Ariwo ẹkún sọ lásìkò tí Ogogo ń wọ káà ilẹ̀ sùn

Ariwo ẹkún sọ lásìkò tí Ogogo ń wọ káà ilẹ̀ sùn

Awọn oṣere nibieto isinku Ogogo

Ariwo ẹkun sọ laarọ ọjọ Aje niluu Ilaro, nipinlẹ Ogun lasiko ti wọn n sin oku Taiwo Hassan Ogogo to jade laye lọjọ Aiku.

Ọpọ mọlẹbi, ọrẹ, araalu, ati ogunlọgọ oṣere tiata lo peju sibi eto isinku naa ti BBC Yoruba si wa nibẹ pẹlu.

Akọroyin wa to a nibẹ ṣafihan bi awọn abanikẹdun ṣe gbe oku Ogogo lọ si iboji rẹ ki wọn to sin in ni ilana ẹsin Musulumi.

Lara awọn korikosun Ogogo to fi omije ṣe odigboṣe si oṣere naa ni Yinka Quadri ti awọn eeyan n parọwa si bo ṣe wa ẹkun mu nibẹ.

Awọn akẹgbẹ Ogogo mii ti wọn tun wa nibẹ ni Jide Kosoko, Faithia Balogun, Femi Adebayo, Mr Latin, Madam Saje, Toyosi Adesanya, atawọn oṣere mii.

Nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ lórúkọ àwọn ẹgbẹ́ òní tiata t níbi eto ìsìnkú náà, Alagba Dele Odule sọ pé iku tí mú ipinya ba ibadọrẹ Yinka Qudri, Ogogo àti Dele Odule.

Dele Odule ni ẹgbẹ́ osere lorile-ede Nàìjíríà lapapó yóò ṣaferi Ologbe Taiwo Hassan Ogogo ẹni tí ó jáde láyé leni ọdún 66 lẹ́yìn àìsàn kansa tí ó ti ń bá fínra.

Wọ́n gbé òkú Ogogo dé gbàgede Pavilion nílùú Ilaro, Àwọn èèkàn òṣèré tíátà tú síbẹ́

Aworan Ogogo wa lapa osi, aworan oku rẹ ninu posi wa laarin ti tawọn oṣere to wa sibi isinku rẹ si wa lapa ọtun.

Oríṣun àwòrán, Taiwo Hassan Ogogo/BBC

Ọpọlọpọ awọn elere tiata ni wọn pesẹ silu Ilar oni ipinlẹ Ogun lati ṣe ẹyẹ ikẹyin fun oloogbe Taiwo Hassan Ogogo.

Lasiko ti eto isinku ati lati kirun sii lara bẹrẹ ni awọn agba oṣere loniraanran ti n sọ ọrọ inu wọn lori igbesi aye rẹ.

Ninu ọrọ rẹ, Eekan Oṣere Dele Odule ni gbolohun kan lo le ṣe akojọpọ igbe aye oloogbe Ogogo at iwi pe gbolohun naa ni pe "eeyan daadaa ni Taiwo Babtunde Hassan Ogogo".

Pẹlu Omije ni awọn eekan miran bii Fausat Balogun 'Madam Sajẹ' ati awọn miran fi sọrọ ti wọn si yombo igbesi aye rẹ.

Ètò ìsìnkú ti bẹ̀rẹ̀ fún Taiwo Hassan 'Ogogo'
Oloogbe Taiwo Hassan (Ogogo) lapa osi, awọn to gbe oku rẹ lapa ọtun.

Oríṣun àwòrán, Jide Kosoko/ Facebook/ BBC

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 7

Eto isinku agba oṣere tiata, Taiwo Hassan ti ọpọ mọ si Ogogo ti gbera sọ.

