Ọmogun Naijiria dóòlà èrò ọkọ̀ 33 lọ́wọ́ ajínigbé, bẹ́ sínú igbó láti fọ́wọ́ òfin máwọn jàndùkú agbébọn náà

Awọn ero ọkọ duro niwaju bọọsi, agbesunmọmi fi aṣọ boju

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ikọ ọmogun Naijiria ti wọn n pe ni Operation Fansan Yamma ti doola ero ọkọ mẹtalelọgbọn lọwọ awọn janduku ajinigbe nijọba ibilẹ Tsafe nipinlẹ Zamfara.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ologun, Ọgagun Aliyu Danja, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe lọsan an ọjọ Abamẹta ọjọ kẹjọ oṣu Kẹjọ ọdun yii ni ikọ ọmogun atawọn ọlọpaa doola awọn ero ọkọ naa loju ọna ti wọn ti n rinrin ajo lagbegbe Magazu nijọba ibilẹ Tsafe ni Zamfara.

Ọgagun Danja ni kete ti ikọ ọmogun naa gbọ nipa iṣẹlẹ ijinigbe ọhun ni wọn morile ibi ti ijinigbe naa ti waye ti wọn si bawọn agbesunmọmi to ti n gbe awọn ero ọkọ naa lọ sọrọ.

Ọgbẹni Danja ni bayii ni ikọ ọmogun doju ija kọ awọn ajinigbe naa eyi to mu wọn fawọn ero ọkọ ọhun silẹ ti wọn si sa wọ igbo lọ.

O ni lẹyin naa ni ikọ ologun naa doola gbogbo ero ọkọ mẹtalelọgbọn ọhun.

Lẹyin naa lawọn ikọ ọmogun bẹ sinu igbo lati ṣawari awọn janduku ajinigbe naa ti wọn fẹsẹ fẹ.

Ẹwẹ, ọga agba ikọ ọmogun Fansan Yamma ti wa gboṣuba rabandẹ fawọn ọmogun to doola awọn ero ọkọ naa lori bi wọn ti ṣe giri ti wọn si doola awọn eeyan naa lọwọ ajinigbe ti ẹnikẹni ko si ku tabi farapa.

Ọgagun to n dari ikọ naa ko ṣai fi da araalu loju wi pe ileeṣẹ ologun ko ni kaarẹ nipa pipese aabo fun araalu papaa julọ lẹkun iwọ oorun ariwa Naijiria.

Ileeṣẹ ologun tun wa rọ araalu lati fi to awọn ọmogun leti nigba kugba ti wọn ba kofiri awọn agbesunmọmi tabi ẹnikẹni to ba n ṣiṣẹ laabi nibi kibi.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post