Ẹgbẹ́ Arewa fọnmú lórí ìdúnkookò Sunday Igboho fáwọn Fulani pé yóò lẹ́yìn, Igboho fèsì padà

Sunday Igboho kọju sawọn adari ẹya Fulani to wa nilu Igboho, o n ba wọn sọrọ

Oríṣun àwòrán, Sunday Igboho

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 9

Ẹgbẹ Arewa Consultative Forum ati Northern Elders Forum ti ṣekilọ pe o ṣeeṣe ki iwa aitele ofin gbilẹ si ni Naijiria ti ijọba apapọ ko ba tete mojuto gbedeke ti gbajumọ to n ja fun idasilẹ Yoruba Nation, Sunday Igboho fun awọn olori Fulani to w ani ipinlẹ Oyo lori awọn eeyan tawọn ajinigbe ji gbe ni ipinlẹ naa.

Awọn ẹgbẹ naa, pẹlu awọn ẹgbẹ Fulani mii fẹsun kan Igboho pe nise ni o n fi ẹsun iwa ọdaran tawọn kan n n hu kan gbogbo odidi iran Fulani ati pe irufẹ iwa bẹẹ le ṣokunfa wahala, to si le mu ki ipenija ba iṣọkan orilẹ ede Naijiria.

Ikilọ yii lo n waye lẹyin ti fidio kan to ṣafihan ibi ti Igboho ti n ba awọn olori Fulani to wa ni ilu Igboho sọrọ to si n fun wọn ni gbedeke wakati meji lati gba itusilẹ awọn to wa ni ahamọ ajinigbe naa.

Agbẹnusọ ẹgbẹ Arewa Consultative Forum, Ọjọgbọn Tukur Muhammad-Baba ninu atẹjade kan to fi sita juwe gbedeke ti Igboho fun awọn eeyan naa bi ohun ti ko ba ofin mu, jẹ ohun to lewu, to si mu ipenija aabo to n ba Naijiria finra peleke si.

"Itanra ẹni jẹ ni ki eeyan maa sọ pe iran kan lo n huwa ijinigbe ni Naijiria lonii"

Muhammad-Baba ni ijọba apapọ, awọn ẹṣọ aabo, awọn ori ade ọrun ilẹkẹ atawọn olori ẹsin gbọdọ tete dide lati mojuto ọrọ naa ko to di ohun nla ti apa ko ni ka mọ.

O ni ojuṣe awọn alaṣẹ ni lati tete pe akiyesi Igboho si pe fifi iwa ọdaran kan gbogbo iran kan le ṣokunfa wahala ati pe fifun awọn Fulani ni gbedeke lori iwa tawọn perete kan wu tumọ si pe wọn n pe gbogbo iran Fulani ni ọdaran.

O woye pe ko i tii si ẹri kankan gboogi to fidi iran awọn to huwa ọdaran naa mulẹ, to si ni ọpọ eeyan lo ti n kopa ninu ijinigbe lati fi gba owo lai iran tabi ẹya kankan ṣe.

"Bi o ṣe fidi rẹ mulẹ pe iran Fulani ni awon ajinigbe to gbe awọn eeyan naa ko ye ẹnikẹni, a mọ pe ijinigbe lati fi gba owo ti di iṣẹ fun ọpọ eeyan lai fi iran, ẹsin tabi ẹya kankan ṣe."

Agbẹnusọ ẹgbẹ Arewa naa tun fi kun pe itanra ẹni jẹ ni ki eeyan maa sọ pe iran kan lo n huwa ọdaran, to si ni Igboho atawọn eeyan rẹ ko lẹtọọ kankan labẹ ofin lati fun awọn eeyan ni gbedeke ti wọn fun wọn naa.

Bakan naa lo bu ẹnu atẹ lu ijọba lori bi wọn ko ṣe mojuto eto aabo to fi mẹhẹ de ibi to wa bayii lonii eyi to n mu ki ọpọ awọn eeyan maa dide lati ja funra wọn.

Awọn ajinigbe kan n mura bii Fulani ni, wọn kii ṣe Fulani - NEF

Ọrọ Muhammad-Baba ko yatọ si iwoye ẹgbẹ Northern Elders Forum bi agbẹnusọ wọn, Ọjọgbọn Abubakar Jiddere naa ṣe woye pe ko tọna ki wọn maa fi iwa ọdaran awọn perete sọri gbogbo iran kan.

Jiddere woye pe ipenija to n ba Naijiria funra rẹ kọja ohun ti eeyan yoo tun maa runa si, to si ni iran Fulani gan ni ipenija aabo to ṣokunfa ijinigbe ati ipaniyan ti ṣọṣẹ fun julọ.

O ṣekilọ pe ọpọ awọn oniṣẹ ibi to n huwa ọdaran ti wọn wa ninu igbo ti wọn n mura bii Fulani ni kii ṣe iran Fulani ti wọn kan si n ṣe bẹẹ lati sọ iran naa lẹnu ni.

