You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Ṣé òótọ́ ni ìjọba àpapọ̀ ya owó sọ́tọ̀ fún àjọ PFIPC tí Adeniyi Adeyemi darí rẹ̀ tí wọ́n tún ní àwọn kò mọ̀ nípa rẹ̀?
Rugudu ti ja ni ọọfisi Aarẹ Naijiria lẹyin ti olori oṣiṣẹ Aarẹ Femi Gbajabiamila ati agbẹnusọ Aarẹ, Bayo Onanuga sọ pe Aarẹ Bola Tinubu ko mọ Ọmọọba Adeniyi Adeyemi ri gẹgẹ bii oṣiṣẹ ijọba apapọ.
Adeniyi Adeyemi, gẹgẹ bii ohun to sọ ṣaaju, ni ọga agba ajọ Presidential Foreign Intervention Promotion Council/Presidential Economic Advisory Council, ti ijọba apapọ ti sọ pe oun ko mọ bayii.
Amọ ṣa, atẹjade lati ọọfisi olori oṣiṣẹ Aarẹ, Femi Gbajabiamila sọ pe ijọba Naijiiria ko ni ileeẹẹ kankan to n jẹ bẹẹ, ati pe Aarẹ Tinubu ko fun ọkunrin naa ni iwe igbanisiṣẹ kankan.
Ninu atẹjade Onanuga lọjọbọ, o fidi rẹ mulẹ pe ijọba ko ni ọọfisi tabi ileeṣẹ ti Adeyemi ni oun jẹ adari rẹ.
Amọ ṣa, iwadii ileeṣẹ iroyin BBC fi han pe alakalẹ wa fun ọọfisi ọhun ninu iwe eto iṣuna ọdun 2026 bo tilẹ jẹ pe ijọba ni ko si ileeṣẹ kankan to n jẹ bẹẹ.
Ni oju ewe 50 ati 51 iwe eto iṣuna ọdun 2026 ti ileeṣẹ to n ri si ọrọ eto iṣuna naa, o han gedegbe nibẹ pe owo ti iye rẹ to 1,302,978,784 biliọnu ni ijọba la kalẹ fun ọọfisi naa.
Gẹgẹ bii alakalẹ owo ọhun, 802,978,783 miliọnu ni wọn la kalẹ fun nina ọọfisi naa, 200,00,001 miliọnu wa fun owo awọn iṣẹ kan ni ọọfii ọhun nigba ti 300 miliọnu wa fun awọn akanṣẹ iṣẹ nibẹ.
Ninu oṣu Kẹwaa, ọdun 2025 ni ajọ naa ti ijọba apapọ sọ pe oun ko mọ nipa rẹ ṣe ipade kan ṣaaju apero 'World Investment Summit (WIS)' to yẹ ko waye ni Naijiria ninu oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii.
Ninu ipade to waye loṣu Kẹwaa naa ni ileeṣẹ iroyin Guardian ti jabọ pe Adeyemi ni awọn n reti olori orilẹede bii 80 kaakiri agbaye nibi ipade apero ti yoo waye ni Naijiria ti wọn pe akori rẹ ni 'Unlocking Capital, Accelerating Development, Driving Prosperity'.
Wọn ni ireti wa pe ipade apero ọhun yoo mu ki awọn oniṣowo agbaye wa na owo to le ni tiriliọnu marun un naira fun owo ṣiṣẹ ni Naijiria.
Ọpọ awọn aṣoju ijọba orilẹede lagbaye lo wa nibi ipade ọhun to waye nile itura Wells Carlton niluu Abuja.
Adeyemi Mathew: Ọkùnrin tó gba ìwé ìgbanisíṣẹ́ lẹ́yìn tó ní òun san ₦400m, ṣí àkáǹtì sí CBN, tún ní ìpín ₦1.3b nínú ìṣúná Nàìjíríà, ṣùgbọ́n tí ìjọba àpápọ̀ pè ní gbájúẹ̀
Awuyewuye ṣi n lọ lori ọrọ Ọmọba Adeniyi Adeyemi ti ileeṣẹ ọlọpaa fẹsun onikoko mẹjọ to da lori igbimọpọ lati ṣe ayederu ẹka ijọba kan to pe orukọ rẹ ni PFIPC ni ile ẹjọ giga apapọ l'Abuja.
