Yàtọ̀ sí oyún ìbejì,mọ̀ nípa bí obìnrin ṣe lè lóyún méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú kan ṣoṣo

Ajulọ ti ko lopin ni Aṣẹda ni lori awa ẹda rẹ to da, awọn nnkan mi-in a si jọ kayeefi to ṣoro lati gbagbọ ninu àrà ti Eledumare n da, amọ bo ṣe ri gẹlẹ niyẹn, koda ti imọ ijinlẹ ko le yi i pada.
Iru rẹ ni ti ki obinrin ti loyun, ki ara rẹ ma pese ẹyin mọ nitori oyun naa, ṣugbọn ki ara yii kan naa tun pada pese ẹyin ninu oyun ọhun, ki atọ ọkunrin kàn an ko si pada di ọlẹ̀ keji ninu ara obinrin to ti loyun naa.
Eyi ni oloyinbo n pe ni Superfetation.
Bawo ni Superfetation, liloyun ninu oyun ṣe n waye?
Gẹgẹ bawọn dokita ṣe fidi ẹ mulẹ, oyun ninu oyun yii yatọ si oyun ibeji.
Bo ṣe maa n ṣẹlẹ ni pe obinrin ti ara rẹ ko pese ẹyin mọ nitori o ti loyun, yoo kan deede tun pese ẹyin ninu oyun naa.
Bi atọ okunrin ba pade ẹyin keji yii, yoo di ọmọ. Nigba naa ni oyun keji yoo bẹrẹ si i dagba pẹlu eyi to ti wa ninu, bo tilẹ jẹ pe ọmọ to ti n dagba ninu tẹlẹ yoo gberu ju eyi to ṣẹṣẹ duro lara oloyun naa lọ.
Iwadii fidi rẹ mulẹ pe iru oyun bayii ko wọpọ, ewu si ni fun alaboyun to ba ni in.
Yoo nilo itọju gidi ninu oyun naa, iṣẹ abẹ ni wọn si maa n fi gbẹbi iru rẹ, bẹẹ ni ọmọ keji to kere yoo ni lati maa dagba ninu igo ko too pada di ọmọ gidi bi Aṣẹda ba yọnda.