Awọn Afaa ẹsin Islam to ṣiwaju eto isinku naa ni ile oloogbe naa ni ilu Ilaro tọkasi awọn ipa rere ti oloogbe naa ko ninu idagbasoke ẹsin Islam ti wọn yoo si mọ riri aisimọ rẹ lẹyin ipapoda rẹ.

Wọn ni "ọkan lara awọn oṣere ti ko sọ ẹsin nu ninu iṣẹ tiata to ṣe" ni Ogogo.

Awọn oṣere bii Fẹmi Adebayọ, Alapinni ati bẹẹ bẹẹ lọ ni wọn ti wa nibi eto naa.

Lẹyin ti wọn sọrọ tan ni wọn gbe oku rẹ jade ni ile rẹ lati lọ kirun sii lara ni agbegbe Pavilion

Wo bí ètò ìsìnkú Ogogo yóò ṣe lọ láàárọ̀ òní nílùú Ilaro

Oloogbe Taiwo Hassan (Ogogo)

Oríṣun àwòrán, Kira Taiwo Hassan/Facebook

Àkọlé àwòrán, Oloogbe Taiwo Hassan (Ogogo)

Oni ọjọ Aje, ọjọ kẹrinlelogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 ni wọn yoo sinku gbajumọ oṣere; Taiwo Hassan (Ogogo) si ilu abinibi rẹ ti i ṣe Ilaro, nipinlẹ Ogun.

Aago mẹta ọsan ọjọ Aiku ana, ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026 ni Ogogo jade laye lẹni ọdun mẹrindinlaadọrin (66), lẹyin aisan jẹjẹrẹ onipele kẹrin to ba a finra.

Atẹjade ti agba oṣere, Ọmọọba Jide Kosoko fi sita lori isinku naa ṣalaye pe ọjọ Aiku ti Ogogo jade laye naa ni wọn yoo gbe oku rẹ de Ilaro, nibi ti wọn yoo ti tẹ ẹ ni ẹtẹ ẹyẹ lonii ọjọ Aje, ṣaaju isinku rẹ ti yoo waye laago mọkanla aarọ.

Atẹjade ti Jide Kosoko fi kede iku ati isinku naa ka pe:

"Pẹlu ibanujẹ ọkan, a kede iku Alhaji Taiwo Hassan, ti gbogbo eeyan mọ si Ogogo, ẹni to jade laye laaago mẹta ọsan ọjọ Aiku, ọjọ kẹtalelogun oṣu Kẹjọ ọdun 2026, lẹni ọdun mẹrindinlaadọrin (66)."

Nipa ibi ti eto naa yoo ti waye, Asade Agunloye Pavillon, Ilaro nipinlẹ Ogun, ni wọn pe e.

Bakan naa ni awujọ awọn ẹlẹsin Islam n'Ilaro, kede eto isinku Ogogo, lati ẹnu Imaamu agba wọn.

Awujọ awọn ẹlẹsin Islam Ilaro naa bẹrẹ ikede ọhun pẹlu ọrọ Larubawa to sọ pe :

"Inna lillahi wa inna ilayhi raji'un" to tumọ si pe ọdọ Ọlọrun ni a ti wa, ọdọ rẹ naa si ni a o pada si.

Wọn kede pe awọn pe ẹbi, ọrẹ ati gbogbo eeyan lati wa, kawọn jọ bu ọla ikẹyin fun Ogogo, oṣere tiata to jade laye lojiji.

BBC News Yoruba yoo maa mu eto isinku naa wa fun yin bo ba ṣe n lọ.

Àgbà òṣèré tíátà, Taiwo Hasan Ogogo ti jáde láyé

Ogogo nigba aye rẹ

Oríṣun àwòrán, Taiwo Hassan

Gbajumọ oṣere tiata Yoruba, Taiwo Hassan, ti ọpọ mọ si Ogogo ti jade laye.

Ogogo lo jade laye lẹyin to ti kọkọ ba aisan jẹjẹrẹ firan.

