Aráàlú fárígá, ṣèwọ́de ní Ibadan tako ìjọba lórí bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ tí wọ́n jí gbé ṣì ṣe wà ní àhámọ́

Aráàlú fárígá, ṣèwọ́de ní Ibadan tako ìjọba lórí bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ tí wọ́n jí gbé ṣì ṣe wà ní àhámọ́
Published

Awọn ẹgbẹ ajafẹtọ jade lọjọ Aje ni ilu Ibadan tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ọyọ lati fi ẹhonu han lori ijinigbe awọn akẹkọọ ati olukọ kan ni agbegbe Ogbomoṣọ ni nnkan bii ọsẹ meji sẹyin.

Ninu iwọde naa to waye lowurọ ọjọ Aje, awọn ajafẹtọ naa ṣe iwọde lọ awọn ileeṣẹ ijọba titi kan ile gomina ati ofiisi gomina ni agbegbe Agodi ni ilu Ibadan.

Lara awọn patako alakọle ti wọn n gbe kiri lasiko iwọde naa la ti ri awọ̀n ti wọn kọ awọn akọle bii " Gbogbo ẹmi lo ni pataki, ẹ da awọ̀n ajinigbe lẹkun", " "Ẹ dide sọrọ soke".

Ki lo ti ṣẹlẹ ṣiwaju?