Àṣìta ìbọn agbésùnmọ̀mí pa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ lásìkò táwọn ológun ń dènà ìjínigbé

Eeyan mẹta na ibọn soke ninu okunkun

Oríṣun àwòrán, Others

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Awọn akẹkọọ kan lati ile ẹkọ girama Federal Government Girls College, Monguno, nipinlẹ Borno, ti padanu ẹmi wọn pẹlu ibọn awọn agbesunmọmi to ba wọn lasiko ti ikọ ologun Naijiria koju awọn agbebọn naa.

Aṣita ibọn pa awọn akẹkọọ naa nigba ti awọn agbesunmọmi kọlu ile ẹkọ wọn lọjọ Aiku, ọjọ kọkandinlogun oṣu Keje ọdun 2026 yii.

Bawo leyi ṣe ṣẹlẹ?

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ ologun ilẹ Naijiria fi sita lọjọ Aiku naa ni Ọgagun Muhammed Goni to jẹ Adele agbẹnusọ ikọ HADIN KAI ni Maiduguri ti ṣalaye, pe nnkan bii aago kan aabọ oru ọjọ Aiku naa ni awọn agbesunmọmi yabo Federal Government Girls College, Monguno.

O ni ikọ agbesunmọmi Islamic State West Africa Province (ISWAP) lo ṣe ikọlu naa nigba ti wọn gbiyanju lati ji ọpọ awọn akẹkọọ gbe lọ nile ẹkọ ọhun.

Atẹjade naa tẹsiwaju pe awọn agbesunmọmi raye wọle sile ẹkọ yii pẹlu iranlọwọ awọn kan ti wọn n ṣe agbodegba fun wọn lati ko awọn ọmọ ọlọmọ wọgbo lọ.

Amọ ikọ ologun tete koju wọn lati dena rẹ bi atẹjade ologun ṣe ṣalaye.

Wọn ni ologun fi ajulọ han awọn agbesunmọmi naa, eyi to mu ki awọn eeyan naa sa lọ lai ri ọmọ kankan gbe lọ.

Ijọba ipinlẹ Borno lo n lo ile ẹkọ FGGC yii bii ibugbe igba diẹ fun awọn akẹkọọ ile ẹkọ Gbogboniṣe Federal Polytechnic, Monguno ki ikọlu naa too waye.

Awọn akẹkọọ kan ba ikọlu naa lọ ọ̀run

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

Gẹgẹ bawọn ologun ṣe ṣalaye, ikọlu naa mu ẹmi awọn akẹkọọ kan lọ, bo tilẹ jẹ pe wọn ko sọ iye wọn.

"Lẹyin ikojuara-ẹni naa, ikọ ologun ṣe aṣeyọri nipa kiko akẹkọọ mẹrindinlaadọta (46) lọ si Bareke ologun Kinnasara to wa ni Monguno, nibi ti wọn ti yẹ ilera wọn wo, ti wọn si fun wọn ni itọju to yẹ.

"Gbogbo awọn akẹkọọ ti a doola ni a fidi ẹ mulẹ pe wọn wa ni ilera pipe, wọn ko si ji akẹkọọ kankan gbe lọ.

"Amọ o ṣeni laanu pe awọn akẹkọọ kan padanu ẹmi wọn lẹyin ti aṣita ibọn lati ọdọ awọn agbesunmọmi naa ba wọn lasiko ti iro ibọn n bole lakọlakọ laaarin ikọ ologun ati agbesunmọmi."

Bẹẹ ni atẹjade ologun naa wi.

BBC News Yoruba yoo maa mu afikun iroyin yii wa fun yin bo ba ṣe n lọ.

Iléeṣẹ́ ológun dènà ìkọlù àwọn agbéṣùmọ̀mí, pa ọ̀pọ̀lọpọ̀, fojú àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè mẹ́ta tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ISWAP hàn

Awọn ologun ti wọn wa ninu ọkọ ijagun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ileeṣẹ Ologun Naijiria ti kede didena ikọlu awọn agbeṣumọmi alakatakiti ẹsin Islam, iyẹn Islamic State West African Province, Iswap ni agbegbe Cross Kauwa ni ipinlẹ Borno eyi to ṣokunfa iku ọpọ awọn agbeṣumọmi naa, ti awọn yooku si salọ.

Atẹjade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ Ologun, Ọgagun Mohammed Goni fi lede lọjọ Aiku sọ pe ni alẹ ọjọ Abamẹta ni ikọlu naa waye nigba ti awọn agbeṣumọmi naa gbiyanju lati ṣekọlu si ibudo awọn ologun kan.

Ileeṣẹ Ologun fi kun pe awọn agbeṣumọmi naa fẹ gbiyanju lati ja ibi ti ijọba n ko awọn ohun elo itọju aisan onigba meji si lati ji wọn ko ki ọwọ awọn ọmọ ogun to tẹ wọn.

Ipinle Borno atawọn ipinlẹ mii ni ariwa Naijiria lo maa n koju ajakalẹ aisun onigba meji lasiko ojo, bi awọn laasigbo ati ikọlu to maa n waye ni awọn ipinlẹ naa ṣe ti ṣakoba fun fun nini omi to ṣe e bumu buwẹ.

Ọgagun Goni ni bi ileeṣẹ Ologun ṣe ti mọ nipa ikọlu ti wọn fẹ ṣe naa ni awọn ọmọ ogun koju wọn, ti apa awọn ologun si ka wọn eyi to mu kawọn agbeṣumọmi naa sa asala fun ẹmi wọn.

