Òní ni ìdájọ́ àwọn afurasí agbésùnmọ̀mí tó lé ní 400 yóò wáyé l'Abuja

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gbogbo oju lo lara ile ẹjọ giga ilu Abuja lonii lori igbẹjọ awọn afurasi agbesunmọmi to n lọ lọwọ ti idajọ wọn yoo waye lonii.

Igbẹjọ ọhun, ti ọpọ gbagbọ pe o jẹ igbẹjọ agbesunmọ to pọ julọ to n waye lẹẹkan ṣoṣo ni Naijiria ni afurasi ti wọn le ni 400 ti n kawọ pọn rojọ iwaju adajọ.

Lara awọn ẹsun ti ijọba apapọ fi kan awọn eeyan naa ni kikopa ninu igbesunmọmi, nina owo sinu owo igbesunmọ, ṣiṣe iranwọ fun awọn agbesunmọmi, ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Igbẹjọ naa to bẹrẹ lọsẹ yii ni oniruru adajọ n gbọ lẹyin ti wọn taare awọn igbẹjọ kan lati Kainji, nipinlẹ Niger, siluu Abuja.

Ṣaaju idajọ ti yoo waye lonii, adajọ agba Naijiria, Lateef Fagbemi (SAN), ti kọkọ sọ pe ẹri ti fi han pe awọn bii 150 ninu awọn afurasi naa lo jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Igbẹjọ yii jẹ ọkan gboogi lara ọna ti ijọba apapọ n gba lati rẹyin igbesunmọmi ni Naijiria.

Awọn onwoye ohun to n lọ sọ pe idajọ naa yoo ni ipa pataki ti yoo ko ninu itan Naijiria ninu igbesẹ rẹ lati gbogun ti igbesunmọmi.

Idajọ ọhun ko tii bẹrẹ lasiko ti n a ko iroyin yii jọ amọ a oo maa mu iroyin ọhun wa fun yin bo ba ṣe n lọ.

Àwọn afurasí tó lé ní 400 yóò fojú balé ẹjọ́ lónìí lórí ìgbéṣùmọ̀mí

Ko din ni awọn afurasi agbeṣumọmi irinwo ti wọn yoo farahan nile ẹjọ lọjọ Aje ni Naijiria ni ile ẹjọ giga ilu Abuja, olu ilu Naijiria.

O jẹ ọkan gboogi lara igbẹjọ ti yoo waye lori ipenija aabo to n ba orilẹ ede yii, ti wọn si n ri gẹgẹ bi ọna ti ijọba n gba lati koju laasigbo to n waye leralera lasiko yii.

Igbẹjọ yii lo n waye lẹyin ọsẹ diẹ ti irufẹ igbẹjọ bẹẹ waye ninu oṣu Kẹrin ọdun yii nibi ti ijọba ti wọ awọn afurasi to le ni ẹẹdẹgbẹta lọ sile ẹjọ lori igbeṣumọmi ti ile ẹjọ si dajọ fun awọn to le ni 386 ninu wọn.

Igbẹjọ ti yoo waye lonii ni ọpọ eeyan n ri gẹgẹ bi itẹsiwaju ijọba lati gbe igbesẹ to tọ lati kasẹ igbẹjọ naa nilẹ ati lati ṣedajọ ododo fawọn afurasi agbeṣumọmi naa.

Oniruuru ẹsun ni awọn afurasi agbeṣumọmi naa n koju to fi mọ ṣiṣe ikọlu sawọn araalu, ipese ounjẹ, ibugbe, ohun irinna fawọn Boko Haram ati ikọ agbeṣumọmi mii.

Igbagbọ wa pe ile ẹjọ yoo mu igbẹjọ naa y ani kiakia pẹlu agbekalẹ awọn akanṣe ile ẹjọ to maa mu igbejọ ya.

Orilẹ ede Naijiria n koju igbeṣumọmi latọwọ oriṣiriṣi awọn ikọ agbeṣumọmi bii Boko Haram, Iswap ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ọpọ eeyan lo ti padanu ẹmi wọn sọwọ awọn agbeṣumọmi yii nipasẹ oniruuru ikọlu awọn oniṣẹ laabi yii ni ọdun yii nikan.

Lati bii ọdun mẹrindinlogun sẹyin ni awọn agbeṣumọmi ti n ṣọṣẹ ni Naijiria, gbẹmi ọpọ eeyan, tawọn eeyan to le ni miliọnu meji si ti di ailanilelori mọ.

Amọ diẹ lawọn to maa n koju igbẹjọ lori igbeṣumọmi, ti ọpọ awọn agbeṣumọmi si maa n lo ọpọ ọdun ni ahamọ lai koju igbejọ kankan.

Yatọ si igbeṣumọmi, oniruuru ikọlu lo tun n waye laaarin awọn agbẹ atawọn darandaran ti igbagbọ wa pe wọn jẹ iran Fulani.

Ikọlu yii saba maa n yọri si ipaniyan paapaa ni ẹkun aarin gbungbun ati iwọ oorun ariwa Naijiria.

Ipenija aabo mii to tun n waye ni Naijiria ni awọn agbebọn ti wọn maa n gbe eeyan lati gba owo. Awọn wọnyii lo saba n ṣekọlu si ile ẹkọ lati ji awọn akẹkọọ gbe lati fi gba owo lawọn ilu to wa ni ẹsẹ kuku.