Bí àjọ INEC kò ṣe yọjú síbi ìpàdé àpapọ̀ ADC, àwọn àṣaájú ẹgbẹ́ sọ̀kò ọ̀rọ̀ sí Tinubu, lé adarí igun alátakò méjì

Oríṣun àwòrán, African Democratic Congress HQ
Ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC) ti pari ipade gbogbogbo wọn niluu Abuja, nibi ti awọn ọmọ ẹgbẹ ti fẹnuko lati ṣatunṣe si ofin ẹgbẹ naa.
Lẹyin eto idibo wọn to waye nibi ipade naa ni alaga to n ri si eto idibo ọhun to tun ti fi akoko igba kan ri jẹ gomina ipinlẹ Imo, Emeka Ihedioha, ti kede esi ibo.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ninu awọn eeyan 1,576 to forukọsilẹ, ibo mẹsa an ni wọn danu nigba ti eeyan 1,471 to jẹ ida 94% wọn fọwọ si ki wọn ṣatunṣe si ofin ẹgbẹ wọn.
Chinedu Idigo to jẹ akowe gbogbogbo fun ẹgbẹ naa kede pe lara nnkan ti wọn fẹnuko le lori ni lati yọ awọn amuyẹ kan ti araalu nilo ki wọn to le di ọmọ ẹgbẹ, wiwọgile ofin ẹlẹkunjẹkun fun awọn to ba n dije fun ipo adari ninu ẹgbẹ.
Wọn tun fẹnuko lati wọgile ofin to sọ pe ti eeyan kan ba fi ipo silẹ, ẹlomiran ti yoo ba gba ipo naa gbọdọ wa lati ẹkun ti ẹni to kuro nibẹ ti wa.
Nibi ipade ọhun ni wọn tun ti tu igbimọ ti Oloye Ralph Nwosun n dari rẹ ka nigba ti igbimọ ti David Mark n dari yoo bẹrẹ si n dari eto ẹgbẹ naa bayii.
Gbogbo atunṣe ti wọn fẹnuko le lori yii ni awọn ọmọ ẹgbẹ fi ontẹ lu ki wọn to pari ipade ọhun.
Nigba to n sọrọ, alaga ẹgbẹ naa, David Mark sọ pe oniruru ipade loun ti lọ gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP amọ ko tii si ipade ti wọn ṣe daadaa bii ti ẹgbẹ ADC.
O ni bi wọn ṣe ṣepade naa daadaa n fi han pe ẹgbẹ ọhun ti ṣetan lati bori ibo Aarẹ ọdun 2027.
Awọn ti wọn le kuro ninu ẹgbẹ
Nibi ipade naa ni wọn ti fi ọwọ osu juwe ile fun alaga igun kan ninu ẹgbẹ naa tẹlẹ, Nafiu Bala ati Leke Abejide to n ṣoju ẹkun Yagba nile igbimọ aṣojuṣofin lati ipinlẹ Kogi.
ADC tun le awọn mii kuro ninu ẹgbẹ, lara wọn ni Kingsley Temitope, Noman Obinna, Kennedy Odion, Stella Chukwuma, atawọn mẹrin mii.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ, eredi lile wọn kuro ninu ẹgbẹ ko ṣẹyin bi wọn ṣe n ṣe awọn nnkan to le di ilọsiwaju ẹgbẹ lọwọ.
Sẹnetọ Binos Yaroe lati ipinlẹ Adamawa lo daba ki wọn fi ọwọ osi juwe ile fun awọn eeyan naa ti gbogbo ẹgbẹ si fọwọ si pe ko ri bẹẹ.
Aregbesola bu ẹnu atẹ lu ijọba "Renewed Hope" Tinubu
Ẹwẹ, Rauf Aregbesola to ti fi akoko igba kan jẹ ọmọ oṣelu APC ti sọ pe jibiti lasan ni ileri ireti ọtun "Renewed Hope" ti Aarẹ Bola Tinubu ṣe fu awọn ọmọ Naijiria.
