Kókó ọ̀rọ̀ tí Tinubu sọ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ìjinigbé àti ìpànìyàn tó wáyé nílé ẹ̀kọ́ Ogbomoso

Oríṣun àwòrán, Bayo Onanuga/X/Olamiju Akala/X
Aarẹ Bola Tinubu ti kọminu lori iroyin kan to sọ pe awọn janduku agbebọn ti ṣekupa ọkan lara awọn olukọ ti wọn ji gbe pẹlu awọn akẹkọọ nile ẹkọ girama to wa niluu Esinele l'Ọgbomoso lọsẹ ti kọja.
Ọjọ Ẹti to kọja lawọn janduku agbebọn ọhun ya wọ ile ẹkọ naa ni ijọba ibilẹ Oriire nipinlẹ Oyo nibi ti wọn ti ji awọn akẹkọọ atawọn olukọ gbe lọ.
Ninu atẹjade kan ti Oludamọran aarẹ lori eto iroyin, Bayo Onanuga, fi sita, Tinubu kẹdun pẹlu ẹbi awọn eeyan tawọn agbebọn naa ti pa.
''Inu mi bajẹ lori iroyin to sọ pe awọn agbebọn ti ṣekupa ọkan lara awọn olukọ ti wọn ji gbe.
Mo n fi asiko yii kẹdun pẹlu ẹbi gbogbo eeyan ti wọn ji gbe lọ.''
Aarẹ Tinubu sọ pe awọn ẹṣọ eleto aabo n ṣiṣẹ takun takun bayii lati doola awọn ti wọn ji gbe naa nibi ti wọn ko wọn pamọ si.
Tinubu ko ṣai sọ nipa iwulo idasilẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ pẹlu iṣẹlẹ ọhun.
''Awọn iṣẹlẹ ijinigbe bayii maa n sọ nipa iwulo ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ, tori awọn lo le de awọn igberiko.
Ile aṣofin agba gbọdọ ṣiṣẹ lori abadofin idasilẹ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ ni kiakia.'' Tinubu lo sọ bẹẹ.
Ko tii si ẹgbẹ agbesunmọmi to tii sọ pe awọn lawọn wa nidii iṣẹlẹ naa titi di asiko yii.
Amọ, Tinubu sọ pe awọn agbebọn to n ji eeyan gbe pawo naa lo wa nidi iṣẹlẹ ọhun.
Ẹwẹ, ijọba ti sọ pe awọn si n gbiyanju lati mọ iye akẹkọọ ti wọn ji gbe lọ.
Ṣaaju ni Gomina Seyi Makinde ipinlẹ Oyo ti sọ pe olukọ meje lawọn janduku ajinigbe ọhun ji gbe lọ.
Tinubu fikun ọrọ rẹ pe awọn ẹṣọ eleto aabo yoo ri pe awọn doola gbogbo awọn ti wọn ji gbe lọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Makinde ní ìjọba kò gbọdọ̀ fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ètò ààbò, ṣe ìfilọ́lẹ̀ ikọ̀ tí yóò máa mójútó ìwà ọ̀daràn

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi makinde ti ṣe ifilọlẹ ikọ ti yoo maa mojuto iwa ipa iyẹn "Violent Crime Response Unit (VCRU) ti ijọba apapọ ṣẹṣẹ ṣagbedide rẹ ni ileeṣẹ ọlọpaa.
Makinde gboriyin fun igbesẹ naa, bo ṣe ni ṣiṣe agbedide ikọ bẹẹ lasiko yii jẹ ohun to tọna paapaa bi iṣẹlẹ ijinigbe atawọn iwa ipa ṣe n pọ si ni ojoojumọ.
Nigba to n sọrọ nibi ifilọlẹ naa to waye lọjọ Abamẹta ni olu ileeṣẹ ọlọpaa to w ani agbegbe Eleyele ni ilu Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo, ni ṣiṣe agbedide ikọ naa ṣafihan erongba ijọba ipinlẹ ati ijọba apapọ lati mu igbooro bae to aabo ni ipinlẹ Oyo.