O tẹmpẹlẹmọ pe gbogbo iran to w ani Naijiria ni wọn ni ẹtọ kan naa labẹ ofin Naijiria ati pe gbogbo eeyan lo yẹ ki ipenija aabo to n ba Naijiria finra kọ lominu lai maa naka aleebu si iran kan ṣoṣo.

Bẹẹ naa lo ni ko yẹ lati maa dunkoko mọ awọn eeyan ti wọn n huwa, ti wọn n ṣiṣẹ wọn lọna to tọ labẹ ofin nitori iwa awọn perete kan.

N ko tabuku iran kankan, awọn ọ̀daràn tó jẹ́ ẹya Fulani ni mo n ba wi - Igboho fesi

Ẹwẹ, Sunday igboho ti wa sọ pe gbogbo ilakaka ati ija ti oun n ja jẹ lati mu igbooro ba aabo to ti mẹhẹ ni ilẹ Yoruba ati pe awọn afurasi ọdaran ni oun n ba wi pe oun ko tabuku iran kankan.

Igboho ni gbogbo igbesẹ oun n waye lati fopin si ijinigbe, igbesumọmi, ipaniyan atawọn iwa ọdaran mii to ti di tọrọ fọnka sile, to si n dunkoko mọ igbe aye irọrun fawọn eeyan nilẹ Yoruba.

Atẹjade ti agbẹnusọ Igboho, Olayomi Koiki fi lede rọ awọn ọmọ Naijiria lai fi ẹya tabi ẹsin ṣe lati maa ṣatilẹyin fun ijọba atawọn ẹṣọ aabo lati koju iṣoro aabo to n ba Naijiria finra.

Igboho ninu atẹjade naa ni awọn ẹgbẹ Arewa ti wọn n bu ẹnu atẹ lu ounn ṣi oun gbọ ati pe wọn n tu ọrọ oun ati gbedeke ti oun fun awọn naa si ọna mii ni.

O ni o yẹ ki gbogbo awọn ti wọn n bu ẹnu atẹ lu oun naa pawọpọ ṣe atilẹyin fun oun atawọn ẹṣọ aabo lati fopin si ipenija aabo ati lati a idajọ ododo fun awọn ti wọn ti fori ṣọta ipenija aabo ni Naijiria.

Sunday Igboho ti wọnú igbó bíi ẹ̀ẹ̀mẹrin, a kò tíì rí àwọn tí wọn jí gbé, ₦150m táwọn ajínigbé bèèrè là ń wá - Ọba Igboho

Sunday Igboho ati awọn ẹmẹwa rẹ to mu oniruuru ibọn lọwọ, duro si ẹba oju popo, igbo nla kan wa niwaju wọn pẹlu awọn mọto ti wọn gbe wa

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Ni opin ọsẹ to kọja yii ni iroyin nipa ijinigbe ati ipaniyan to n waye ni Oke Ogun ipinlẹ di ohun to lu si gbogbo aye.

Eyi ko ṣẹyin fidio kan to gba ori ayelujara nibi ti Sunday Adeyemọ ti ọpọ mọ si Sunday igboho ti n ba olori awọn Fulani sọrọ ni aafin Ọba ilu Igboho to si n fi itara han lori bi eto aabo ṣe ti mẹhẹ ni ilu naa.

Igboho fẹsun kan pe awọn Fulani ni awọn afurasi to n ji awọn eeyan gbe ni agbegbe naa ati pe oun ko ni kawọ rọ ni ilu baba oun, ki oun maa wo awọn ajinigbe naa lati maa da nnkan ru.

Igboho fẹsun kan pe awọn ajinigbe to gbe alaboyun atawọn ọmọ rẹ beere fun owo itusilẹ lati tu awọn eeyan naa silẹ amọ niṣe ni wọn pa ẹni to gbe owo lọ fun wọn lai tu awọn eeyan wọn silẹ.

Ọọdunrun miliọnu naira ni awọn ajinigbe naa kọkọ beere fun lati gba itusilẹ awọn eeyan naa ki wọn to dinku si aadọjọ miliọnu naira.

Sunday Igboho ati awọn ẹmẹwa rẹ to mu oniruuru ibọn lọwọ, duro si ẹba oju popo, igbo nla kan wa niwaju wọn pẹlu awọn mọto ti wọn gbe wa

Oríṣun àwòrán, Screenshot

"A ko tii ri awọn ti wọn ji gbe ti a n wa, awọn ajinigbe ni awọn maa gba aadọjọ miliọnu naira"

Oniruuru awuyewuye lo ti waye lori fidio naa, tawọn ileeṣẹ iroyin kan sig be iroyin pe awọn eeyan naa ti gba itusilẹ lẹyin ti Igboho dunkoko mọ awọn Fulani naa amọ ti alaga ijọba ibilẹ Oorelope ati ileeṣẹ ọlọpaa ti jiyan iroyin naa.

Nigba ti BBC News Yoruba kan si ọkan lara awọn Ọba ilu Igboho, Ona Onibode Igboho, Ọba Abdulrasheed Adetoyese Jaiyeola Kẹta fidi rẹ mulẹ pe awọn to wa ni ahamọ awọn ajinigbe naa ko i tii gba itusilẹ.

