Télọ̀ kan ju èké fídíò nípa ìkọlù agbébọn l‘Ogun sórí ayélujára láti pawó, ọ̀rọ̀ bá bẹ́yìn yọ fún-un

Telo to n ranṣọ, o dori kodo, bọ bata rẹ si ẹgbẹ kan .

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Telọ kan, Qawiyu Oloyede, ni ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti fọwọ ofin mu bayii, fun ẹsun pe o gbe fidio ikọlu awọn agbebọn ti ki i ṣe otitọ jade sori ayelujara.

Iwa ti Qawiyu wu yii ni awọn ọlọpaa ṣọ pe o ko ipaya ba araalu, to si jẹ pe o ṣe bẹẹ lati le fi ni ọpọ ero loju opo ayelujara rẹ ni.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, DSP Oluseyi Babaseyi to fidi ẹ mulẹ, pe awọn ti mu Qawiyu si atimọle, tun ṣalaye pe fidio ti telọ naa gbe kalẹ lọwọ ara rẹ lo ju sori ayelujara bii otitọ.

Alaye ọlọpaa

Ninu fidio naa ni wọn ti ṣafihan ikọlu kan , ti wọn si n sọ pe awon agbebọn ti wọ Atan Ota, ipinlẹ Ogun.

Ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe iwadii pada fi han, pe fidio ti ẹnikan mọ ọn mọ gbe kalẹ lọwọ ara rẹ ni ikọlu naa, ki I ṣe pe ikọlu ọhun waye ni tootọ.

Wọn ni o gbe e kalẹ lati tun ko ipaya ba araalu, pẹlu bi aibalẹ ọkan ṣe n waye lọwọ latari awon agbebọn to n ji eeyan gbe ti wọn si n pa wọn lorilẹede yii.

DSP Babaseyi sọ pe afurasi naa ti wa ni ẹka awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ nipinlẹ Ogun, fun itẹsiwaju iwadii ati bi yoo ṣe foju balẹ ẹjọ.

Iwa ọdaran to lagbara leyi gẹgẹ bi Babaseyi ṣe ṣalaye , nitori o le da omi alaafia ilu ru.

O rọ araalu lati maa ṣewadii ohun ti won yoo maa pin lori ayelujara daadaa ki wọn too maa pin in ka.

Ẹni to ba pin irọ lori ayelujara yoo jiya labẹ ofin ni Alukoro ọlọpaa Ogun sọ.

Mo gbe fidio irọ naa jade ki n le ni ero pupọ loju opo Tiktok mi ni - Qawiyu

Ninu fidio kan lori ayelujara, Qawiyu to n ṣe iṣẹ aranṣọ niluu Atan Ota, nipinlẹ Ogun, n jẹwọ ẹṣẹ rẹ fun awọn ọlọpaa.

Ninu fidio naa lo ti ni:

"Mo gbe ikọlu irọ naa kalẹ mo si ju u sori ayelujara Tiktok mi ki n ba le ni ero pupọ loju opo mi.

"Mi o mọwe, mi o le kawe, bẹẹ ni mi o le kọ.

"Mi o lọ sile ẹkọ, ọmọọṣẹ mi lo kọ awọn ọrọ to tẹle fidio yẹn."

Qawiyu fi kun un pe fidio to pada kari ayelujara yii kọ ni akọkọ iru ẹ ti oun ju safẹfẹ, o ni oun ti ju iru rẹ meji jade ṣaaju lọsẹ to kọja.

O tẹsiwaju pe darandaran kan to han ninu fidio yii ko mọ pe o wa nibẹ rara.

Aranṣọ yii sọ pe darandaran naa maa n da ẹran rẹ kọja lẹyin ṣọọbu oun, ko si mọ pe oun ti ka a silẹ ninu fidio naa.

O ni oun tilẹ ti kọkọ sọ fun un ri pe ko waa farahan ninu fidio, ṣugbọn darandaran naa kọ jale, ko too di pe oun ya a mọ fidio nigba ti ko mọ rara.

Afurasi to ti wa ni ahamọ bayii sọ pe aimọwe lo ko ba oun, o loun ko mọ pe oun to le bẹẹ ni oun danwo.

"Ẹ jọọ ẹ forijimi, aṣọ awọn onibaara mi ti mo fẹ ran fun ọdun Ileya ṣi wa ni ṣọọbu mi"

Qawiyu Oloyede lasiko to n jẹwọ fun ọlọpaa

Oríṣun àwòrán, Screenshot

"Ni itẹsiwaju alaye rẹ, Qawiyu bẹbẹ pe ki ijọba foriji oun.

Telọ naa sọ pe awọn aṣọ tawọn eeyan gbe foun lati ran fun ọdun Ileya to wọle de ṣi wa ninu ṣọọbu oun toun ko ti i ran.

"Mo ṣe fidio naa lati fi ṣe kọntẹnti bawọn eeyan ṣe maa n ṣe ni.

"Mo ṣe e nitori mo ri I bawọn eeyan ṣe n fi fidio pawo lori ayelujara ni, ọmọọṣẹ mi ni mo ni ko ba mi ya a."

Bẹẹ ni telọ to n wa awijare pẹlu ẹbẹ naa wi, ṣugbọn ileeṣẹ ọlọpaa ni aimọ ki I ṣe awijare.

Wọn lo di dandan ki Qawiyu to fẹ di gbajumo ojiji to si fẹẹ gbabẹ pawo sapo koju ofin ijọba.