Wo ọ̀nà márùn-ún tí àwọn ọ̀dọ́ lè máa gbà rí owo gọbọi

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Owo ṣe koko laye, atọmọde atagba lo nilo rẹ lati gbe igbesi aye irọrun. Ai si owo lọwọ lo n mu ijaya wa, owo n bẹ nile ni baba alaafia ara.
Amọ ọna wo leeyan le gba rowo bi ko ṣe nipa iṣe aje, ẹni ti ko ba ṣe ko ni i ri nnkan kan jẹ.
Bi eeyan tiẹ ba ọla nile paapaa, to ri ogun gidi to le sọ di owo jẹ lọdọ awọn obi rẹ, dandan tun ni ko ṣiṣẹ kun un ki ọrọ naa ma baa parun.
Amọ lasiko yii ti aye ti yi pada kuro ni ti igba atijọ, to di pe ọpọ awọn ọdọ asiko yii ko fẹ iṣẹ gidi kan lati ṣe, ọla idile tabi ajogunba ọrọ̀ le parun bi eeyan ko ba ṣọra.
Lati dena pipa ọla ẹbi run, ati ki eeyan le da ọla tiẹ naa ni, BBC kan si Ọmọwe Isma'il Muhammad Anchau, olukọ agba ni College of Science and Technology, Kaduna.
O ṣalaye ọna marun-un ti ọdọ le tọ lati di ọlọrọ laaye ara wọn.
Amọ o ni imọ, iṣẹ ọwọ, ifarada, suuru ati gbigba ọna ododo wa owo lo ṣe koko julọ.
Wọnyi ni awọn ọna marun-un to la kalẹ
1 – Ẹkọ iṣẹ ọwọ̀
Ninu alaye Ọmọwe Isma'ila Muhammad Anchau, o ni ohun akọkọ ni pe ki eeyan kọkọ wo ibi to ti jade wa, ko si beere lọwọ ara rẹ pe ṣe Abọlanle loun ni abi ọmọ atapata dide, bo si ṣe atẹrọfọdide ni.
O ni ki eeyan tun beere lọwọ ara rẹ bo ṣe ni imọ si.
Idahun si awọn nnkan wọnyi lo ni yoo jẹ igbesẹ akọkọ ti yoo ran ọdọ lọwọ lati wa ọna ọla.
Nipa ti iṣẹ ọwọ to yẹ lati mọ nipa rẹ, Ọmọwe Anchau ka awọn wọnyi:
Ẹkọ nipa imọ ẹrọ kọmputa (ICT)
Bi wọn ṣe n tun foonu ṣe.
Fọto yiya ati lilo kamẹra fi ka nnkan silẹ bii fiimu (Videography).
Aṣo riran, iṣẹ jorin-jorin, kafinta ti Yoruba n pe ni gbẹnagbẹna ati bẹẹ bẹẹ lọ.
2 – Òwò ṣiṣe
Ọna ọla mi-in bi Ọmọwe Anchau ṣe la a kalẹ fawọn ọdọ ni owo ṣiṣe. Awọn ohun to ni o le tete pawo ni:
*Karakata lori ayelujara
*Tita awọn nnkan eelo ko ṣe maa jẹ, ko ṣee ma lo lojumọ.
*Ṣiṣe ọgbin tabi ọsin awọn ẹran ile labọọde ti yoo pada gbooro.
3) Imọ ẹrọ fawọn to kawe
Pe awọn eeyan ni ẹkọ iwe maa n ran wọn lọwọ bi wọn ba fẹ kọ nipa ayelujara, ju awọn ti ko kawe lọ gẹgẹ bi Ọmọwe Anchau ṣe wi.
O ni awọn ọdọ to kawe yatọ si awọn ti iwe wọn ko pọ tabi ti wọn o tiẹ kawe rara.
Fun idi eyi, anfaani ati tete fi ẹkọ imọ ẹrọ ri owo wa fun awọn kan ju awon kan lọ ninu wọn.
Lati fi imọ ẹrọ asiko yii maa ri owo, o ni ki ọdọ kẹkọọ nipa
Awọn oju opo kọmputa (computer programming).
Okoowo ori ayelujara (Digital marketing).
Gbigbe awọn eto atinuda jade lori ayelujara (Content creation).
Ṣiṣe iṣẹ ọnà pẹlu aworan(Graphic design).
Imọ nipa akọsilẹ, onka ọlọkan-o-jọkan (Data analysis skills).
4 – Fifi owo pamọ ati kikowo le ori okoowo mi-in
Ọmọwe Anchau sọ pe ọna meji ọtọọtọ ni eeyan fi n kowo le ori okoowo ti yoo si tun maa ri owo fi pamọ.
Akọkọ ni fifi apa kan pamọ lara owo to n wọle deede.
Ikeji ni kikowo le ori okoowo to ba ofin mu lẹyin ti o ti mọ nipa rẹ denudenu.
5) Ni ajọsẹ to daa pẹlu awọn eeyan
Lakootan, olukọni agba naa sọ pe o ṣe pataki lati ni ajọse to daa pẹlu awọn eeyan.
Ni ajọsọ pẹlu awọn ọga lẹka okoowo rẹ.
Maa lọ si idanilẹkọọ awọn akọṣẹmọṣẹ lẹka to o ti n pawo wọle.
Maa kan si awọn akọṣẹmọṣẹ to ṣee fi ọrọ lọ.
Awọn ohun to yẹ ki o yago fun nibi to o ti n sare owo
Ero lati di olowo kia lai ṣiṣẹ.
Jibiti tabi fifi ọna èrú wa owo.
Ninawo ju ohun to n wọle fun ọ lọ.
Kikọ ohun to n pawo fun ọ silẹ tabi ki eeyan kọ̀ lati kọ ẹkọ tuntun ni awọn nnkan ti Ọmọwe Anchau ka bii eewọ fun ọdọ to fẹ lowo tiẹ lọwọ.



























