Kí ló dé tí Super Falcons ṣe lulẹ̀ ní WAFCON? Àjọ eléré bọ́ọ̀lù Nàíjíríà, NFF bẹ̀rẹ̀ ìwádìí, bó se júwe ọ̀nà ilé fún akọ́nimọ̀-ọ́n-gbá wọn

Oríṣun àwòrán, Super Falcons Show/Facebook
Ajọ to n ṣabojuto ere bọọlu alafẹsẹgba nilẹ Naijiria, NFF ti yọwọ Justine Madugu kuro lawo iṣakoso ẹgbẹ agbabọọlu awọn obinrin ilẹ Naijiria, Super Falcons.
NFF lo gbe igbesẹ yii lẹyin awọn agbabọọlu naa kọ lati yege fun idije ifẹ ẹyẹ agbaye, ati bi wọn tun ṣe tete jabọ ninu idije ifẹ ẹyẹ ilẹ Afrika to ṣẹṣẹ pari.
Awọn alakoso ajọ naa lo kede igbesẹ tuntun naa loju opo 'X' lọjọ Aje, ọsẹ yiii, ti wọn si jẹ ko di mimọ pe awọn ko le kawọ gbera lati jẹ ki ina Super Falcons maa jo ajorẹyin.
"Igbimọ iṣakoso ajọ Nigeria Football Federation ti sọ fun gbogbo awọn alakoso ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons lati fipo silẹ loju ẹsẹ," NFF sọ bẹẹ ninu atẹajde to gbe sita.
Bi ẹ ko ba gbagbe, lọjọ kẹtala, oṣu Kẹjọ, ọdun yii, ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons kọ lati peregede fun idije ife ẹyẹ agbaye ti awọn obinrin f'ọfun 2027.
Super Falcons padanu sọwọ akẹgbẹ wọn lati orileede South Africa, leyi to jẹ aṣekagba lati peregede.
Igba akọkọ ree ti ẹgbẹ agbaboọlu Super Falcons yoo padanu lati kopa ninu idije ife ẹyẹ agbaye ti awọn obinrin latigba ti wọn ti bẹrẹ lọdun 1991.
Ṣaaju akoko yii ni Super Falcons ti kọkọ padanu ninu anfaani mẹrin to le jẹ ki wọn peregede, nigba ti wọn padanu sọwọ akẹgbẹ wọn lati Cameroon ninu idijẹ ife ẹyẹ ilẹ Africa (WAFCON) ti ọdun 2026 to ṣẹṣẹ pari.
Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Madugu sáájú?
Magudu ti wa labẹ ayẹwo to lagbara gidi nipa yiyan awọn agbabọọlu rẹ, ati agbekalẹ awọn ọna amulo ni gbogbo asiko ipolongo WANFCON to pada ja si ofo.
Akọnimọ-ọn-gba ẹni ọdun mejilelọgọta naa lo padanu iṣẹ rẹ nigba to ku bi ọdun kan lati lewaju Super Falcons lọ sibi aṣeyọri igba kẹwaa lera wọn.
NFF yan ìgbìmọ ẹlẹ́ni mẹ́fà
Ni bayii, ajọ NFF ti wa kede pe awọn ti ṣagbekalẹ igbimọ ẹlẹni mẹfa ti yoo ṣe iwadii finnifinni lati mọ awọn nnkan to ṣokunfa bi Falcons ṣe n padanu lera-lera.
Fanny Amun to ti figba kan ri jẹ akọwe agba ajọ NFF ni wọn yan gẹgẹ bi alaga igbimọ ọhun.
Awọn miran to tun wa ninu igbimọ oluwadi naa ni Ladan Bosso, akọnimọ-ọn-gba tẹlẹ fun ẹgbẹ agbabọọlu Flyin Eagles; Desire Oparanozie, balogun ikọ Super Falcons tẹlẹ; Mutiu Adepoju, to jẹ agbabọọlu Super Eagles tẹlẹ; ati Alex Mana toun jẹ afunfeere tẹlẹ.
Nasiru Sa'idu, to jẹ alaga ajọ to n ri sọrọ ere idaraya nipinlẹ Sokoto ni yoo tukọ gẹgẹ bi akọwe.





























