Wọ́n ti sìnkú Iyeru, ọ̀gá NURTW Ogun tó jade láyé - ìjọba ìpínlẹ́ Ògùn kẹ́dùn

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ọrọ iku gbajugbaja ọga ẹgbẹ awakọ tẹlẹ nipinlẹ Ogun, Akeem Abodunrin ṣi n jẹ kayefi, ti ko sit ii sẹni to le sọ pato iru iku to pa a.

Alẹ ọjọ Abamẹta tii ṣe opin ọsẹ to kọja yii, ọjọ kejila, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ni iroyin naa jade sigboro wi pe Abodunrin, ẹni tọpọ awọn eeyan mọ si Iyeru ti ku.

Latigba ti iroyin ibanujẹ ọhun ti jade, ni ọpọ awọn to mọ ọkunrin naa ti bẹrẹ sii kẹdun, ti awọn miran si n barajẹ.

Ẹsẹ ko gbero nile oloogbe naa to wa ladugbo Quarry Road niluu Abeokuta laaarọ ọjọ keji, paapaa lasiko ti wọn n sinku rẹ.

Titi digba ti oloogbe naa fi jade laye, oun ni alaga ati alabojuto fun gbogbo garaaji to wa n ipinlẹ Ogun, eyi ti wọn pe ni Ogun State Park Management Services (OGSPAM).

Tani Akeem Abodunrin?

Odu ni Abodunrin tọpọ mọ si Iyeru, kii ṣaimọ foloko ni gbogbo ipinlẹ Ogun ati agbegbe rẹ, paapaa nilẹ Naijiria.

O ti le lọgbọn ọdun ti Iyeru ti wa nidi iṣẹ awakọ nipinlẹ Ogun.

Nigba ti wahala ẹgbẹ awakọ, ẹka ti NURTW nipinlẹ Ogun bẹrẹ, to di pe wọn bẹrẹ sii pa ara wọn kaakiri, Iyeru ni ijọba ipinlẹ Ogun kede lati ṣe adele alaga fun igbimọ iṣakoso ẹgbẹ naa.

Igbimọ ọhun ni ijọba ipinlẹ Ogun gbe dide lọjọ kẹrin, oṣu Keje, ọdun 2019 lati yanju aawọ to n ṣẹlẹ ninu ẹgbẹ NURTW.

Nigba ti wahala miran tun bẹrẹ ninu ẹgbẹ naa lọdun 2022.

Eyi lo mu ki ijọba ipinlẹ Ogun da ẹgbẹ ti yoo maa ṣakoso gbogbo garaaji kaakiri ipinlẹ, eyi ni wọn pe ni Ogun State Park Management.

Latigba naa ni ijọba ipinlẹ Ogun ti kede Iyeru gẹgẹ bi alaga ati alabojuto ẹgbẹ naa, to si jẹ pe ori ipo ọhun lo wa titi digba ti ọlọjọ fi de.

Ìjọba ìpínlẹ́ Ogun kẹ́dùn

Ijọba ipinlẹ Ogun labẹ iṣakoso Gomina Dapo Abiodun ti wa fi atẹjade ibanikẹdun ranṣẹ si awọn mọlẹbi oloogbe naa, ati gbogbo ẹgbẹ awakọ kaakiri ipinlẹ naa.

Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna feto irinna nipinlẹ ọhun, Onimọ-ẹrọ Olugbenga Dairo fi sita, o ni ibanujẹ ni iku ọkunrin naa jẹ fun wọn, nitori pe kii ṣe nnkan ti wọn lero tẹlẹ.

Dairo sọ pe ojiji ni iroyin iku naa ba awọn, to si lawọn ko le muu mọra, nitori awọn ipa ribiribi ti oloogbe naa ko nigba aye rẹ, iyẹn lẹka igbokegbodo ọkọ ati awọn garaaji.

"Alaaji Bodunrin jẹ agba alẹnulọrọ ti ipa rere rẹ ninu idagbasoke, ati iṣakoso alalaafia lẹka ẹgbẹ awakọ jẹ eyi to ni ipa rere," atẹjade naa sọ bẹẹ.

"Gẹgẹ bi alaga OGSPAN, Iyeru fi ara rẹ jin fun titẹle ilana alaafia, ikora-ẹni-nijanu ati eto to muna doko lawọn garaaji kakairi.

"Ilana adari rẹ gbe e si aarin gbungbun lati mu ki irẹpọ ati iṣọkan jọba lagboole awakọ," Dairo fi kun ọrọ rẹ.

Bakan naa lo fi kun ọrọ rẹ pe, "aaye to ni ipa ni ọkunrin naa fi silẹ lojiji, ti awọn mọlẹni, alabaṣiṣẹpọ ati awọn isọngbe rẹ yoo si mọ ọ lara kaakiri agboole awakọ.

"Ni orukọ Gomina Dapo Abiodun to jẹ gomina ipinlẹ Ogun ati gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun, mo n fi atẹjade ibanikẹdun yii ranṣẹ si mọlẹni Alaaji Akeem Abodunrin, igbimọ iṣakoso OGSPAN wi pe Ọlọrun yoo tu wọn ninu."