Báwo ni owó PFIPC ṣe wọ́ àbá ìsúná tó bá jẹ́ ìjọba kò mọ nípa àjọ náà lóòótọ́, èmi kọ́ ni mo ṣé e, mo wà ní àhámọ́ ọlọ́pàá lásìkò náà - Adeyemi sọ nínú fídíò tuntun

Oríṣun àwòrán, PFIPC/INSTAGRAM
Adeniyi Adeyemi, ẹni to n koju ẹsun pe o ṣe idasilẹ ayederu ileeṣẹ Presidential Foreign Intervention Promotion Council, PFIPC, ti jade sọrọ ninu fidio tuntun, to si sọ idi to fi ṣagbekalẹ ileeṣẹ naa.
Adeyemi ni oun da ileeṣẹ naa silẹ lati le fi pe awọn oludokoowo wọ Naijiria ati lati mu igbega ba iṣejọba Bola Ahmed Tinubu, pe igbesẹ oun kii ṣe fun ere ara oun nikan.
Ninu fidio kan to gba ori ayelujara ṣafihan bi Adeyemi ṣe n ba gbajumọ ori ayelujara, Martins Otse ti ọpọ eeyan mọ si VeryDarkMan sọrọ.
O sọ ninu fidio naa pe oun ko mọ bi owo ti wọn ya fun ajọ naa ṣe wọnu aba isuna ọdun 2026 nitori oun w ani ahamọ ọlọpaa lasiko ti wọn gbe aba isuna naa kalẹ.
Nigba to n sọrọ lori bi ileeṣe aarẹ ṣe ni awọn ko mọ ohunkohun nipa ajọ naa labẹ awọn ileeṣẹ ati ajọ to wa labẹ ijọba apapọ, Adeyemi ni ọrọ naa ya oun lẹnu nitori oun ko mọ bi aba isuna ajọ ti wọn sọ pe awọn ko mọ ṣe wọnu aba isuna.
O ni ahamọ awọn ọlọpaa ni oun wa lasiko ti wọn n ṣagbeyẹwo awọn aba isuna ọdun 2026 nile aṣofin.
"Bawo ni wọn ṣe maa sọ pe awọn ko mọ nipa ajọ ti aba isuna rẹ wa ninu aba isuna orilẹ ede Naijiria fun odun 2026? Emi kọ ni mo ṣe aba isuna naa, mo wa ni ahamọ ọlọpaa nigba naa."
Adeyemi ṣalaye pe ni oṣu Kẹwaa, ọdun 2025 ni wọn pe oun lati ileeṣẹ ọlọpaa ni Abuja pe olori oṣiṣẹ ileeṣẹ aarẹ kọwe ẹsun nipa oun.
O ni oun lọ sileeṣẹ ọlọpaa naa lati lọ dahun awọn ibeere ti wọn fẹsun rẹ kan oun amọ ti wọn fi oun si ahamọ fun ọjọ metalelogun.
O sọ pe ohun ti wọn fẹsun rẹ kan oun ni pe wọn ni ki oun wa ṣalaye bi oun ṣe ni awọn iwe ẹri ti oun ni lori ajọ naa lọwọ ti wọn si fi oun si ahamọ.
"Ọjọ mẹtalelogun ni mo lo ni ahamọ ọlọpaa, emi kọ ni mo ṣe aba isuna ajọ PFIPC"
O fi kun pe awọn ọlọpaa beere iwe idanimọ oun ati iwe ti wọn fi gba oun siṣẹ, ti oun si fun wọn ni ẹni to ba oun gba iwe igbanisiṣẹ naa.
O ni lẹyin naa ni wọn fi oun si ahamọ lati ọjọ Kẹtalelogun, oṣu Kẹwaa titi di oṣu Kọkanla ọdun 2025, to si jẹ pe nigba ti oun fi maa jade kuro ni ahamọ, wọn ti pe oun lẹjọ, ti wọn si tig be ọfiisi ti oun n lo fun ileeṣẹ mii.
O ni oun da ajọ naa silẹ gẹgẹ bi ọmọ Naijiria rere ti oun jẹ, ti oun si lo owo ara oun lati fi gba ọfiisi, san owo tabua ki wọn fi gbe ajọ naa le oun lọwọ nitori oun ni igbagbọ pe igbesẹ naa maa pe awọn oludokoowo wọ Naijiria lati ilẹ okeere.
O fi kun pe idasilẹ ajọ naa waye nipasẹ afojusun lati mu ki awọn oludokoowo wọ Naijiria, ti awọn si ti n ṣe eyi pẹlu nini ajọṣepọ pẹlu awọn ileeṣẹ, lajọlajọ ati ẹka ijọba lọkanojọkan to fi mọ awọn ileeṣẹ to n ri si iwa ajẹbanu.
"Kii ṣe nitori ara mi ni mo ṣe gbe ajọ naa kalẹ. Ṣaaju ki gbogbo awọn awuyewuye yii to waye, a ti n gbaradi fun apero to maa milẹ titi, tawọn oludokoowo kaakiri agbaye maa kopa nibẹ."
Lori ẹsun pe Adeyemi n fẹsun kan ileeṣẹ aarẹ lori iṣẹlẹ yii, olori oṣiṣẹ ileeṣẹ aarẹ, Femi Gbajabiamila, Adeyemi ni oun ko ba Gbajabiamila ṣe ipade ri ayafi ni ọrọ ti awọn n sọ lori foonu latara ọrẹ oun to ti doloogbe bayii, Dolapo Tanimola.