Ileeṣẹ ọlọpaa fẹsun kan Ọmọba Adeyemi pe o n dari ayedereu ẹka ijọba to pe orukọ rẹ ni Presidential Foreign Intervention Promotion Council (PFIPC).
Ileeṣẹ ọlọpaa fẹsun kan Ọgbẹni Adeyemi pe o ṣe ayederu lẹta igbanisiṣẹ lati ọwọ ijọba apapọ eyi to ni adari awọn oṣiṣẹ nileeṣẹ aarẹ, Họnarebu Femi Gbajabiamila buwọlu.
Bakan naa ni ileeṣẹ ọlọpaa sọ pe Adeyemi tun ṣi akaunti mẹrinlelọgbọn lorukọ oniruuru ayederu ẹka ijọba.
Adeyemi fẹsun kan Gbajabiamila pe o gba N400m lori iyansipo oun
Ṣaaju ni Ọgbẹni Adeyemi fẹsun kan olori awọn oṣiṣẹ nileeṣẹ aarẹ, Gbajabiamila, pe o gba N400m lọwọ oun lori iyansipo oun gẹgẹ bii ọga agba ajọ PFIPC.
Bakan naa ni o tun sọ pe Gbajabiamila tun beere N200m mii lati le daabo bo iyansipo oun.
Ọmọba Adeyemi tun fẹsun kan olori awọn oṣiṣẹ nileeṣẹ aarẹ wi pe o beere fun ida 48% owo N27.4bn ti ajọ PFIPC yoo fi bẹrẹ iṣẹ, amọ, Adeyemi ni oun kọ eti ikun si ọrọ naa.
A tun gbọ pe N1.3bn ni ijọba ya sọtọ ninu eto iṣuna ọdun 2026 eyi to wa fun owo ti ajọ naa yoo naa fun ọdun kan.
Ọrọ yii jade lẹyin ti Gbajabiamila sọ ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ kọkanla oṣu Kẹfa to kọja wi pe ko si ẹka ileeṣẹ ijọba ti orukọ rẹ n jẹ PFIPC ninu iṣejọba Aarẹ Bola Tinubu, ati pe aarẹ ko yan an sipo lati dari ẹka naa.
Amọ, Ọmọba Adeyemi, sọ pe Gbajabiamila sọ pe ko si ẹka ijọba to n jẹ bẹẹ tori oun kọ lati fun un lawọn nnkan ti o beere lọwọ oun.
Ọga agba ajọ PFIPC sọ pe bawo ni ajọ naa ṣe wa loju ewe 50 ati 51 abadofin ile aṣofin agba fun eto iṣuna 2026 orilẹede Naijiria to ba jẹ wi pe ko si ajọ to n jẹ PFIPC gẹgẹ bi Gbajabiamila ṣe sọ .
Adeyemi sọ pe niṣe lo yẹ ki Gbajabiamila kọwe fipo silẹ tori oun lo jẹ ki Aarẹ Tinubu buwọlu iyansipo oun gẹgẹ bii adari ajọ PFIPC.
Ọkunrin naa sọ pe bi ajọ PFIPC ba jẹ ayederu, bawo lo ṣe wọ inu eto iṣuna ọdun 2026 ti kii ba ṣe pe jibiti ni eto iṣuna ọhun.
Ọgbẹni Adeyemi tun sọ pe bawo ni ajọ PFIPC ṣe le jẹ ayederu lẹyin ti o ti wa fun bii ọdun kan ti ọfiisi ajọ naa si wa ni ileeṣẹ ijọba apapọ l'Abuja, ati pe ajọ naa tun ni oriṣiiriisi apo ikowosi eyi to wa ni akọsilẹ banki apapọ Naijiria, CBN.
O fẹsun kan Gbajabiamila wi pe o n gbiyanju lati jẹ ki araalu ri oun gẹgẹ bii onijibiti lasan an ni.
Ọgbẹni Adeyemi tun sọ pe awọn afurasi agbenipa gbiyanju lati ṣekupa oun lopopona Abuja si Kaduna lọjọ keje oṣu Kẹsan an ọdun 2025.
O ni lasiko ikọlu ti wọn ṣe soun yii ni wọn ji awọn foonu atawọn iwe kan lọ lọwọ oun.
