Ìbejì ló wù wá láti fẹ́ láti ilẹ̀, a ti wà pọ̀ fún ọdún mẹ́wàá, a fẹ́ fẹ́ àwọn ìbejì kan tẹ́lẹ̀ àmọ́ ìwà àti ẹ́jẹ́ wa kò papọ̀ - Ìbejì Oguntoye
Se ni ariwo sọ ni ọjọ̀ Satide, Ogunjọ osu Kẹfa ọdun 2025 nigba ti Taiwo Ati Kehinde Oguntoye se igbeyawo pẹlu Taiwo ati Kehinde Adediran.
Ilu Ibadan tii se olu ilu ipinlẹ Oyo ni isẹlẹ naa ti waye, ti ọpọlọpọ awọn ibeji kaakiri agbaye si darapọ mọ wọn lati bawọn kopa nibi ayeyẹ naa.
Taiwo ati Taiwo fẹ ara wọn nigba ti Kehinde ati Kehinde naa gbe di tọkọtaya.
Awọn ibeji Oguntoye ti wọn jẹ ọmọ bibi Ibadan, olu ilu ipinlẹ Oyo, ti ọjọ ori wọn ti le logoji ọdun lo ti maa n sọ pe ibeji ni awọn maa fẹ nigba ti awọn ba maa di ẹni to n ni aya nile.
Awọn Taiwo ati Kehinde Oguntoye ti wọn jẹ ẹni to maa n ṣe agbatẹru ayẹyẹ ọdun ibeji to maa n waye ni ọdọọdun ni ilu Igbo Ora ṣe igbeyawo pelu awọn ibeji mii to jẹ obinrin meji.
BBC News Yorùbá bá Taiwo àti Kehinde Oguntoye tí wọn fẹ́ ìbejì níyàwó sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí wọn ṣe fẹ́ ìbejì àti bí wọn ṣe mọra pẹ̀lú àwọn ìrìrí wọn tẹ́lẹ̀ láti fẹ́ ìbejì.

"A ni awọn ibeji obinrin tẹlẹ ti a n fẹ, amọ iwa wa ko papọ tabi ki ẹjẹ wa ma papọ, ni ko jẹ ki awọn fẹra"
Nigba ti wọn n ba BBC sọrọ, Taiwo ati Kehinde Oguntoye ni o ti wa ninu ipinnu awọn lati fẹ ibeji bii aya lati ibẹrẹ aye awọn, ti Ọlọrun si fi amin si.
"Awọn nnkan ta n se nii se pẹlu awọn ibeji, kii si se pe a ko ni awọn ibeji lọwọ amọ Ọlọrun lo ni pe ki eyi ri bẹẹ.
Ẹka imọ nipa eto ọgbin ni awa wa nile ẹkọ fasiti nigba ti awọn iyawo wa wa ni ẹka eto ẹkọ eyi ti ko jinna sira wọn.
A ti dijọ wa fun ọdun mẹwaa, nigba to ya kaluku wa rin ni ọna tiẹ, awọn ba ẹkọ lọ soke okun, ti awa naa si n lọ soke okun kaakiri.
Nigba to ya, a tun pada, ti a si di tọkọ taya."
Awọn ibeji Oguntoye wa yan pe awọn ni awọn ibeji obinrin tẹlẹ ti awọn n fẹ, amọ o le jẹ pe iwa awọn ko papọ tabi ki ẹjẹ awọn ma papọ, ni ko jẹ ki awọn fẹra.
Amọ eyi ti Ọlọrun kọ ree.

Oríṣun àwòrán, Taiwo and Kehinde Oguntoye
"Kehinde mọ ti Kehinde, Taiwo naa si mọ ti Taiwo, a mọ bi a se n da awọn iyawo wa mọ, wọn ko le dapọ rara"
Bakan naa ni awọn ibeji Oguntoye fikun ọrọ wọn pe awọn iyawo awọn jọra pupọ, ti awọn wọn gan si maa n si wọn mu nigba miran.
"Kehinde mọ ti Kehinde, Taiwo naa si mọ ti Taiwo, a mọ bi a se n da awọn iyawo wa mọ, wọn ko le dapọ rara.
Ọmọ majẹmu ni awa ibeji naa, bi Ọlọrun se kọ, lo mu ki irinajo wa papọ.
Ko si ẹni to la le wa lọwọ pe ibeji la gbọdọ fẹ tabi pe ilu kan ni ki wọn ti wa.
Igba ti Ọlọrun maa se, ọmọbibi ilu Ibadan, nijọba ibilẹ Lagelu, ni awa atawọn iyawo wa naa.
A nifẹ asa gan, awa meji nikan la n lọ tẹlẹ amọ ibi ti a ba lọ bayii, a ti di mẹrin, awọn ibeji Adediran ti darapọ mọ wa.
Nnkan ayọ ati itẹsiwaju ni yoo jẹ, ti yoo si silẹkun ibukun, owo,ti yoo si tun ni alubarika.
Awọn iyawo wa naa n lọ kaakiri, wọn ko duro si oju kan, wọn si nifẹ si nnkan ti awọn ọkọ wọn n se, awọn naa yoo si jẹ alakoso sawọn nnkan ti a n se."

Ta ni awọn Taiwo ati Kehinde Oguntoye?
Taiwo ati Kehinde Oguntoye ni oludasilẹ ileeṣẹ Twins World Creations International Limited, ileeṣẹ ti wọn da silẹ nibii ọdun mẹwaa sẹyin lati mu igbega ba ipa awọn ibeji kaakiri agbaye.
Ileeṣẹ yii lo bi ayẹye ọdun ibeji ti wọn maa n ṣe ni ilu Igbo Ora, ilu ti igbagbọ wa pe ibe ni ibeji pọ si julọ kaakiri agbaye.
Ni ilẹ ẹkọ giga fasiti Ibadan, University of Ibadan ni Taiwo ati Kehinde ti kẹkọọ gboye ninu imọ amojuto ẹranko, ayika ati inaju.
Bakan naa ni wọn kẹkọọ gboye Diploma ninu imọ irinna ati inaju "Travel & Tourism" ni ile ẹkọ Institute of Business Technology Management of Nigeria.
Ni ọdun 2014 ni The African Sun Times ni Amẹrika fun awọn Taiwo ati Kehinde Oguntoye ni ami ẹyẹ awọn ibeji to gbajumọ julọ lẹka eto inaju Africa.
Awọn naa ni ibeji to kọkọ maa ṣoju ẹkun Africa nibi ayẹyẹ ọdun ibeji, Mojiang International Twins festival, China lọdun 2016.
Ọpọlọpọ awọn ami ẹyẹ mii bẹẹ naa ni wọn ti gba ni orilẹ ede Amẹrika ati ilẹ Africa.




