Ọba alaye naa ni aadọjọ miliọnu naira ti wọn n beere fun gẹgẹ bi owo itusilẹ ni awọn ṣi n wa, ti awọn ko si ri yanju titi di asiko yii.

"A o tii ri awọn ti wọn ji gbe ti a n wa, wọn ṣi duro lori pe awọn maa gba aadọjọ miliọnu naira naa ṣi ni.

"Sunday Igboho ti wọ inu igbo bii ẹẹmẹrin lẹnu igba to de pelu awọn eeyan rẹ, wọn o tii ri wọn."

Ona Onibode ti Igboho, Ọba Abdulrasheed Jaiyeola Kẹta joko lori itẹ, o wọ agbada toke tilẹ asọ ankara alawọ dudu ati eweko, o si de fila alawọ sokoleti, o fi ẹgba sọrun

"Sunday Igboho ba awọn olori Fulani sọrọ lati fi ṣẹru bawọn boya wọn maa ri awọn eeyan wọn ba sọrọ lati dena iwa ibajẹ"

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nigba to n sọrọ lori fidio to gba ayelujara nibi ti Sunday Igboho ti n ba awọn olori Fulani sọrọ, Ọba naa ni awọn gbe igbesẹ naa lati le wa ojutuu sọrọ awọn ajinigbe ti wọn n ṣọṣẹ ni agbegbe naa ni.

O ni oun to jẹ ki Sunday Igboho pe ipade naa ko ṣẹyin pe awọn Fulani ni awọn afurasi to n ji eeyan gbe ni agbegbe naa, ti awọn si gbe igbesẹ naa lati fi ṣẹruba wọn boya wọn maa ri awọn eeyan wọn ba sọrọ lati dena iwa ibajẹ.

O fi kun pe igbagbọ wa pe awọn Fulani to n gbe ni agbegbe Oke Ogun atawọn to n ṣiṣẹ ibi le ni ajọṣepọ nipasẹ pe iran kan naa ni wọn ati pe ọja Kara to wa ni agbegbe naa mu ki awọn Fulani maa pọ si nibẹ.

Ọba naa kọminu pe lodi si aye igba to jẹ pe awọn ọba maa n mọ igba ti alejo ba wọ ilu, o ni idasilẹ awọn ọja Kara ti ijọba n da silẹ kaakiri gbogbo ilu jẹ ko ṣoro fun awọn araalu lati le mọ nigba tawọn ajoji ba ti wọ ilu ati lati mojuto irufẹ awọn eeyan to n wọ agbegbe wọn.

"Ṣe bi nnkankan la maa sọ fun wọn lati dawọ awọn iwa ibi ti wọn n wu?

Wọn ni ọrọ aje ni gbogbo ibẹyẹn, ta ba sọ pe a maa le wọn kuro nibẹ yẹn, wọn o ni fẹ ki ọrọ aje wọn bajẹ, wọn a le mọ bi wọn ṣe maa ba awọn ọmọ wi lati dawọ iṣẹ ibi duro."

Ọba Ọba Abdulrasheed Adetoyese woye pe igbese ti Sunday Igboho ko buru nitori awọn eeyan ilu rẹ lo n gbiyanju lati da aabo bo, ti ko si ni dake maa woran ki nnkan maa bajẹ loju rẹ.

Ẹ kilọ fun Igboho lati ye dunkoko mọ awọn Fulani mọ, kii ṣe gbogbo iran Fulani ni ọdaran - Ẹgbẹ Fulani

Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn Fulani kan, the Concerned Fulani People of Nigeria ti kepe aarẹ Naijiria, Bola Ahmed Tinubu, Gomina ipinlẹ Oyo, Seyi Makinde atawọn ọba mii nilẹ Yoruba ti ṣekilọ fun Sunday Igboho lori ọrọ to sọ nipa awọn Fulani.

Ẹgbẹ naa ni ohun ti Igboho sọ nipa awọn ẹya Fulani to n gbe ni ipinlẹ Oyo ku diẹ kaato nitori o ko gbogbo iran awọn pọ ni.

Atẹjade ti adari ẹgbẹ naa, Ibrahim Barkindo Chubado fi sita lọjọ Aiku sọ pe pipe gbogbo Fulani ni ọdaran fun iwa ti awọn diẹ ninu wọn n wu le dena igbepọ alaafia to ti n waye ni agbegbe naa fun igba pipẹ laaarin awọn Yoruba ati Fulani ni agbegbe ọhun.

Ẹgbẹ naa tẹmpelẹmọ pe awọn iran Fulani ko fi aaye gba iwa ijinigbe, igbeṣumọmi atawọn iwa ọdaran mii ati pe ko yẹ ki wọn maa fi iwa ibajẹ kan kan gbogbo iran tabi ẹya.

O ni awọn Fulani to wa kaakiri orilẹ ede Naijiria ni wọn maa n huwa ọmọluabi, ti wọn si maa tẹle ilana ati ofin, ti ko si yẹ ki wọn maa di ẹbi awọn ọdaran ru gbogbo wọn.