Ọmọba Adeyemi wa rọ Aarẹ Tinubu wi pe ko gbe igbimọ oluwadii kan dide ti yoo ṣewadii ikọlu tawọn afurasi agbenipa ṣe soun ati iwadii iku Babatunde Tanimola ẹni to sọ pe o ṣe alarina laarin oun ati Gbajabiamila ẹni ti awọn ọlọpaa ni o ku ninu ijamba ina to ṣẹlẹ nile itura kan to wa ni agbegbe Utako l'Abuja lọjọ kejilelogun oṣu Kẹwaa ọdun 2025.
Ileeṣẹ Aarẹ ni irọ ni Adeyemi pa mọ Gbajabiamila lori idasilẹ ajọ PFIPC
Ẹwẹ, ileeṣẹ aarẹ ti sọ pe irọ to jinna si ootọ lọrọ ti Ọgbẹni Adeyemi sọ ijọba apapọ yan sipo ọga agba ajọ PFIPC.
Oludamọran aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, ṣalaye ninu atẹjade kan to fi sita wi pe ọfiisi olori awọn oṣiṣẹ nileeṣẹ aarẹ lo kọkọ ṣe akiyesi pe ajọ kan wa to n jẹ PFIPC lẹyin ti ajọ NIPC sọ fun ijọba wi pe awọn ti ṣakiyesi ajọ mii to n ṣiṣẹ tawọn n ṣe.
Onanuga ni lẹyin naa ni Gbajabiamila fi ọrọ naa to ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS ati ileeṣẹ ọlọpaa leti lọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹwaa wi pe ki wọn ṣe iwadii awọn onijibiti to n ṣakoso ayederu ẹka ijọba naa.
Gbajabiamila ṣalaye ninu iwe ipẹjọ to fi ranṣẹ si ajọ DSS ati ọlọpaa wi pe awọn eeyan kan lọ ṣe ayederu ibuwọlu lati ọdọ ijọba lati le maa dari ajọ PFIPC ti ijọba ko mọ nnkankann nipa rẹ.
Ileeṣẹ aarẹ ni ọrọ naa di nnkan ti ọfiisi oludamọran aarẹ lori eto aabo paṣẹ ki iwadii waye lori rẹ.
Onanuga sọ pe olori awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ aarẹ sọ nigba naa wi pe oun ko fun ẹnikẹni ni lẹta igbaniṣiṣẹ fun Ọgbẹni Adeyemi, ati pe ijọba apapọ ko mọ ẹka naa.
Oludamọran fikun ọrọ rẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa fọwọ ṣinkun ofin mu Ọgbẹni Adeyemi lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Kẹwaa ọdun 2025 nibi to n lo bii ọfiisi rẹ niluu Abuja.
Onanuga ni iwadii ileeṣẹ ọlọpaa fi han pe ayederu iwe igbaniṣiṣẹ lo wa lọwọ Adeyemi, ati pe ko si ẹka ijọba kankan ti orukọ rẹ n jẹ PFIPC.
Bakan naa ni ileeṣẹ aarẹ sọ pe iwa jibiti bi Adeyemi hu pẹlu bi o ṣe n fi ara rẹ han gẹgẹ bii adari ẹka ileeṣẹ ijọba.
Oludamọran aarẹ tun sọ pe ayederu ni akaunti mẹrinlelọgbọn to loun ṣi lorukọ oniruuru ileeṣẹ ijọba.
Onanuga tun ṣalaye ninu atẹjade to fi sita pe ileeṣẹ ọlọpaa ti fẹsun to da lori ṣiṣe ayederu iwe ati ipo kan Adeyemi ati eeyan meji mii ni ile ẹjọ giga apapọ l'Abuja.
Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu Keje yii ni igbejọ naa yoo bẹrẹ.
Onanuga fikun ọrọ rẹ pe Adeyemi ti figba kan ri pe ara rẹ ni nnkan ti ko jẹ ri, nigba to sọ lọdun 2016 wi pe oun ni aarẹ ẹgbẹ World Youth Organization eyi to sọ pe o n ṣiṣẹ pọ pẹlu ajọ iṣọkan agbaye, UNO.
Oludamọran aarẹ sọ pe nigba to ya ni ajọ UNO sọ pe awọn ko mọ ọn ri.