni iṣẹlẹ yii ti waye lọjọ Aje ọsẹ yii.

Egungun ti iṣẹlẹ abuku naa kan ni wọn pe orukọ rẹ ni Omebe, a gbọ pe egungun to fẹran jagidijagan ni.

Gẹgẹ bi awọn fidio to ṣafihan ohun to ṣẹlẹ ṣe fi han lori ayelujara, obinrin kan n lọ soko ni, o si pade egungun Omebe loju ọna.

Bi eegun naa ṣe ri obinrin yii lo kọlu u, o si bẹrẹ si i lu u pẹlu igi nla kan.

Obinrin naa ko kawọrọ bi eegun ṣe n lu u, oun naa bẹrẹ si I ba a ja.

O lu eegun debi to lapẹẹrẹ, o si ṣe bẹẹ ṣi awọn ti eegun Omebe da bo oju rẹ.

Àṣé ọkọ obinrin naa lo wa labẹ ẹ̀kú egungun

Nibi ti ija ọhun lagbara de, awọn ara abule pe jọ lati la wọn, ṣugbọn eegun ati obinrin to n ba a wọya ija ko fi ara wọn silẹ.

Nibi ti ija naa ti n lọ lọwọ ni obinrin yii ti ṣi awọn loju eegun Omebe, nigba naa lo si ri I pe ọkọ oun lo wa labẹ ẹku!

Eyi lo ya ọpọ eeyan lẹnu ti wọn si n beere pe ki lo le ṣẹlẹ ti ọkọ yoo gbe eegun, ti yoo pade iyawo rẹ lọna ti yoo si bẹrẹ si I fi igi nla lu u.

Bawọn kan ṣe n sọ pe boya iyawo naa ti ṣẹ ọkọ rẹ tẹlẹ nile ni ọkọ ṣe gbe ẹku eegun Omebe wọ lati fiya jẹ ẹ.

Bẹẹ lawọn mi-in sọ pe eewọ nla ni nilẹ Igbo ki iru nnkan bayii ṣẹlẹ.

Wọn ni iyawo to ṣi eegun loju yii yoo nilati jẹ iya rẹ, bo ti wu ko jẹ ọkọ rẹ lo ru ẹku Omebe to.

"Ijiya nla ni yoo koju obinrin to ṣi aṣọ loju eegun, koda, o le ni lati pada sile awọn obi rẹ"

Baba agba kan lati Nsukka, Alagba Augustine Attah, ṣapejuwe ohun ti iyawo naa ṣe bii eewọ nla.

O ni ninu aṣa ilẹ awọn, obinrin naa yoo koju ijiya gidi fun ohun to ṣe, ko le baa jẹ ẹkọ fun awon eeyan mi-in.

Alagba Attah sọ pe bo tiLẹ jẹ pe ọkọ rẹ lo wa ninu ẹku, yoo ṣi jiya bii ki wọn le e kuro niluuu, ki wọn ni ko sanwo itanran, tabi ki wọn tiẹ le e danu nile ọkọ naa, ki wọn le e sọdọ awọn obi rẹ.

Gbogbo eyi le waye fun iyawo naa gẹgẹ bii ẹni ti ko mọ pe awo egungun wa, to si dan ohun ti ko gbọdọ ṣẹlẹ wo fun eegun.

Bakan naa ni ọmọ bibi ilu Nsukka kan, Emeka Omeje, sọ pe o dun oun pe aye ti yipada si bo ṣe wa nigba iwaṣẹ.

O ni to ba jẹ laye ọjọun-un ni, obinrin ko ni i dabaa ati rin niwaju egungun, debi ti yoo ni oun fẹ ba a ja.

Eyi ni wọn lo fa a ti wọn ko fi ki n pe obinrin si ọrọ egungun nilẹ Igbo, ti wọn ko si ki n jẹ ki wọn mọ awo tawọn ọ̀jẹ̀ n ṣe.