Makinde ni ijiroro ti oun ni pẹlu Kọmiṣanna ọlọpaa Oyo fi han pe ikọ naa ni akọkọ iru rẹ ni guusu ẹkun iwọ oorun Naijiria.
O ni iṣẹlẹ ijinigbe to waye ni ijọba ibilẹ Oriire nibi ti wọn ti ji ọpọ awon ọmọde gbe jẹ ki siṣe idasilẹ ikọ naa ṣe pataki.
O fi kun pe iṣẹlẹ ijinigbe to waye naa ti mu ki awọn eeyan ipinlẹ Oyo wa ninu inu fu aya fun bayii atawọn ẹbi awọn ọmọ tawọn ajinigbe naa ṣekọlu si.
Gomina nMakinde tẹsiwaju pe ijọba ti n ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ẹṣọ aabo lojuna ati fidii ohun to ṣẹlẹ lori ikọlu naa mulẹ
Bakan naa lo ba awọn obi awọn ọmọ ti wọn padanu emi wọn kẹdun, to si gbadura ki Ọlọhun tẹ awọn ọmọ naa si afẹfẹ rere.
O ni eto aabo jẹ ohun ti ẹnikẹni ko gbọdọ fi ṣere rara bo ṣe ni iṣẹlẹ to waye naa ti ṣafihan inilo lati maa wa ni oju lalakan fi n ṣọri ni gbogbo igba.
O woye pe awujọ ti aabo rẹ ba peye ni idagbasoke ti maa n bae to ọrọ aje, idokoowo, inaju ati igbayegbadun awọn eeyan, ti awọn eeyan si maa ni itẹriba fawọn ohun to jẹ ti ijọba.
Gomina wa juwe ikọ VCRU bi awọn to poju owo, ti wọn si le tete ji giri si ojuṣe wọn lsti koju iwa ọdaran, ti wọn ko si ni fi igba kan bọ omiran ninu, ti wọn yoo si maa bọwọ fun ẹtọ ọmọniyan.
Bẹẹ naa lo tun jẹwọ atilẹyin ti n ṣe fawọn ẹṣọ aabo, to si ni awọn ko ni dawọ awọn atilẹyin bii ipesẹ nnkan irinsẹ atawọn ohun eelo mii ti wọn nilo lati fi ṣe ojuṣe wọn.
Makinde wa kan saara si ẹka naa, to si ni ohun gbagbọ pe wọn ti gbaradi lati bẹrẹ ojuṣe wọn.
O ni awọn yoo maa ṣe atilẹyin fawọn ẹṣọ aabo ni ipinlẹ Oyo pẹlu erongba pe wọn maa tẹsiwaju lati maa da aabo bo emi ati dukia awọn araalu ati ti ijọba.
O tẹmpẹlẹmọ pe ojuṣe aabo kii ṣe fun ẹnikankan rara, to si parọwa sawọn araalu ki wọn wa ni oju lalakan fi n ṣọri ki wọn si maa ṣe atilẹyin fawọn ẹṣọ aabo ni gbogbo igba.
Bakan naa lo tun gboriyin fun ọlọpaa Naijiria ati ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo fun iṣẹ naa bi o ṣe kede pe ajọṣepọ ijoba apapọ ati ijoba ipinlẹ ni.
Ṣaaju ni Kọmiṣanna ọlọpaa Oyo, Abimbola Ayodeji Olugbenga sọ pe idasilẹ VCRU lo jẹ afojusun ọga agba ọlọpaa Naijiria lojuna ati mu ayipada ba awọn ikọ to n ṣiṣẹ ni ẹka naa tẹlẹ ri ki wọn ba a tun le maa ṣiṣẹ to poju owo.
O ni wọn ṣe agbedide ikọ naa lati tete maa mojuto iwa ọdaran to ba n waye lai tẹ ẹtọ awọn eeyan loju mọlẹ ati lai lugbadi ofin.
O ṣalaye pe gbogbo awọn ọlọpaa ti wọn ko sinu ikọ naa ni wọn ti ṣe idanilẹkọọ to peye fun ti wọn si maa ṣe agbedide igbimo laipẹ ti yoo maa mojuto iṣẹ ti wọn ba n ṣe.




























