Àwọn wo ni ẹbí Adeleke tó dí ètò òṣèlú mú ṣinṣin l'Osun lati ọdun 1979?

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Odu ni idile awọn Adeleke, kii ṣamọ f'oloko nipinlẹ Osun, paapaa lorileede Naijiria ati kaakiri agbaye.
Idile naa lo jẹ pe wọn bi wọn ṣe ta gbongbo kaakiri ilẹ Naijiria naa ni wọn tun tan kaakiri agbaye, ti aye si n kan saara si wọn.
Bi idile Adeleke ṣe gbajumọ nidi eto okoowo, oṣelu, agbo ariya, beẹ ni wọn ko gbẹyin lawọn ẹka bii eto amofin ati awọn miran.
Koda, baba Ayoola Adeleke ti bẹrẹ oselu lati ọdun1979 nigba to lọ sile asofin agba nilu Eko, lẹyin naa ni Isiaka Adeleke di gomina ipinlẹ Osun, ki Ademola Adeleke to wa di gomina fun igba meji bayii.
Ki ni agbara idile yii to se di ipo oselu ipinlẹ Osun mu digbi lati ọdun 1979?
BBC News Yoruba tọpinpin idile yii lati ori baba wọn, awọn ọmọ idile naa to ti dipo oselu mu nibẹ ati ohun to jẹ idi agbara wọn ti wọn ko fi yapa.

Oríṣun àwòrán, Davido
Ayoola Adeleke: Sẹnetọ to ṣoju ẹkun Oyo atijọ ti awọn ilu bii Ede, Osogbo, Irepodun, Ifelodun, Odo Otin ati Ila Orangun wa labẹ rẹ
Oloye Raji Ayoola Adeleke jẹ agba ajafẹtọ ọmọniyan ati ogbontarigi oloṣelu ko too papoda.
Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kejila, ọdun 1983 ni wọn bi i niluu Ede.
Iya rẹ, Adeboyin lo wa lati agboole Onilegogoro, to si tun jẹ Iyalode, iyẹn olori awọn ọlọja nilu Ede nigba naa.
Laarin ọdun 1935 si 1938 Ayoola Adeleke lọ sile ẹkọ alakọbẹrẹ St. Peter to wa niluu Ede, ipinlẹ Osun, ko too tẹsiwaju nile-ẹkọ girama tiluu Ibadan, to si jade lọdun 1943.
Ọdun 1943 lo gba iwe ẹri nipa akọṣẹmọṣe nọọsi, to jẹ ọkan gboogi lara awọn oludasilẹ ẹgbẹ awọn nọọsi nilẹ Naijiria.
Ayoola Adeleke jẹ igbakeji aarẹ ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ oniṣọkan, ULCN, to si tun di oniruuru ipo mu lawọn ẹgbẹ kaakiri. Akiyitan rẹ lo jẹ ki wọn yan an gẹgẹ bii Balogun ilu Ede lọdun 1976.
Ọdun 1979 ni Ayoola Adeleke gbegba oṣelu, to si wọle gẹgẹ bii sẹnetọ to ṣoju ẹkun Oyo atijọ ti awọn ilu bii Ede, Osogbo, Irepodun, Ifelodun, Odo Otin ati Ila Orangun wa labẹ rẹ.
Oloye Ayoola Adeleke fẹ iyawo nigba meji, iyawo rẹ keji, Nnena Esther Adeleke lo jẹ ọmọ ipinlẹ Abia, to si bimọ marun-un, lara eyi ti Isiaka Adeleke, Adedeji Adeleke ati Ademola Adeleke wa ninu wọn.

Oríṣun àwòrán, Isiaka Adeleke
Isiaka Adeleke: Gomina alagbada akọkọ fun ipinlẹ Osun
Ogbontarigi agba oṣelu naa ni Isiaka Adetunji Adeleke, ti ọpọ eeyan mọ si Serubawọn.
Ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kinni, ọdun 1955 ni wọn bi sile aye.
Ipinlẹ Enugu ni wọn bi Isiaka Adeleke si lọdun 1955, ibẹ si lo wa titi ti ogun abẹle Naijiria fi bẹrẹ, ko to di pe wọn gbe e wa siluu Ibadan lati bẹrẹ eto ẹkọ rẹ.
Ile-ẹkọ girama tiluu Ogbomoso lo ti pari iwe mẹfa, bẹẹ lo tun kẹkọọ gboye nipa ọrọ didari ilu.
Igba meji ọtọọtọ ni Isiaka adeleke di ipo sẹnetọ mu lẹkun Iwọ-Oorun ipinlẹ Osun.
Inu ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP) ni Isiaka Adeleke gba wọle sipo sẹnetọ fun igba akọkọ lọdun 2007.
O tun darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC to gba wọle fun saa keji lọdun 2015.
Lẹyin ti wọn pin ipinlẹ Osun niya kuro lara ipinlẹ Oyo ijọun, Isiaka Adeleke wọle sipo gomina lọdun 1992, oun si ni gomina alagbada akọkọ fun ipinlẹ Osun.
Ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹrin, ọdun 2017 ni Isiaka Adeleke jade laye lẹni ọdun mejilelọgọta niluu Osogbo, lasiko to n gbaradi lati kopa ninu eto idibo gomina ipinlẹ Osun lọdun 2018 ko le wọle fun saa keji.

