Kí ló fá ikú ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń jí epo rọ̀bì fà ní Okrika, ìpínlẹ̀ Rivers? Ohun tí a mọ̀

Oríṣun àwòrán, The Youths and Environmental Advocacy Centre (YEAC-Nigeria)
Awọn eeyan ti ko din ni mẹwaa ni wọn ti gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra nibi ti awọn afurasi ole ti n gbiyanju lati ji epo wa niluu Okrika, ipinlẹ Rivers.
Oorun buruku kan ti wọn lo n jade lati inu epo rọbii ni wọn lawọn eeyan naa fa si imu, to si gba ẹmi gbogbo wọn, ti awọn miran tun farapa.
Nnkan bi agogo mejila ori, Ọjọbọ, ọsẹ yii, ọjọ kẹta, oṣu Kẹsan, ọdun 2026 ni iṣẹlẹ naa waye ni adugbo Okari Jetty, iyẹn lagbegbe Okrika Mainland.
Ohun ti a gbọ ni pe awọn araalu ti ko din ọgọrun kan ti wọn n gbe niluu Okrika ati agbegbe rẹ ni wọn ya lọ si agbegbe Okari Jetty naa lati ji epo rọbii wa lọna aitọ.
Nibẹ la gbọ pe wọn tun ti gbe ọkọ oju omi nla kan ti wọn fi n gbe epo rọbii lọ awọn orileede kaakiri, eyi ti wọn fẹẹ fi epo naa gbe kuro ni Naijiria lọ sibẹ.
Lara awọn ara gbegbe ti iṣẹlẹ naa ti waye sọ fawọn akọroyin pe ojiji ni oorun buruku kan bẹrẹ sii run jade lati inu afẹfẹ lasiko ti awọn eeyan yii n ṣiṣẹ ibi lọwọ.
O ni bi oorun naa ṣe gbilẹ, lo ba afẹfẹ alaafia jẹ, to si ṣe ipalara fun gbogbo awọn to wa nibẹ lasiko naa.
Pupọ ninu awọn ti wọn lọ ṣiṣẹ ibi yii ni wọn jẹ ọdọ to n gbe lagbegbe Okrika ati ilu to sunmọ ọn.
Ẹni to ba awọn akọroyin sọrọ ti ko fẹẹ darukọ ara rẹ, sọ pe, "Pupọ ninu wọn ṣubu sinu odo lasiko naa, nigba ti awọn yooku gbiyanju lati sa asala fun ẹmi ara wọn.
"Awọn yooku w anile iwosan ti wọn ti n gba itọju, nigba ti awọn ẹya ara wọn ti bẹrẹ sii ṣiṣẹkiṣẹ lati inu," ẹni naa ṣalaye.
Siwaju sii lo fidi rẹ mulẹ pe awọn mẹtadinlogoji ti wọn da mọ ninu wọn lo jẹ pe ọmọ ilu Okrika nibẹ ni wọn jẹ, ati pe wọn ko da awọn mẹfa ti wọn tun ri mọ, ati pe ọpọ awọn eeyan ni wọn ṣi n wa titi di asiko yii.
Agbẹnusọ ọlọ́pàá ìpílẹ̀ Rivers sọ̀rọ̀
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Rivers, Blessing Kaborlo Agabe jẹ ko di mimọ pe awọn ti bẹrẹ ẹkunrẹrẹ iwadii nipa iṣẹlẹ naa.
Agabe sọ pe awọn afurasi naa ni wọn ku lasiko ti wọn n gbiyanju lati ji epo rọbii ilẹ Naijiria wa lọna aitọ.
"Awọn afurasi yii ku lasiko ti wọn n gbiyanju lati ja ilẹ Naijiria lole, nipa jiji epo rọbii wa," Agabe sọ bẹẹ.
Bakan naa lo sọ pe ko tii sẹni to wa fi iṣẹlẹ naa to ileeṣẹ ọlọpaa leti bo ti tọ, bo tilẹ jẹ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati mọ iye awọn to ku.
Ajọ YEAC sọ̀rọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún
Ajọ kan ti wọn pe ara wọn ni Youths and Environmental Advocacy Centre (YEAC-Nigeria) to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sọ pe afẹfẹ buruku to jade lati inu ohun to pe ni "Indorama Fuel" lo ṣakoba fun wọn.
Gẹgẹ bi wọn ṣe sọ ninu atẹjade ti alakoso agba, Ọmọwe Fyneface Dumnamene buwọlu, wọn ni ẹka to n ja fun ẹtọ ọmọniyan lagbegeb Niger Delta sọ pe awọn ti ko din ni mẹtadinlogoji ni wọn ti ku.
