Olórí ọmogun Naijiria ṣàlàyé ibi tí iṣẹ́ dé lori ìgbìyànjú láti dóòlà àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ tí wọ́n jí gbé l'Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Olori ọmogun ori ilẹ ní Naijiria, Ọgagun Waidi Shuaibu, ti sọ pe iṣẹ si n lọ láti doola awọn akẹẹkọ at'awọn olukọ ti wọn ji gbe l'Ogbomoso ní ìpínlẹ̀ Oyo.
Ọgagun Shuaibu sọrọ yii fawọn akọroyin lopin ọsẹ to kọja niluu Port Harcourt nibi ayẹyẹ ayajọ ọjọ awọn ọmogun tí ọdun 2026.
Lọjọ kẹẹdọgbọn oṣù Karun un lawọn janduku agbébọn yawọ ile ẹkọ girama to wa ni Esinele ati ile ẹkọ alakọbẹrẹ ni Yawota ní ìjọba ìbílẹ̀ Oriire; nibi ti wọn ti ji àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ to le logoji lọ.
Olori ọmogun ori ilẹ Naijiria sọ pe "ileeṣẹ ọmogun si n tẹsiwaju akitiyan rẹ lati doola awọn akẹẹkọ at'awọn olukọ ti wọn ji gbe nipinlẹ Oyo.
Mo si fi n da a yin loju pe a ti ń ṣe àṣeyọrí nínú igbiyanju wa lati doola awọn t'awọn agbébọn ji gbe lọ naa."
Ọgagun Shuaibu ni oun gbagbọ pe gbogbo awọn ti wọn ji gbe yii ni wọn yoo pada wale ni alaafia lati lọ ba ẹbi wọn.
Olórí ọmogun sọ pe ileeṣẹ ologun n ṣiṣẹ takun takun kaakiri gbogbo ẹkun orilẹ ede Naijiria lati wa ojutuu sí ètò aabo to mẹhẹ.
Ọgbẹni Shuaibu ní ileeṣẹ ọmogun ti ṣe aṣeyọri nla nipasẹ ikọ Operation Hadin Kai to n gbe ija kojú àwọn janduku agbébọn at'awọn agbésùnmọ̀mí.
O ni laipẹ yii ni ọwọ iléeṣẹ́ ológun tẹ ogbontarigi adari agbésùnmọ̀mí, Abu Bilal al-Minuki, pẹlu ajọṣepọ awọn ọmogun Amerika.
Shuaibu ni ko din ni agbésùnmọ̀mí 1,872 t'awọn ọmogun ti mu balẹ, nigba ti ọpọ ninu wọn ti jọwọ ara wọn pe awọn o ṣe igbesunmọmi mọ.
"Alaafia ti jọba lẹkun iwọ oorun guusu yatọ si ipinlẹ Oyo ti wọn ti ji àwọn akẹkọọ ati olùkọ lọ"
Ọgagun Shuaibu ni aseyori ileeṣẹ ọmogun Naijiria ti jẹ ki ọpọ eeyan ti wọn ti sa kuro ni ibugbe wọn tẹlẹ tori awon agbesunmomi pada sí ibugbe wọn bayii.
O fikún ọrọ rẹ pe alaafia ti jọba ni gbogbo awọn ipinlẹ Yoruba, yatọ si ipinlẹ Oyo nikan t'awọn agbébọn ti jí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ gbe lọ.
O ni ileeṣẹ ologun yoo tubọ gba ọmogun ẹgbẹrun mejidinlọgbọn sawọn Ibudo ologun to wa ni Osogbo, Zaria, ati Amasiri-Edda nipinlẹ Ebonyi.
"Laipẹ yii ni mo pàṣẹ pé kí ileeṣẹ ologun gba awọn ọdọ ẹgbẹrun mejidinlọgbọn ṣiṣẹ ologun lati seranwọ lori ipese aabo to peye kaakiri orilẹ ede Naijiria.
Ni bayii, ko din ni ẹgbẹrun mẹfa to ti kẹkọọ jade ni Ibudo ologun to wa ni Zaria nigba ti ẹgbẹrun marun un ti ṣetan mi Osogbo.
Ẹgbẹrun mẹta ọmogun yoo tun ṣetan lati darapọ mọ ileeṣẹ ologun ni ibùdó ọmogun to wa ni Amasiri-Edda," Ọgagun Shuaibu ṣalaye.


























