Ohun tí a mọ̀ nípa bí wọ́n ṣe jí àwọn èèyàn gbé nínú bọ́ọ̀sì tó ń kó àwọn àgùnbánirọ̀ láti Ibadan lọ sí àgọ́ NYSC ní Imo àti Akwa Ibom

Oríṣun àwòrán, KOLA SULAIMON/AFP via Getty Images
Awọn agbebọn kan ti ji awọn eeyan mọkandinlogun, pupọ ninu wọn jẹ agunbanirọ to n lọ bẹrẹ eto isinruulu wọn.. Ọkọ bọọsi meji to ko awọn eeyan arinrinajo naa lawọn agbebọn naa dabu rẹ ni ipinlẹ Imo ti wọn si ko awọn eeyan inu rẹ lọ.
Awọn ibudo ifinimọle awọn agunbanirọ to wa ni ipinlẹ Imo ati Akwa Ibom ni awọn bọọsi naa n ko awọn eeyan naa lọ ki wọn to ji wọn gbe ni Ọjọbọ.
Ọgbẹni Isaiah Akpan to ṣalaye ọr naa fun BBC sọ pe, '"meji ninu awọn ọkọ mi gbe awọn eeyan lati ilu Ibadan lalẹ ana, ọkan ninu rẹ n lọ si agọ ifinimọle NYSC ni Akwa Ibom, ikeji si n lọ si ti Ipinlẹ Imo".
O ni wọn ji gbogbo awọn arinrinajoinu bọọsi akọkọ gbe, wọn si ji mẹrin gbe ninu ikeji.
"Eyi sọ iye awọn ti wọn ji gbe di mọkandinlogun
Ki ni ọlọpaa sọ?
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Imo, Henry Okoye sọ fun BBC peọrọ naa ti kan awọn ọlọpaa leti























