Èyí lohun tí ìjọba pinnu láti ṣe lẹ́yìn tí omíyalé fojú àwọn olùgbé ìlú Eko rí màbo

Oríṣun àwòrán, @MAZITUNDEEDNUT/INSTAGRAM
Ojo arọọrọda to n waye paapaa ni ipinlẹ Eko lẹnu ọjọ meta sẹyin bayii n ko ipaya ba awọn olugbe ipinlẹ Eko.
Ohun to n fa ipaya naa ko ṣẹyin omiyale agbara ya ṣọọbu to maa n saba waye lasiko ojo bayii lawọn agbegbe kan to fi Victoria Island, Lekki, Gbagada ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Lati ọjọ Aiku, ọjọ Kejidinlọgbọn, oṣu Kẹfa ni awọn olugbe ipinlẹ Eko ti n fi oniruuru aworan ati fidio bi ẹkun omi ṣe n ṣọṣẹ ni adugbo wọn ṣọwọ sori ayelujara.
Eyi to ṣe pabanbari ibẹ ni ojo to rọ lati owurọ ọjọ Iṣẹgun, ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹfa titi di irọlẹ malẹ ọjọ naa ni eyi to fa ki ọpọ ma le jade kuro nile lọ si ibikibi.
Yatọ si pe ojo naa se awọn eeyan mọle, ọpọ ontaja ni ko ribi lọ sidi igba wọn, tawon oṣiṣẹ naa ko si ibi iṣẹ lọ latari ẹkun omi to gba gbogbo igboro.
Awọn fidio to gba ori ayelujara ṣafihan bi ẹkun omi ṣed waye ni awọn agbegbe bii Oshodi, Victoria Island, Lekki, Ikeja, Gbagada, Mushin, Mafoluku ati bẹẹ bẹẹ lọ.
Ọpọ awon agbegbe yii ni awọn ọlọja ko ti le ṣi ṣọọbu, tawọn olugbe ibẹ naa ko le jade nitori agbara ojo ti gbale ati ṣọọbu mọ wọn lọwọ.
Ohun to tun ya awọn eeyan lẹnu ni pe ọpọ awọn agbegbe ti ẹkun omi, to jẹ ohun to saba maa n waye lawọn agbegbe kan lọdọọdun ni ipinlẹ Eko, ni awọn naa koju iṣẹlẹ naa ni ọjọ Iṣẹgun.
Awọn araalu wa rọ ijọba ipinlẹ Eko lati tete mojuto ẹkun omi ati agbara ya ṣọọbu yii, ki wọn si ka a kun iṣẹlẹ pajawiri to nilo amojuto ni kiakia.
Ṣaaju ni ijọba ipinlẹ Eko ṣekilọ fawọn araalu lati gbaradi fun ojo to maa waye fun ọjọ diẹ eyi to le fa omiyale agbara ya ṣọọbu.
Bakan naa ni ileeṣẹ ijọba apapọ to n ri si ọrọ ayika ti kede pe o ṣeeṣe ki ẹkun omi waye ni awọn agbegbe bii Apapa, Badagry, Epe, Eti-Osa, Ikeja, Ikorodu, Ikoyi, Lagos Island, Lekki, Ojo, Orile-Agege, Surulere, Agege, Alimosho ati Kosofe.
Ijọba rọ awọn eeyan to n gbe ni awọn agbegbe yii lati ri daju pe gbogbo koto idaminu wọn ni aaye wa nibẹ ti omi le gba kọja lojuna ati mu adinku ba ipa ti omiyale agbara ya ṣọọbu naa le fa.

Oríṣun àwòrán, @MAZITUNDEEDNUT/INSTAGRAM
Ijọba ipinlẹ Eko bẹrẹ igbesẹ lati mu adinku ba ipa ẹkun omi
Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Eko ti wa rọ awọn eeyan lati ṣe suuru pẹlu ẹkun omi to waye lọjọ Iṣẹgun.
Kọmiṣanna fun eto ayika ati ipese omi ni ipinlẹ Eko, Tokunbo Wahab ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Iṣẹgun ṣalaye pe Gomina Babajide Sanwo-Olu ti buwọlu gbigbẹ ati ṣiṣe itọju awọn koto idominu mejidinlọgbọ lojuna ati mu adinku ba omiyale kaakiri ipinlẹ naa.
Wahab ṣalaye pe ayipada oju ọjọ lo ṣokunfa bi ojo ṣe pọ laaarin ọjọ diẹ lera wọn eyi to fa omiyale kaakiri awọn agbegbe ni ipinlẹ Eko.
O woye ẹkun omi ati omiyale agbara ya ṣọọbu to waye laaarin ọjọ meji yii kii ṣe ohun to ṣẹlẹ ni Naijiria nikan nitori ọpọ awọn orilẹ ede mii lẹkun Africa ati North America ni wọn koju iṣẹlẹ ẹkun omi ni ọjọ kan naa.
O ni awọn koto idominu ti wọn ti kun fọfọ atawọn ojuṣan agbara tawọn eeyan n da ilẹ si wa lara ohun to n fa omiyale ni awọn agbegbe bii Victoria Island, Lekki, Ikeja, Gbagada, Mushin, Mafoluku ati bẹẹ bẹẹ lọ ni ipinlẹ Eko.
Wahab sọ aridaju rẹ pe ijọba ti n gbe igbesẹ to yẹ lati mojuto awọn ajuṣan agbara, awọn koto idominu ni awọn agbegbe ti omiyale ti ṣọṣẹ ati pe awọn oṣiṣe ijọba n sa gbogbo ipa wọn lati ri pe awọn omi naa ko maa darogun gun igba pipẹ.
Bakan naa lo rọ awọn eeyan lati ye da ilẹ sawọn ojuṣan agbara mọ nitori aw.ọn nnkan to maa n jẹ ki ẹkun omi ni ipa to pọ lasiko ojo niyẹn.
Bẹẹ naa lo rọ awọn awakọ lati ye wakọ ninu agbara ojo, to si rọ awọn olugbe agbegbe to ṣeeṣe ki ẹkun omi tun ti waye lati gbọ ikilọ, ki wọn si ṣamulo awọn ikilọ naa ki ipa ojo arọọrọda ma ba a di ohun ti yoo tun ṣakoba fun igbe aye wọn.
O fi kun pe ipa ayipada oju ọjọ ti n foju han kaakiri agbaye tawọn ilu ti omi pọ nibẹ si n koju ojo to pọ ju awọn ilu mii lọ.



