Omọ rẹ obinrin, Kira Taiwo, lo fi ikede iku rẹ sita ni irọlẹ ọjọ Aiku lojun opo Instagram rẹ.

Lẹyin naa ni agba oṣere mii, Saheed Balogun tun ikede ọhun sita nibi to ti sọ pe "Inna lillahi wa inna ilayhi raji'un. O le sinmi bayii arakunrin mi, Taiwo Hassan Ogogo. Ki Ọlọrun tẹ ọ si afẹfẹ rere."

Ti ẹ ko ba gbagbe, aarọ ọjọ Isẹgun to kọja la ti mu iroyin wa fun yin pe awọn ọmọbinrin gbajumọ osere tiata naa, Shakira ati Haleemah Taiwo figbe bọnu lori ayelujara pe aisan jẹjẹrẹ n se baba awọn.

Lẹyin ikede naa ni wọn wa n beere fun iranlọwọ awọn ọmọ Naijiria ki baba wọn le gbadun, ti wọn si n ke sawọn oniṣegun oyinbo ati ti ibilẹ to ba le wo baba wọn san lati jade wa.

Awọn ere ti Ogogo ti kopa

Taiwo Hassan Ogogo wọ agbada ati fila

Oríṣun àwòrán, Taiwo Hassan Ogogo

Iwọn yii ni diẹ lara awọn ere manigbagbe ti Taiwo Hassan Ogogo ti kopa:

  • Atitebi (1994)
  • Agbelebu (1995)
  • Agbo-Odaju (1995)
  • Owo Blow parts 2,3 (1996) oun ni Wole Owolabi
  • Omin (2008) o se Adesina
  • Elewon (2009) o se Yomi
  • Omo Ghetto (2010) as D.P.O
  • Aye O (2016) o se Faniyi
  • Ọjọ ẹyẹ mi (My Joyous Day) (2016)
  • Tenant of the House (2019) o se Hon. Kasali
  • Amerah (2021) o se Alhaji
  • Aníkúlápó (2022) o se Alaafin Ademuyiwa
  • Bank Alert (2023) O se baba agba
  • IGE - the unlikely oil merchant (2023) oun lo se Olalere
  • Anikulapo: Rise of the Spectre (2024) o se Alaafin Ademuyiwa

Ta ni Taiwo Hassan Ogogo?

Ọjọ kọkanlelọgbọn osu kẹwa ọdun 1959 ni wọn bi Taiwo Hassan, ti ọpọ eeyan mọ si Ogogo.

Ọmọbibi ilu Ilaro, to wa ni agbegbe Yewa nipinlẹ Ogun nii se, to si jẹ ibeji, tori ibeji ni wọn saba maa n bi ninu idile rẹ.

Bakan naa ni baba ati iya rẹ naa jẹ ibeji.

Ogogo pari ile ẹkọ alakọbẹrẹ rẹ nile ẹkọ Christ Church nilu Ilaro, ko to morile ile ẹkọ girama Gazikia College nilu Eko.

Amọ Ogogo ko le pari ile ẹkọ girama naa tori ọda owo, lẹyin naa lo wa lọ sile ẹkọ ẹkọsẹ ọwọ nibi to ti kọ nipa isẹ atọkọse, ti a mọ si Mẹkaliki.

Gbajumọ osere tiata naa si sisẹ bii Mẹkaliki fun ọdun mẹtala gbako nileesẹ to n pese omi, water corporation.

Ogogo bẹrẹ isẹ tiata lọdun 1981 ni kete to bẹrẹ isẹ mẹkaliki, to si kuro lẹnu isẹ mẹkaliki nileesẹ Water Corporation lọdun 1994, ko le gbajumọ isẹ tiata to yan laayo.

Agba osere naa ti gba oniruuru ami ẹyẹ nidi isẹ tiata, to si tun gba ami ẹyẹ ipa to ko ninu ere Anikulapo, tii se Alaafin Oyo.