O sọ pe lasiko ikọlu awọn ọmọ ogun sawọn agbeṣumomi naa, ileeṣẹ Ologun ṣawari ẹrọ ayaworan kan lọwọ wọn, eyi to ṣe afihan awọn nnkan ti awọn agbeṣumọmi naa ti ka silẹ nipa ikọlu wọn.

O ni awọn ṣawari awọn fidio nipa awọn ikọlu ti wọn ti ṣe atawọn ohun elo ti wọn n lo fi ṣiṣẹ.

Gẹgẹ bi ileeṣẹ Ologun ṣe sọ, ayẹwo awọn fidio to wa ninu ẹrọ ayaworan naa fi han pe awọn olori ikọ agbeṣumọmi mẹrin lo wa nidii ikọlu ti wọn gbiyanju lati ṣe naa to fi mọ awọn ajoji lati ilẹ okeere mẹta.

Ta ni àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè mẹ́ta tí iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà sọ pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ISWAP?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọkan lara awọn ajoji naa ni Abu Ishaq lati orilẹ ede Pakistan, ẹni ti ileeṣẹ Ologun gba pe oun lo maa n ṣe idanilẹkọọ fun gbogbo awọn Iswap naa patapata.

Bakan naa ni wọn tun darukọ Abu Thaiba ẹni to jẹ ọmọ ilẹ Morocco, ti wọn si pe ni dokita iṣegun oyinbo ti oun naa n ṣiṣẹ fun Iswap.

Wọn ni awọn ṣi n ṣiṣẹ lati fidi ẹni ti ajoji kẹta naa jẹ mulẹ.

Ileeṣẹ Ologun ni eyi fidi rẹ mulẹ pe awọn ikọ agbeṣumọmi Iswap n ri iranlọwọ ati atilẹyin lati ilẹ okeere, ti wọn si n jẹ anfaani ti ajọṣepọ naa mu bawọn.

Wọn fi kun pe iwadii awọn fi han pe awọn agbeṣumọmi naa ṣekọlu pada sawọn ọmọ ogun ti wọn si ṣe ọmọ ogun Naijiria meji le ṣe, ti wọn si tun ko lara oku awọn eeyan wọn tawọn ọmọ ogun pa.

Ikọ agbeṣumọmi Boko Haram ati Iswap to ya kuro lara wọn ti ṣe ọpọlọpọ ikọlu sawọn ilu atawọn ibudo ọmọ ogun ni ẹkun ila oorun ariwa Naijiria.

Naijiria ti mu alekun ba bi o ṣe n gbogunti awọn agbeṣumọmi pẹlu atilẹyin ati ajọṣepọ ilẹ okeere to fi mọ orilẹ ede Amerika nipase idanilẹkọọ ati ibaṣepọ to loorin.

Abu Ishaq

Ọkan lara awọn atọhunrinwa naa ni wọn fi ọda pupa ya sọtọ ninu aworan yii, oun ni ileeṣẹ ologun pe ni Abu Ishaq

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/X

Ẹni akọkọ tawọn ṣọja Naijiria ṣafihan rẹ ninu fọto awọn ISWAP naa ni wọn pe ni Abu Ishaq.

Atẹjade ti Ọgagun Mohammed Goni fi sita, ṣalaye pe ọmọ orilẹede Palestine ni, o si n ṣiṣẹ pẹlu ikọ apani ISWAP.

Iṣẹ rẹ ninu ikọ naa gẹgẹ bawọn ologun Naijiria ṣe wi, ni lati maa kọ awọn ISWAP nija, ko maa fun wọn ni ẹkọ ogun.

Abu Thaiba

Enikeji ti wọn pe ni Abu Thaiba ni wọn fi ọda pupa ya sọtọ ninu fọto awon ISWAP ti wọn jọ ya

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/X

Ẹnikeji ti wọn darukọ rẹ to ti okeere wa ni wọn pe ni Abu Thaiba. Wọn ri oun naa ninu fọto tawọn ISWAP jọ ya pẹlu rẹ.

Ọmọ orilẹede Morocco, ni Ariwa Africa ni wọn pe Abu Thaiba.

Iṣẹ rẹ ninu ikọ naa bi awọn ologun ṣe sọ ni lati maa fun awọn ikọ naa ni itọju, nitori dokita oniṣegun oyinbo ni.

Bi wọn ba faragbọta logun, oun lo maa n ba wọn wẹ oju ọgbẹ ti yoo si tọju wọn.

Iṣẹ n lọ lori ẹnikẹta

Ẹnikẹta ni wọn fi ọda pupa ṣe adayanri rẹ ninu aworan awọn ISWAP yii.

Oríṣun àwòrán, Nigerian Army/X

Ẹkunrẹrẹ alaye nipa ẹnikẹta ko ti i foju han gẹgẹ bi awọn ṣọja Naijiria ṣe wi, amọ oun naa wa ninu fọto awọn ISWAP ọhun.

"A ṣi n ṣiṣẹ lorii ba a ṣe maa mọ orukọ rẹ, ọmọ ilu to jẹ ati iṣẹ to n ṣe fun ikọ naa."

Bẹẹ ni apa kan atẹjade awọn ṣọja Naijiria naa wi.

Ṣaaju ki wọn too ri awọn ọmọ ilẹ okeere yii ni òye ti n foju han, pe awọn atọhunrinwa kan wa ninu ikọ ISWAP ati Boko Haram ti wọn jọ n ṣe.