Agbèsùnmọ̀mí pa ṣọ́já, dàná sun àgọ́ ọlọ́pàá, iléèwòsàn àti yàrá ìkàwé

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ikọ agbesunmọmi ti wọn fura si pe Boko Haram ni wọn, tun gbe iṣẹ wọn de lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii nigba ti wọn dana sun agọ ọlọpaa, ileewosan alabọọde ati yara ikawe meji nile ẹkọ kan nijọba ibilẹ Ngala, ipinlẹ Borno.

Adele Alukoro fun ẹka ologun apapọ lapa Ariwa-Ila-Oorun Naijiria, Ọgagun Muhammed Goni, fidi ikọlu naa mulẹ ninu atẹjade to fi sita l'Ọjọbọ, ọjọ kẹsan-an oṣu Keje ọdun 2026 yii.

Yatọ si ikọlu sawọn ibudo yii, ṣọja kan pada ba iṣẹlẹ yii lọ.

Ọgagun Goni ṣalaye pe awọn agbesunmọmi naa gbiyanju lati gba ori iganna wọle si ibudo awọn ologun to wa nibẹ.

Nibi ti wọn ti koju ara wọn ni wọn ti pa sọja kan, bo tilẹ jẹ awọn ologun naa gbiyanju koju awọn agbesunmọmi ọhun, ti wọn fara gbọta lọ bo ṣe sọ.

Bawo ni ikọlu naa ṣe waye ?

Gẹgẹ bi awọn araalu Ngala kan ṣe ṣalaye fun ẹka iroyin Punch, wọn ni bi ikọ agbesunmọmi naa ṣe de ni wọn ṣina ibọn bolẹ, ti wọn si tu awọn olugbe agbegbe naa ka.

"Gbogbo wa la sa kuro niluu, awọn agbesunmọmi to ni nnkan ija igbalode ni wọn, lẹyin ti wọn koju awọn ologun ni wọn wọ ile ẹkọ kan, ti wọn dana sun yara ikawe meji.

"Wọn tun kọlu agọ ọlọpaa ati ileewosan kan, wọn dana sun ibẹ." Bẹẹ ni awọn eeyan to kọ lati daruko wọn naa wi.

Bakan naa ọlọde ibilẹ kan ṣalaye pe ikọ ọlọpaa, ologun atawọn ọmọ ẹgbẹ ologun apapọ, le awọn agbesunmọmi naa nigba ti wọn n sa lọ.

O ni ṣugbọn ọna wọn ti jin pupọ lasiko ti wọn n tọpasẹ wọn lọ naa.

Alaye ologun

Ninu atẹjade ti Ọgagun Muhammed Goni fi sita lo ti ṣalaye siwaju, pe awọn agbesunmọmi naa ba ọkọ ayinbọn meji atawọn nnkan ija ologun je.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ikọ ologun Hadin Kai koju awọn eeyan naa, nibudo wọn ni Logomani.

Ọgagun Goni sọ pe:

"Bo tilẹ jẹ pe awọn agbebọn naa sare wọ apa kan ori iganna ọgba ologun lasiko ti ija n lọ lọwọ, ikọ ologun tete tunra mu, wọn dena ikọlu naa, wọn ṣe awọn agbebọn naa lesẹ, eyi to mu kawọn kan sa lọ pẹlu ọta ibọn lara wọn.

"O wa ṣeni laanu pe ologun kan sun loju ija yii, bẹẹ ni wọn ba ọkọ ayinbọn atawọn nnkan ikoju ija mi-in jẹ."

Ni bayii ṣaa, Ọgagun Goni sọ pe alaafia ti pada si ibudo ologun Logomani, wọn si ti ṣafikun awọn ikọ to n ri si aabo nibẹ.

Bẹẹ lo ni eto n lọ lati so okun aabo le si i.