O ke si Tinubu pe ko kọwe fi ipo silẹ latari eto abo to mẹhẹ ni Naijiria.
Aregbesola lo sọ ọrọ naa nibi ipade gbogbogbo ADC to waye niluu Abuja.
O ni ọdun mẹrin sẹyin ni ijọba Tinubu ṣeleri ireti ọtun fun awọn ọmọ Naijiria, ọdun mẹta sinu ijọba rẹ, ileri kan naa lo si n ṣe faraalu bo tilẹ jẹ pe araalu ko ri ireti ọtun kankan gba.
Aregbe ni "Nigba wo gan ni ireti yii yoo wa si imuṣẹ?
"Esi ibere yii ko le rara, jibiti lasan ni. Ti a ba fun wọn laaye, ijọba yii yoo tẹsiwaju lati maa ta ireti ọtun faraalu titi ayeraye."
Wayi, agbẹnusọ Tinubu, Bayo Onanuga ti da pada fun Aregbesola lori ọrọ naa to fi tabuku ijọba ọga rẹ.
Onanuga juwe Aregbesola gẹgẹ bii ẹni to kuna ninu ojuṣe si ọmọ Naijiria lasiko to wa nipo oṣelu.
Gẹgẹ bo ṣe sọ loju opo X rẹ, Onanuga ni o yẹ ki Aregbesola yẹ ara rẹ wo nigba to wa nipo gomina ati minisita abẹle nitori inira nikan ni araalu mọ lasiko rẹ lori alefa.
"Bí kò ṣe sẹ́ni tó lè fọwọ́ bo ògo òòrùn ni wọ́n kò lè dí ADC lọna"- Aregbesola fèsì bí kóòtù ṣe sún ìgbẹ́jọ́ síwájú

Oríṣun àwòrán, ADC/ X
Rauf Aregbesola, Akọwe apapọ fun ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), ti sọ pe ko sohun to le yi ẹgbẹ naa kuro loju ọna to n n tọ, bẹẹ ni kinni kan ko le ṣẹlẹ ti yoo wa fi rẹ ADC laye.
"Bi ko ṣe sẹni to le fọwọ bo ogo oorun lati ma tan, bẹẹ naa ni wọn ko le di ADC lọna".
Aregbesola sọ eyi nibi ipade apapọ ẹgbẹ naa ti wọn n ṣe lai wo ti gbogbo ipenija to n koju wọn lọwọlọwọ.
O fi kun un pe ofin orilẹ ede Naijiria lawọn n tẹle, awọn ko si le gba kawọn eeyan ti ko kunju oṣuwọn maa gbilẹ ni Naijiria.
"Ijọba naa ṣeleri ireti ogo lọdun mẹrin sẹyin, ọdun mẹta ti pe, ileri kan naa ṣaa ni. Awọn ọmọ Naijiria yẹ ki wọn ri esi, ojuṣe tiwa si ni lati ri i pe akoyawọ waye."
Bẹẹ ni Aregbesola wi bi ipade apapọ naa ṣe n gberasọ.
Awon agbaagba ẹgbẹ naa bii David Mark, Dino Melaye ati Rotimi Amaechi wa ni nibi ipade naa, titi kan Rabiu Kwakwanso ati Peter Obi pẹlu awon alẹnulọrọ gbogbo.

Oríṣun àwòrán, ADC/ X
Ile ẹjọ sun igbẹjọ ADC si ọjọ kejilelogun oṣu Kẹrin 2026.
Ẹwẹ, igbẹjọ awọn olori ADC to yẹ ko waye lonii ni wọn ti sun siwaju nile ẹjọ to ga julọ lorilẹed.
Ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹrin ọdun 2026 ni kootu sun un si.
Ẹjọ naa ti igun David Mark pe ni igbimọ idajọ ẹlẹni marun un ti Adajọ Mohammed Garba lewaju sun siwaju.
