You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Èyí ni àpéjọpọ̀ ẹ̀sìn márùn-ún táwọn èèyàn ti máa ń pọ̀jù lágbàáyé
Ni gbogbo agbaye, lagbo ẹsin ati aṣa, kaluku lo ni apejọpọ ti wọn ti maa n kora jọ bo ti wu ko kere to.
Amọ awọn apejọpọ kan wa to jẹ kari aye ni wọn, ti wọn si gbajumọ kaakiri agbaye.
Awọn mi-in ninu wọn wa fun ipejọ ẹsin, awọn mi-in wa fun ijọ, bẹẹ ni awọn miran wa fun apejọ lati ṣe wẹjẹwẹmu.
Lọpọ igba, ọdọodun ni awọn apejọpọ yii maa n waye.
Lọwọlọwọ yii, apejọpọ marun-un lo jẹ koko ti wọn si gbajumọ ju lagbaaye, eyi to jẹ ti ẹsin.
Wọn wa laaarin ẹsin Islam, Hindu ati tawọn Jew.
Awọn marun-un naa ree
1 - Maha Kumbh Mela - India
Eyi ni akojọpọ to pọju lagbaaye, ti wọn maa n ṣe laarin awọn Hindu lorilẹede India.
O kere tan, eeyan to le ni miliọnu lọna ọgọfa (120 million) lo maa n wa sibi apejọpọ yii, amọ o tun ti n lẹkun si I gẹgẹ bii ẹka onka Uttar Pradesh Census Bureau ṣe sọ.
Fun apẹẹrẹ, ni 2013, apejọpọ naa gba alejo eeyan to to ọgọfa miliọnu eeyan, nigba ti eeyan aadọrinlelẹgbẹta(670m) darapọ ni 2025, eyi to mu un di ọkan lara awọn akojọpọ to pọju lagbaaye.
Ẹẹkan ninu ọdun mejila ni akojọpọ yii maa n waye, kalẹnda awọn Hindu ni wọn si maa n fi gbe e kalẹ.
Wọn maa n gbe e kiri ibudo mẹrin ẹsin bii:
Prayagraj
Haridwar
Nashik
Ujjain
Eyi to tobi ju ninu wọn ni Prayagraj, awọn eeyan naa maa n kora jọ ni odo atthe Ganges, Yamuna ati Saraswati fun iwẹ odo mimọ.
Awọn Hindu gbagbọ pe iwe naa maa n wẹ wọn mọ ninu ẹṣẹ wọn.
2 -Apejọ Forty - Karbala, Iraq
Eyi ni akojọpọ keji ti ero rẹ maa n pọ ju lagbaaye, nibi ti awọn ijọ Shia ti maa n kora jọ niluu Karbala, Iraq.laarin ogoji ọjọ ti won ya sọtọ lati fi ṣọfọ Akọni Sayyidina Hussaini, ọmọ ọmọ Anabi Muhammad (Ki ikẹ ati ọla Oluwa maa ba a).
Imam Hussain ibn Ali yii jẹ akọni ti wọn pa lọjọ kẹwaa oṣu Muharram, ni ọdun 61 AH.
Wọn pa a ni ilu Karbala ti wọn n pe ni Iraq lonii. Ọjọ naa ni wọn n pe ni Ashura.
Akọsilẹ lati Karbala fi han pe eeyan miliọnu si ọgbọn lo maa n wa sibi apejọ naa lasiko iṣọfọ ọhun, ni gbogbo ogunjọ oṣu Safar ti i ṣe oṣu keji oju ọrun tawọn ẹlẹsin Islam n lo.
Bo tilẹ jẹ pe ọdọọdun ni onka yii maa n yi, akọsilẹ fi han pe eeyan miliọnu mọkanlelogun (21 million) lo wa nibẹ ni 2022, eeyan ọgbọn miliọnu ni 2017, gẹgẹ bi awọn alaṣẹ Agọ Al-Abbas Mimọ ati ti Imam Hussaini ṣe sọ.
3 - Bishwa Ijtema - Bangladesh
Apejọpọ Bishwa Ijtema maa n waye lọdọọdun ni Bangladesh, nibi ti o kere tan, miliọnu marun-un awọn Musulumi ti maa n korajọ ni Tongi, lẹba ilu Dhaka.
Awọn alakooso akojọpọ naa gbe e kalẹ fun kikọni lẹkọọ iwa ọmọluabi, ijọsin ati iṣọkan awọn Musulumi, ki I ṣe fun oṣelu rara.
Lara ohun ti won maa n ṣe nibẹ ni
Kikọ ẹkọ nipa ẹsin Islam.
Jijokoo adua fun awujọ ẹsin Islam.
Ẹkọ nipa kikede ẹsin Islam lai fa wahala.
O ju orilẹede Musulumi aadọjọ (150 countries) lọ ti wọn maa n kora jọ pade nibẹ fun iṣọkan agbegbe wọn.
Adua ipari ipade naa, (Akheri Munajat), to jẹ igun pataki ninu rẹ maa n fa ero pupọ wa.
4) Hajj - Mecca
Irinajo Hajj maa n waye loṣu kejila oju ọrun ti awọn Musulumi n lo, eyi ti i ṣe Zul-Hijjah.
Awọn koko apẹjọ Hajj maa n waye lati ọjọ kẹjọ se ikejila oṣu Dhul-Hijjah lọdọọdun.
Hajj jẹ ọkan lara opo ẹsin Islam, o si jẹ dandan fun gbogbo Musulumi to ba lowo ati ilera pipe lati lọ, o kere tan, lẹẹkan ninu iṣẹmi aye wọn.
Apejọpọ Hajj maa n ni to eeyan miliọnu meji si mẹta, pẹlu bawọn eeyan ṣe n wa sibẹ kaakiri agbaye.
Ni 2010, eeyan 2.8m ni akọsilẹ sọ pe wọn ṣe Hajj ni Saudi, ni 2012, awọn to kopa to jẹ 3,161,573, gẹgẹ bi onka Arabian Statistical Agency, ṣe sọ
5) Odi Western - Jerusalem
Ibi ti a mọ si Western Wall tabi Odi Western niluu Jerusalem, jẹ ọkan lara awọn ibi mimọ fun awọn Jew, o si kere tan, eeyan miliọnu marun-un maa n ṣabẹwo sibẹ lọdọọdun.
Eyi tumọ si pe eeyan miliọnu marun-un maa n ṣabẹwo sibẹ yipo oṣu mejila to wa ninu ọdun lasiko ọtọọtọ.
Ninu ilu Jerusalem, ilu ọdun iyebiye lo wa, igbagbọ ọpọ eeyan si ni pe aaye naa jẹ abala to ṣẹku lara Tempili keji, eyi ti awọn ijọ Rome wo lọdun 70 AD.
Fun idi eyi, awọn Jews lati oriṣiriṣi ilu maa n wa sibẹ lati jọsin.