Oríṣun àwòrán, Davido
Adedeji Adeleke: Baba olowo to ni ileesẹ nlanla ati fasiti
Ọjọ kẹfa, oṣu Kẹta, ọdun 1957 ni wọn bi Adedeji Tajudeen Adeleke, ẹni to jẹ ogbontarigi nidi iṣẹ okoowo.
Adedeji Adeleke to jẹ baba gbajugbaja olorin takasufee nni, David Adeleke ni oludasile fasiti Adeleke nipinlẹ Osun.
Yatọ fasiti ti Adedeji Adeleke da silẹ, oun tun ni oludasilẹ ileeṣẹ Pacific Holdings Limited, to si tun jẹ ẹgbọn si Gomina Ademola Adeleke to n ṣakoso ipinlẹ Osun lọwọlọwọ.
Ipinlẹ Enugu ni wọn bi Adedeji Adeleke si lọdun 1957 naa, to si kẹkọọ nile ẹkọ alakọbẹrẹ ti Ansar-Ud-Deed ati Seventh-Day Adventist.
Lẹyin eyi lo lọ si ilẹ Amẹrika lati tẹsiwaju ẹkọ rẹ ni fasiti Western Kenturcky, nibi to ti kẹkọọgboye lẹka imọ eto iṣuna lọdun 1979 ati MBA lọdun 1981. Bakan naa lo tun kẹkọọgboye imran ni fasiti Pacific Columbia to wa ni Califonia lọdun 1983.

Oríṣun àwòrán, Dupe Adeleke
Modupeola Adeleke-Sanni
Gbajugbaja oluranlọwọ lawujọ ni Yeyeluwa Modepola Adeleke-Sanni nilẹ Naijiria ati kaakiri agbaye.
Yatọ si pe o jẹ alaanu awọn eeyan, naa lo tun jẹ olori agbegbe, to si tun jẹ ẹgbọn si Gomina ademola Adeleke tipinlẹ Osun.
Yeye Adeleke-Sanni ni aarẹ ẹgbẹ awọn obinrin ninu idile Adeleke jakejado.
Ọpọ eto ironilagbara ni obinrin naa ti ṣagbekalẹ rẹ lati maa fi ṣe iranlọwọ f'awọn obinrin, awọn alailobii, awọn alaini-ipa ati bẹẹbẹẹ lọ.
Ṣe loootọ lo jẹ pe awọn ẹgbọn gomina lo n ṣakoso ijọba Osun, kii ṣe Ademola Adeleke?
Saaju eto idibo gomina nipinlẹ Osun, ni ẹnu ti n kun gomina ipinlẹ naa pe oun kọ lo n dari eto isakoso nipinlẹ naa, amọ se lo n se abẹsinkawọ fun awọn ẹgbọn rẹ.
Awọn eeyan kan wa n naka aleebu si gomina Adeleke pe se lo fa akoso ipinlẹ Osun le ẹgbọn rẹ ọkunrin, Deji Adeleke, tii se baba olowo nipinlẹ Osun lọwọ, ẹni to tun jẹ baba gbajumọ akọrin takansufe nni, David Adeleke, ti ọpọ eeyan mọ si Davido.
Bakan naa ni wọn ni ẹgbọn gomina lobinrin, Dupe Adeleke Sanni, ti ọpọ eeyan n pe ni Yeye lo jẹ igi lẹyin ọgba fun gomina Adeleke to si n pasẹ awọn igbesẹ ti yoo gbe lori eto akoso ipinlẹ Osun fun.
David Adeleke: Gbajumọ akọrin takansufe
Bi wọn ba ni ki awọn ọdọ tabi ọmọde asiko yii darukọ awọn olorin takusufee ti wọn mọ, ki wọn too darukọ mẹta, wọn gbọdọ darukọ Davido, iyẹn David Adeleke mọ wọn.
Kii ṣe ilẹ Naijiria nikan ni David Adeleke ti gbajumọ, kaakiri agbaye ni, to si niwe igbelu lawọn orileede kan.
Davido wa lara awọn olorin takasufee ti aye n gba tiẹ lasiko yii, to si jẹ ọmọ bibi Adedeji Adeleke to jẹ ẹgbọn si Ademola Adeleke, gomina ipinlẹ Osun lọwọlọwọ.


























