Ìrírí mi nígbà àkọ́kọ́ tí wọ́n gbé mi lọ sí Ilorin jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn tó wá fi tipá gbé mi lè pa mí – Tani Olohun

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ifatimileyin Adeagbo ti ọpọ eeyan mọ si Tani Ọlọhun ninu ifọrọwerọ pẹlu akoroyin BBC News yoruba nilu Ibadan ni iyalẹnu lọ jẹ fun oun nigba ti awọn kan sai dede jawọ inu ile oun ti wọn si fi ilẹkẹ ọọrun faa oun jade pẹlu tipatipa bi ẹran.

‎Tani Ọlọhun ni bi aago meje aabo aarọ ọjọ Isẹgun ni awọn eeyan naa yabo ile oun to wa ni agbegbe Olomi Ọleyo nilu Ibadan.

‎Oni wọn ko mu Kaadi idanimọ kankan to fi wọn han gẹgẹ ọlọpa lọwọ tabi iwe ile ẹjọ to fọwọsi ki wọn gbe oun wa han ko to di wi pe wọn fẹ fi tipa tipa kii oun mọlẹ wọ inu ọkọ ayọkẹlẹ ti ko ni nọmba gbe lọ

Ẹ gbami, e ma jẹ ki wọn pa mi - Tani Olohun

Tani ọlọhun ni ọgbọn alumokọrọyi ní awọn oṣiṣẹ ile iṣẹ ọlọpa ti ilu Ilorin ti fi ṣaaju gbe oun ju si atimole tẹlẹri.

‎Eyi lọ faa ti oun fi yari lati tẹlẹ awọn to yabo ile oun lọ,oni wọn sẹlẹri lati pa oun tẹlẹri.

‎O kepe awọn ajafeto-omoniyan awọn ololufẹ rẹ lati gba oun lọwọ pampẹ iku ti wọn dẹẹ silẹ fun.

‎Tani Ọlọhun ni ti wọn ba gbe igbẹjọ wa si ile ẹjọ ni ipinlẹ Oyo oun ṣetan lati sọ tẹnu oun, oni agbẹjọro oun yoo yọju nile ẹjọ nilu Ilorin lati bẹ adajọ ki wọn ṣe igbẹjọ oun nilu Ibadan nibiti oun ngbe ti wọn si ni oun ti ṣẹ.