You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ghana must go: Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa báàgì yìí àti bó ṣe gbajúmọ̀ ní Naijiria
Lẹnu lọọlọ yii lawọn ọmọ orilẹede South Africa bẹrẹ si n lọgun pe ki awọn atọhunrinwa kuro lorilẹede wọn.
Ẹsun ti wọn kan awọn eeyan naa ni pe awọn lo n ṣiṣẹ ibi bii oogun oloro tita, idigunjale, ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ẹsun to lagbara julọ ti wọn fi kan awọn atọhunrina naa ni pe awọn ni ko jẹ ki awọn ọmọ onilẹ funra wọn riṣẹ ṣe nitori wọn ti gba gbogbo iṣẹ to yẹ ki awọn ṣe tan.
Wayi o, ẹmi awọn eeeyan kan ti sọnu sinu igbesẹ naa, bẹẹ lọpọ awọn eeyan ti fi South Africa silẹ amọ ọpọ awọn mii lo ṣi wa nibẹ.
Bo tilẹ jẹ pe awọn atọhunrinwa ti ko ni iwe igbelu ni wọn ni awọn n fẹ ko fi ilẹ awọn silẹ, ẹri wa pe wọn tun gbogun ti awọn mii ti wọn ni iwe igbelu pẹlu.
Lara awọn atọhunrinwa ti ọrọ yii kan julọ ni awọn ọmọ Naijiria, Ghana, Mali ati Zimbabwe.
Amọ ṣa, ṣaaju iṣẹlẹ yii lọpọ ọdun sẹyin ni Ghana ti kọkọ le awọn ọmọ Naijiria kuro nilẹ rẹ, lẹyin naa ni ijọba Naijiria naa tun paṣẹ ki awọn ọmọ Ghana fi Naijiria silẹ.
Fun ọpọ awọn ọmọ Ghana to n fi Naijiria silẹ lọdun naa lọhun, baagi kan ti wọn n lo ni a n pe ni baagi "Ghana Must Go" lonii.
Wo fidio oke yii lati mọ nipa itan Ghana Must Go ni Naijiria.