Dumnamene sọ pe oorun buruku kan to pe ni 'Indorama Fuel' ni wọn fa simu, ti wọn si ku loju ẹsẹ.
Alakoso agba naa sọ pe asiko ti wọn n ji epo rọbii wa lati inu ọpa epo to gbe epo wa lati ileeṣẹ Indorama Eleme Petrochemical Company, eyi to gba ile ifọpo Port Harcourt kọja ni wọn ti ṣagbako naa.
O ni awọn eeyan naa ti da ọpa epo to n gbe epo sinu ọkọ oju omi ti wọn fi n gbe epo rọbii lu lẹgbẹ kan, pẹlu erongba lati jii gbe, ni ọrọ yiwọ mọ wọn lọwọ.
O sọ pe oorun buruku to jade ni gbogbo wọn fa simu lai mọ, to si fa iku awọn eeyan naa, ti awọn miran si farapa, bo tilẹ jẹ pe awọn miran moribọ.
Nigba to n bu ẹnu atẹ lu iwan aa, Dumnamene ṣe ikilọ nla fun gbogbo awọn to n ji epo rọbii wa tọwọ ọmọ wọ bọ aṣọ, nitori ewu to wa nidi rẹ.
Bakan naa lo rọ ijọba apapọ lati dide iranlọwọ fun awọn araalu ti ajalu ti le kuro nibi ti wọn n gbe tẹlẹ, lọ sibomiran ni agbegbe yii.
O ni ki ijọba pese anfaani ọna abayọ ti awọn eeyan naa yoo fi maa ṣe okoowo ti wọn yoo maa fi ri ọna abayọ si jiẹ ati mimu ni irọrun.
Ọlọ́pàá àti NSCDC sọ̀rọ̀
Nigba to n ba BBC sọrọ, agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, Blessing Agabe sọ pe otitọ ni, ati pe awọn eeyan naa ku lasiko ti wọn n gbiyanju lati ji epo rọbii wa lọna aitọ.
"Awọn afurasi naa ku lasiko ti wọn n gbiyanju lati ji epo rọbii wa," Agabe sọ bẹẹ.
O fi kun ọrọ rẹ pe "Iwadii ti n lọ lati ri aridaju iye awọn to ba iṣẹlẹ naa lọ."
Bakan naa ni ileeṣẹ aabo ẹni laabo ilu ti a mọ si Sifu Difẹnsi, NSCDC naa sọ awọn ti n ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn ileeṣẹ eleto aabo miran lati fi okodoro nipa ohun to ṣẹlẹ mulẹ.
NDSCD rọ awọn ileeṣẹ iroyin kaakiri lati dẹkun gbigbe ayederu iroyin sita, ati pe ki wọn maa wadii okodoro lọwọ awọn ileeṣẹ tọrọ kan, ko to di pe wọn gbe iroyin wọn sita.
Wọn sọ siwaju pe awọn iwa jiji epo rọbii wa maa n ko ẹmi awọn eeyan sinu ewu nla bi nnkan to ṣẹlẹ naa ni, ati pe ki awọn eeyan dẹkun iwa abuku bẹẹ.
Ìgbésẹ̀ ìjọba Nàíjíríà
Lati bi ọdun meloo kan sẹyin ni ijọba ilẹ Naijiria ti dide lati gbogun ti bi awọn amookunṣeka ṣe lọ n fọ ọpa epo lati maa ji epo wa kaakiri Naijiria, paapaa lẹkun Niger Delta.
Ileeṣẹ ologun ti Navy ti dide lati ṣe afikun si awọn ọmọ ogun wọn lati daabo bo gbogbo awọn agbegbe ti ọpa epo gba kọja.
Bakan naa ni awọn ologun ati ileeṣẹ eleto aabo yooku naa ko duro lati maa gbogun ti awọn to n ji epo rọbii wa, nipa fifọ ọpa epo.
Bẹẹ ni awọn alakoso tun n ṣe igbiyanju lati ṣe afikun si epo to n jade lẹyin ọpọlọpọ ọdun ti wọn ti n koju iṣoro lati ọdọ awọn to n ji epo wa, ati aisi eto aabo to pe ye.
Ilẹ Naijiria n foju sọna lati maa pese epo to to miliọnu mẹta lojumọ nigba ti yoo ba fi di ọdun 2030, pẹlu aofjusun si eto aabo to dantọ lati daabo bo epo.



























