"Ẹ gbà mí o! Owó onírú owó oníyọ̀ ni mo fi tọ́ ọmọ mi tí wọ́n jí gbé"

"Ẹ gbà mí o! Owó onírú owó oníyọ̀ ni mo fi tọ́ ọmọ mi tí wọ́n jí gbé"
Published

Ọkan lara awọn obi awọn agunbanirọ lati ilu Ibadan tawọn janduku agbebọn ji gbe, Omotoso Adewale, ti rawọ ẹbẹ si ijọba atawọn ẹṣọ eleto lati doola awọn ọmọ naa lọwọ ajibigbe.

Ọgbẹni Adewale sọ fun BBC Yoruba wi pe ni agbegbe Samonda ni ọmọ oun to n lọ sinruulu nipinlẹ Abia ti wọ ọkọ ki o to bọ sọwọ awọn ajinigbe.

Agbẹnusọ ọlọpaa Imo, Okoye Henry sọ pe opopona Owerri si Onitsha ni wọn ti ji awọn agunbanirọ naa gbe.

Ọgbẹni Adewale ṣalaye pe ọmọ oun ko gbe ago rẹ nigba toun pe e lori foonu lati aarọ to fi di alẹ Ọjọru tii ṣe ọjọ kinni oṣu Kẹwaa yii.

O ni lẹyin naa loun lọ si ibudokọ ti o ti wọ ọkọ lọ sibi to ti fẹ sinruulu nibi ti wọn ti sọ fun un pe awọn janduku agbebọn ti ji ọmọ naa gbe pẹlu awọn akẹgbẹ rẹ.

Adewale ni lati igba naa loun ti n pe e lori foonu amọ ipe naa ko lọ mọ.

''Ijọba ẹ gba wa o, owo oniru owo oniyọ ni mo fi tọ ọmọ mi tawọn janduku agbebọn ji gbe.

Emi yoo rọ ijọba wi pe ki wọn jẹ ki onikaluku maa sinruulu ni ẹkun rẹ.

Mi o tii jẹun lati igba ti wọn ti ji ọmọ mi gbe, bakan naa ni mi o le sun,'' Adewale lo sọ bẹẹ.

Obi miran ti ọmọ tiẹ wa naa wa nibẹ sọ pe ni nnkan bi ago marun un ni ọkọ to gbe awọn ọmọ naa lati Ibadan gbera.

Arabinrin naa sọ pe ṣadeede loun gbọ pe wọn ti ji wọn gbe, ti oun si bẹrẹ sii pe ọmọ naa, ṣugbọn ko fesi rara.

O ni gbogbo ero to wa ninu ọkọ to n gbe wọn lọ si Aba ni wọn ji gbe eyi ti ọmọ oun Kehinde naa wa lara awọn ti wọn gbe.

Arabinrin naa sọ pe ọkan lara awọn ọmọ to moribọ ninu bọọsi keji to ko awọn agunbanirọ lo ṣe fidio ọkọ ti Kehinde wa ninu rẹ eyi tawọn agbebọn ji gbogbo ero inu rẹ gbe lọ.

''Ọmọ mi ti pe mi lori ago, awọn ajinigbe naa si sọ fun wa pe ka wa aadọta miliọnu wa.

Wọn ni ọmọ kọọkan lawọn yoo gbe aadọta miliọnu lori wọn.

Iyẹn la n bẹbẹ si pe ki gbogbo eeyan ran wa lọwọ tori a o le da a ṣe, o kọja oye wa.''

A ti ń ṣiṣẹ́ láti gba ìtúsílẹ̀ àwọn àgùnbánirọ̀ tí wọ́n jí gbé ní ìpínlẹ̀ Imo - Ìjọba Oyo

Ijọba ipinlẹ Oyo ti kọminu lori awọn agunbanirọ to jẹ ọmọ ipinlẹ naa ti wọn ji gbe ni ipinlẹ Imo lasiko ti wọn n lọ lati lọ silẹ baba wọn.

Atẹjade ti Kọmiṣanna ipinlẹ Oyo, Dotun Oyelade fi lede sọ pe iroyin ijinigbe awọn agunbanirọ naa ba oun lọkan jẹ paapaa lasiko yii ti Naijiria n koju awọn ipenija nla kọja.

Ijọba ipinlẹ Oyo sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ ohun to buru gidi, ti awọn si n ṣiṣẹ pẹlu awọn ẹṣọ aabo, ijọba ipinlẹ Imo, awọn alaṣẹ ajọ agunbanirọ lati le gba itusilẹ awọn agunbnirọ naa ni kiakia.

Oyelade ninu atẹjade naa fi kun pe awọn ni ifarajin si gbigba itusilẹ awọn eeyan naa ni ayọ ati alaafia, ti awọn ko si ni ko aarẹ ọkan lati ti pe awọn eeyan naa pada sile wọn layọ.

O fi kun pe Gomina Seyi Makinde ti dari gbogbo awọn ohun to yẹ lati ṣawari awọn eeyan naa, to si tẹmpẹlẹmọ pe aabo ẹmi ati dukia awọn eeyan ipinlẹ Oyo lo jẹ ijọba logun yala ninu ipinlẹ naa tabi lẹyin odi.

Ijọba wa rọ ẹbi awọn agunbanirọ naa lati ṣe suuru pẹlu ijọba, ti ijọba si ṣọ aridaju rẹ lati tẹsiwaju pẹlu iwadii wọn lati gba awọn naa silẹ.

Bakan naa ni wọn rọ awọn ẹṣọ aabo lati pọn kun akitiyan wọn, ki wọn si foju awọn ọdaran to ṣiṣẹ ibi naa wina ofin.

Wọn ni gbogbo awọn alẹnulọrọ to wa lori iṣẹlẹ naa ni awọn n ba ṣiṣẹ lati dena irufẹ ijinigbe bẹẹ lọjọ iwaju.