Òṣèré tíátà Mount Zion, Omooba Oluwasegun Oyeyemi jáde láyé

Oríṣun àwòrán, Facebook/Omooba Oluwasegun Oyeyemi
Oṣere tiata ẹsin Kristẹni, Omooba Oluwasegun Oyeyemi, ti dagbere faye lẹni ọdun mejidinlogun.
Gẹgẹ bii ohun ti a gbọ, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹfa, ọdun 2026 yii Oyeyemi jade laye.
Iroyin ni ile iwosan fasiti Babcok, to wa ni Ikenne, nipinlẹ Ogun ni oloogbe naa ti dagbere faye.
Omooba Oluwasegun Oyeyemi gbajumọ lẹyin ipa ribiribi to ko nini ere agbelewo Abattoir, eyii ti ajọ to n gbe fiimu Kristẹni jade, Mount Zion Faith Ministries (MZFM), ṣe.
Ọpọ awọn ololufẹ rẹ, to ti fi mọ oludasilẹ MZFM, Mike Bamiloye ati ọmọ rẹ Joshua Mike-Bamiloye lo ti bẹre si n ṣedaro Oyeyemi bayii.
Lẹyin aisan ranpẹ ni ọdọkunrin naa fi aye silẹ lẹni ọdun mejidinlogun.
Taa ni Oluwasegun 'Omooba' Oyeyemi?

Oríṣun àwòrán, Owojori Rebecca Oluwatosin
Ọjọ karun un, oṣu Kẹfa, ọdun 1988 ni wọn bi Oyeyemi niluu Ibadan, to jẹ olu ilu ipinlẹ Oyo.
Orukọ baba rẹ ni Babatunde Oyeyemi ti iya rẹ si n jẹ Comfort Oyeyemi.
O kẹkọọ jade nipa imọ Physics and Solar Energy ni fasiti Bowen to wa nipinlẹ Ogun lọdun 2011 ko to bẹrẹ iṣẹ ina solar fun awọn eeyan ninu ile ati n ọọfisi wọn.
Oun ni adari ileeṣẹ ati ọkan lara awọn oludasilẹ ileeṣẹ Grinsor Technology Limited (Grinsor Energy and Renewables), to n ri si ọrọ ina solar.
Yatọ si iṣẹ yii, o tun maa n ṣe ere agbelewo fun awọn ọmọlẹyin Krsiti.
Omooba fẹran bọọlu afẹsẹgba to bẹẹ to fi darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu STB FC niluu Ibadan.
O jẹ ẹni to fẹran Jesu, o fẹran Ọlọrun, kii si n fa wahala.
Oloogbe naa fi iyawo, ọmọ meji, obi atawọn ibatan rẹ mii silẹ saye lọ.
Wayi o, ọpọ araalu lo ti bẹrẹ si n ṣedaro iku rẹ ti wọn si ti n ba awọn mọlẹbi rẹ kẹdun iku rẹ bayii.



