Adajọ Garba lo fi aaye gba igbẹjọ naa lati ma ṣe pẹ ju ọsẹ kan lọ, sun un si Ọjọruu to n bọ.

Oríṣun àwòrán, ADC/X
Wo kókó ìpàdé àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú ADC, tó bẹ̀rẹ̀ lónìí láàrin ọ̀pọ̀ awuyewuye

Oríṣun àwòrán, ADC
Ẹgbẹ́ òṣèlú African Democratic Congress, ADC ní gbogbo ètò ló ti wà ní sẹpẹ́ láti ṣe àpérò ẹgbẹ́ náà níbi tí wọ́n ti máa yan àwọn aláṣẹ tuntun fún ẹgbẹ́ náà.
Ní ìlú Abuja tó jẹ́ olú ìlú Nàìjíríà ni àpérò náà yóò ti wáyé ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun, ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹrin, ọdún 2026 ní gbọ̀ngán Rainbow Event Center.
Lópin ọ̀sẹ̀ ni igun tí David Mark ń darí rẹ̀ lẹ́gbẹ́ òṣèlú ADC ọ̀hún ṣe àpérò láti yan àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ ní ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan, tí wọ́n sì ní àpérò àpapọ̀ yóò wáyé lónìí.
Ẹgbẹ́ òṣèlú ADC ní onírúurú ìpèníjà ni àwọn kojú láti rí ibi tí àpérò náà ti máa wáyé nítorí ìjọba kọ̀ láti fún àwọn láàyè láti lo Eagles Square, Abuja.
A máa ṣe àpérò wa, kódà, bó jẹ́ orí títì láti máa ṣé
Ọ̀kan lára àwọn agbẹnusọ ẹgbẹ́ òṣèlú náà, Faisal Kabir sọ fún BBC pé àwọn kọ̀wé ránṣẹ́ sí ìjọba láti jẹ́ kí àwọn lo gbọ̀ngán náà ṣùgbọ́n wọn kò fún àwọn láàyè.
Bákan náà ni wọ́n ní àwọn tún fẹ́ lo pápá ìṣeré Abuja tí wọn kò sì tún fún àwọn ní gbọ̀ngán náà.
Ó ní gbogbo àwọn aládàni tí àwọn kàn sí láti fún wọn ní gbọ̀ngán fún àpérò náà ni ìjọba ń dúnkokò mọ́ wọn pé wọn kò gbọdọ̀ gba àwọn láàyè.
Kabir sọ pé bí àwọn ṣe kojú ìpèníjà nígbà tí àwọn fẹ́ ṣe ìfilọ́lẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú náà kí àwọn tó rí gbọ̀ngán Shehu Musa Yar'adua nígbà náà.
Ó sọ pé pẹ̀lú gbogbo ìpèníjà tí àwọn ń kojú náà kò ní dí àwọn lọ́wọ́ láti ṣe àpérò náà nítorí kódà kó jẹ́ pé orí títì ni àwọn bá ti máa ṣé.
A kò dènà ADC láti lo gbọ̀ngán Eagles Square, wọn ò kọ̀wé pé àwọn fẹ́ lo gbọ̀ngán náà - Wike
Àmọ́ Mínísítà fún olú ìlú Abuja, Nyesom Wike ti jiyàn ẹ̀sun tí ẹgbẹ́ náà fi kan ìjọba pé wọn kò pèsè gbọ̀ngán Eagles Square fún wọn láti lò.
Wike ní ẹgbẹ́ náà kò kọ̀wé ránṣẹ́ sí ìjọba láti bèèrè fún gbọ̀ngán, tó sì pè wọ́n níjà pé kí wọ́n fi ìwé tí wọ́n fi bèèrè fún gbọ̀ngán náà léde tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ ni wọ́n bèèrè fún-un.