Adeyemi ni ọrẹ oun to ba oun kan si Gbajabiamila, ti oun fi sanwo fun idasilẹ ajọ naa ti jade laye bi o ṣe jona mọle ninu ijamba ina kan to waye ni Utako, Abuja.
Bakan naa lo fi kun pe awọn ti n lepa ẹmi oun ninu oṣu Kẹsan-an, ọdun 2026 ki ori to ko oun yọ lọwọ awọn agbebọn to fẹ gbẹmi lọrun oun.
"Mo maa lọ ko gbogbo awọn iwe ẹri mi fawọn ọlọpaa laipẹ"
O tẹmpẹlẹmọ pe gbogbo iwe ati akọọlẹ to ṣatilẹyin fun idasilẹ ajọ naa ni oun ni lọwọ, ti oun si maa ko gbogbo rẹ lọ sọdọ awọn ẹṣọ aabo to ba ya.
"Mo maa lọ fara mi kalẹ fun awọn ọlọpaa ati DSS laipẹ pẹlu gbogbo awọn iwe to wa lọwọ mi lati ṣe iranwọ fun iwadii ti wọn n ṣe.
Ṣaaju ni Adeyemi ti ni oun yoo ṣe afọmọ orukọ oun nitori oun ti ṣetan lati koju igbẹjọ lati wẹ ara oun mọ.
Adeyemi sọ eyi nigba to n kopa lori eto kan ni ileeṣẹ iroyin Channels Television sọ pe oun ti ṣetan lati wẹ ara oun mọ lori awọn ẹsun ti wọn fi kan oun pe oun ṣe agbekalẹ ayederu ajọ ijọba ati iwe igbanisiṣẹ.
O ni oun ni igbagbọ pe ile ẹjọ maa ṣedajọ lori iṣẹlẹ naa bo ṣe tọ, to si oun kii ṣe onijibiti tabi gbajuẹ gẹgẹ bi iroyin ṣe n gbe.
O ni oun maa fun ile ẹjọ laaye lati ṣiṣẹ ọwọ wọn, ki wọn si wẹ oun mọ lori gbogbo ẹsun ti wọn fi kan oun.
O sọ pe oun maa ri daju pe oun fi bi eto igbẹjọ naa ba ṣe n lọ lati fi to awọn araalu leti nitori awọn agbẹjọro oun ti wa lori igbẹjọ naa bayii.
Awuyewuye lori ajọ PFIPC bẹrẹ si ni di oun ti awọn eeyan n sọrọ nipa rẹ lẹyin ti ijọba sọ pe awọn ko mọ nipa idasilẹ rẹ amọ ti aba isuna rẹ wọnu aba isuna Naijiria fun ọdun 2026.
Ileeṣẹ aarẹ ni awọn ko mọ ohunkohun nipa idasilẹ ajọ naa, ti Femi Gbajabiamila si pẹjọ lori pe wọn lo orukọ oun lati gbe ayederu igbanisiṣẹ jade.
Aarẹ Naijiria, Bola Tinubu ti wa dari ajọ to n ri si iwa ibajẹ, Independent Corrupt Practices and Other Related Offences Commission, ICPC lati ṣewadii ọrọ yii ki wọn si jabo laaarin oṣu kan pere.
Aare tun paṣẹ pe ẹnikẹni ti ICPC ba ṣawari pe o lọwọ ninu bi wọn ṣe gbe owo ajọ naa wọ aba isuna ọdun 2026 ni wọn gbọdọ fi lede, ti yoo si koju ijiya to tọ.
Ile aṣofin agba kọ aba lati ṣewadii ẹsun naa
Ẹwẹ, nibi ijiroro ile aṣofin agba to waye niluu Abuja lọjọru ni wọn ti kọ aba lati ṣewadii awọn ẹsun to n waye lori bi owo ajọ PFIPC ṣe wọnu aba isuna ọdun 2026.
Nibi ijiroro ile to waye naa ni aṣofin lati ipinlẹ Kano, Suleiman Kawu ti gbe aba kalẹ pe ki ile aṣofin ṣe iwadii awuyewuye to n lọ naa lojuna ati da aabo bo ijọba apapọ ati ile aṣofin paapaa bo ṣe jẹ pe aba isuna naa gba iwaju wọn kọja.
Kawu ninu aba rẹ sọ pe lati bii ọsẹ kan seyin ni awuyewuye ti n waye lori ajọ naa, tawọn eeyan si ti n naka aleebu sawọn alaṣẹ, ti o si yẹ lati da si.
Amọ igbakeji aarẹ ile aṣofin agba, Barau Jibrin da aba naa nu bi o ṣe ni ko nilo ki wọn jiroro lori aba naa nitori ijọba apapọ ti n ṣiṣẹ le lori.
Jibrin sọ pe Aarẹ Bola Tinubu ti dari ajọ ICPC lati ṣewadii gbogbo ẹsun naa, to si rọ awọn aṣofin pe ki wọn jẹ ki awọn ṣe suuru di igba ti ijọba fi maa pari iwadii wọn.



























