You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ta ni yóò di Olóòtú ìjọba tuntun ní UK, báwo ni wọn yóò ṣe yàn-án?
Bi Olootu ijọba tẹlẹ nilẹ UK, Keir Starmer se kọwe fipo silẹ, ibeere to wa lọkan ọpọ eeyan bayii ni pe ta ni yoo gba ipo rẹ, igba wo si ni wọn yoo dibo yan onitọun.
Ohun to n waye gan ree ni Westminster lẹyin ti Starmer kede pe oun n kuro nipo Olootu ijọba ninu ọrọ to sọ nile ijọba to wa ni Downing Street lọjọ Aje ana.
Andy Burnham, ẹni tii se Mayor tẹlẹ nilu Greater Manchester lo tete kede pe oun fẹ dije sipo olootu ijọba naa.
O si lẹtọ lati dije bayii bi wọn se bura wọle fun gẹgẹ bii ọmọ ile asofin tuntun lati ilu Makerfield.
Wọn bura wọle fun Andy Burnham gẹgẹ bii ọmọ ile asofin
Ni isẹju diẹ lẹyin ti Burnham wọle sile asofin naa ni Wes Streeting,tawọn eeyan maa n ri gẹgẹ bii alatako rẹ, kede atilẹyin rẹ fun Burnham.
"Mo lero pe gbogbo wa la ti Andy lẹyin," Streeting lo sọ bẹẹ amọ nibayii, ikunsinu ti n waye pe ipenija le wa.
Minisita tẹlẹ fun eto aabo, Al Carns, ti ni oun si n ro lọwọ boya oun yoo dije fun ipo olootu ijọba ilẹ UK.
Bakan naa, Akọwe agba feto ẹnawo ninu ijọba Strmer, Darren Jones, naa ni wọn ko fọwọ rọ sẹyin ninu awọn eeyan to nifẹ lati dije sipo Olootu ijọba naa.
To ba jẹ pe ko si ẹni to koju Burnham lati ba dije sipo Olootu ijọba ninu ifigagbaga naa, o seese ko di Olootu ijọba ilẹ UK lọjọ Kẹtadinlogun osu Keje.
Idi ni pe ọjọ yii ni ọjọ to kẹyin fun ẹnikẹni to ba fẹ di minisita lati fifẹ rẹ han.
Bi a se n mu iroyin wa fun yin nipa awọn isẹlẹ to n waye lẹyin ti Olootu ijọba tẹlẹ ni UK kọwe fipo silẹ ati nipa awọn eeyan to nifẹ lati gba ipo naa.
Bakan naa, la maa mu iroyin wa fun yin nipa ohun to n waye nile asofin ati awọn nnkan miran.
Olóòtú ìjọba UK, Keir Starmer kọ̀wé fipò sílẹ̀
Olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi, UK, Keir Starmer ti kọwe fipo rẹ silẹ gẹgẹ bi olootu ijọba ilẹ naa ati olori ẹgbẹ oṣelu Labour Party.
Ko i tii pe ọdun meji ti Starmer gba ipo olootu ijọba ilẹ Gẹẹsi bi o ṣe gba ipo naa lọjọ Karun-un, oṣu Keje, ọdun 2024 lẹyin ti ẹgbe oṣelu rẹ, labour Party ṣe jawe olubori nibi eto idibo gbogbogbo orilẹ ede naa.
Nigba to n kede fifi ipo silẹ lọjọ Aje, Starmer ni oun ti fi ipinnu oun to Ọba Charles leti ni owurọ yii.
"Awọn alaṣẹ ẹgbẹ oselu Labour Party maa gbe atẹ eto bi wọn ṣe maa yan adari tuntun sita ni ọjọ Kesan-an, oṣu Keje"
Ẹwẹ, Starmer ṣi maa dipo rẹ mu titi di igba ti egbẹ oṣelu Labour Party maa pari gbogbo eto lati yan olori mii ki ile aṣofin orilẹ ede naa to wọle pada lati isinmi wọn ninu oṣu Kẹsan-an.
O ni awọn alaṣẹ ẹgbẹ Labour Party maa gbe atẹ eto bi wọn ṣe maa yan adari mii tuntun ni ọjọ Kesan-an, oṣu Keje.
Eyi tumọ si pe wọn ti maa yan olootu ijọba mii ki ile aṣofin to wọle pada.
Starmer juwe akoko rẹ gẹgẹ bi olootu ijọba UK bii igba to wuyi julọ ninu igbesi aye rẹ.
O ni oun n gbe igbesẹ lati fipo oun silẹ nitori oun fi orilẹ ede ti oun nifẹẹ si siwaju ni ati pe oun fi da awọn ẹgbe oṣelu oun ti ko ni igboya ninu oun lati ko wọn sodi nibi eto idibo gbogbogbo orilẹ ede naa.
O fi kun pe oun maa ṣe gbogbo ohun to w ani ikapa oun lati ri daju pe o rọrun lati ijọba fun ẹni to ba maa gbapo lọwọ rẹ.
O ni ẹni to maa gbapo lọwọ oun n gba akoso ijọba Britain ti ayipada ti ba laaarin ọdun meji seyin.