Kí ló dé tí Ọlọ́pàá láti Kwara fẹ́ gbé 'Tani Olohun' ní Ibadan, ṣùgbọ́n tí Sunday Igboho fárígá?

Aworan Ta ni Olohun nigba ti n fipa gbe e.

Oríṣun àwòrán, screenshot

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Laaarọ kutu oni, ọjọ Iṣẹgun ni awọn ọlọpaa ya bo ile gbajumọ ori ayelujara to maa n sọrọ tako ẹsin nni, Abdulazeez Adegbola Ifatimileyin, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Tani Olohun.

Ile rẹ to n gbe niluu Ibadan, ipinlẹ Oyo lawọn ọlọpaa naa ti ko wọ aṣọ ti lọ ka a mọ, ti wọn si fẹẹ jii gbe lọ.

Ilu Ilorin tii ṣe ipinlẹ Kwara ni wọn sọ pe awọn ọlọpaa ọhun ti wa, pẹlu ọkọ bọọsi alawọ funfun ti ko ni nọmba idanimọ.

Kete ti awọn ọlọpaa ọhun ti de si adugbo ti Tani Olohun n gbe, la gbọ pe wọn ti gba ile rẹ lọ, ti wọn si ni ko tẹle awọn lọ si agọ awọn.

Ṣugbọn a gbọ pe loju ẹsẹ ni ọkunrin naa ti sọ pe oun ko le tẹle ẹnikẹni jade kuro ninu ile oun, ati pe imura wọn ko jọ ti ọlọpaa, bi ko ṣe pe oun fura pe wọn fẹẹ ji oun gbe ni.

Ninu fọnran ti ọkunrin naa gbe soju opo rẹ ni Facebook, eyi ti BBC News Yoruba ri, la ti ri nibi ti awọn ọlọpaa ọhun ti fi agidi gbe Tani Olohun, ti wọn si gbe jade kuro ninu ile rẹ.

Igba ti wọn de ibi ti wọn ti fẹẹ gbe e sinu ọkọ bọọsi wọn, ni Tani Olohun yari mọ wọn lọwọ, wi pe oun ko le tẹle wọn lọ sibikankan.

Lara awọn ara adugbo la gbọ pe wọn da si ọrọ naa, ti wọn si lawọn ko nii jẹ ki wọn gbe ọkunrin naa kuro ni ayika ọhun.

Nibẹ ni awọn eeyan ti bẹrẹ sii ranṣẹ sawọn alẹnulọrọ laaarin ilu lati dide iranwọ fun ọkunrin naa, ki wọn ma ba a jiigbe lọ.

Sunday Igboho dá sí ọ̀rọ̀ náà

Awọn alẹyinju aanu la gbọ pe wọn tete ranṣẹ si olori ẹṣọ aabo ibilẹ nni, Iru Ekun, Sunday Adeyemo tọpọ mọ si Igboho lati wa ṣe iranwọ fun Tani Olohun, lori awọn to fẹẹ jii gbe.

Ninu fọnran ọhun, ni Igboho ti n ba ẹnikan sọrọ, to si n sọ pe oniruuru nnkan lo n ṣẹlẹ kaakiri, leyi to n ko ipenija ba ọrọ eto aabo nilẹ Yoruba.

Igboho ni igbesẹ naa ko bojumu to, nitori pẹ ọrọ ẹsin ni wọn jọ n fa, ati pe awọn ọlọpaa to wan aa ti da wahala nla silẹ, leyi to jẹ ki wọn ti gbogbo ọna to wọ inu adugbo ti Tani Olohun n gbe pa.

"Mo ti sọ fun ọga ọlọpaa ipinlẹ Kwara wi pe ko ma ṣe da si ọrọ ẹsin mọ. Wọn n ji awọn eeyan gbe ni Kwara, wọn n pa awọn eeyan lojoojumọ, wọn n ji ọba ati ijoye gbe, ẹ ko da si eyi, ẹ wa sọ pe ki wọn maa ji eeyan gbe n'Ibadan, ko le ṣee ṣe," Igboho sọ bẹẹ.

"Mo ti sọ fun ọga ọlọpaa Kwara ko ye e da si ọrọ ẹsin mọ."