Wike ní kò sí ìgbà kankan tí àwọn dí ẹgbẹ́ òṣèlú kankan láàyè láti lo gbọ̀ngán Eagles Square fún ohunkóhun níwọ̀n ìgbà tí wọ́n bá ti kọ̀wé ránṣẹ́ pé àwọn nílò rẹ̀.
Ó fi kun pé kò sí ìdádúró kankan tó wáyé fún ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP nígbà tí wọ́n fẹ́ lo gbọ̀ngán náà lóṣù tó kọjá níwọ̀n ìgbà tí wọ́n ṣe ohun tó yẹ, tí wọ́n sì san gbogbo owó tó tọ́.
Kí ni kókó àpérò náà dá lé lórí?
Gẹ́gẹ́ bí àpérò ẹgbẹ́ òṣèlú yòókù, níbi àpérò yìí ni wọ́n ti máa yan àwọn adarí tí yóò máa ṣe àkóso ẹgbẹ́ náà níbi ètò ìdìbò gbogbogbò ọdún 2027.
Ní ọdún tó kọjá ni ẹgbẹ́ náà yan àwọn adarí láti máa ṣàmójútó ẹgbẹ́ náà fún ìgbà kan ná lábẹ́ ìdarí David Mark.
Ibi àpérò yìí ni wọ́n ti máa wá yan adarí yálà nípasẹ̀ fífún àwọn tó wà níbẹ̀ láti máa báṣẹ́ wọn lọ tàbí kí wọ́n yan àwọn mìíràn.
Ní ọjọ́ Kejìlá, oṣù Karùn-ún, ọdún 2026 ni ẹgbẹ́ náà ní àwọn máa ṣe ìbúrawọlé fún gbogbo àwọn adarí tí wọ́n dìbò yàn káàkiri gogbo ìpínlẹ̀ tó wà ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.
Ìgbẹ́jọ́ ADC ń wáyé nílé ẹjọ́ lónìí
Àpérò ẹgbẹ́ òṣèlú ADC ló ń wáyé ní ọjọ́ kan náà tí ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà ń gbọ́ ẹjọ́ lórí làásìgbò tó ń wáyé lórí àwọn adarí ẹgbẹ́ òṣèlú náà.
Igun David Mark ló gbé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn lọ sílé ẹjọ́ tó ga jùlọ níbi tí wọ́n ti ń bèèrè pé kí ilé ẹjọ́ náà da ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn gbé kalẹ̀ lọ́jọ́ Kejìlá, oṣù Kẹta ọdún 2023.
Ṣáájú ni igbákejì alága ẹgbẹ́ òṣèlú náà tẹ́lẹ̀ rí, Nafiu Bala Gombe ti pe David Mark lẹ́jọ́ ní ilé ẹjọ́ gíga pé wọ́n gba àṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú ADC mọ́ àwọn kan lọ́wọ́.
Àmọ́ David Mark lọ sí ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn pé kí wọ́n má fi ààyè gba ilé ẹjọ́ gíga láti gbọ́ éjọ́ tí Gombe pè ní ilé ẹjọ́ gíga, pé ilé ẹjọ́ náà kò ní àṣẹ láti gbọ́ ẹjọ́ náà.
Ẹ̀wẹ̀, ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn da ẹjọ́ náà nù, tí wọ́n sì ní kí ilé ẹjọ́ gíga gbọ́ ẹjọ́ náà.
Lẹ́yìn ìdájọ́ náà ni àjọ tó ń mójútó ètò ìdìbò ní Nàìjíríà, INEC yọ orúkọ David Mark àtàwọn míì kúrò lójú òpó wọn gẹ́gẹ́ bí adarí ADC.
INEC tún ṣèkìlọ̀ fún ADC láti má tẹ̀síwájú pẹ̀lú àpérò tí wọ́n fẹ́ ṣe náà títí ilé ẹjọ́ fi máa dájọ́ wọn.


























