Ọdún Ìṣẹ̀ṣe bẹ̀rẹ̀, ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun, Eko ati Oyo kéde ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́

Gbogbo ogunjọ oṣu Kẹjọ ọdọọdun ni ayajọ ọdun Iṣẹṣe nilẹ Naijiria, paapaa lẹkun Iwọ-Oorun orileede naa.
Bo tilẹ jẹ pe awọn ijọba ipinlẹ kan ko tii buwọ lu ọjọ naa f'awọn oniṣẹṣe, ṣibẹ awọn oniṣẹṣe lawọn ipinlẹ ọhun ṣi n jade sita lati ṣajọyọ pẹlu ireti pe erongba wọn yoo wa si imuṣẹ lọjọ kan.
Lara awọn ipinlẹ to ti buwọ lu ayajọ naa fawọn oniṣẹṣe naa la ti ri ipinlẹ Ogun, Eko ati Oyo, ti awọn ijọba naa si tun n kede olude fun gbogbo oṣiṣẹ patapata.
Lati ọdun pipẹ ni awọn agbaagba nidi iṣẹṣe ti n rawọ ẹbẹ si awọn ijọba, paapaa ijọba Naijiria lati buwọ lu ọjọ kan fun wọn ti wọn yoo maa ṣayẹyẹ ọdun iṣẹṣe.
Awọn agbagba ati aṣoju aṣa naa ke gbajare yii, ti wọn si lawọn naa lẹtọọ lati ni ọjọ kan ti wọn yoo maa ṣayẹyẹ ọdun wọn lọdọọdun.
Bakan naa ni wọn jẹ ko di mimọ pe ẹsin iṣẹṣe ni ẹsin adayeba nilẹ Yoruba, ko to di pe awọn oyinbo alawọ funfun gbe awọn ẹsin bii Kristẹẹni ati Isilaamu wa.
Lẹyin eyi lawọn gomina bii Ademola Adeleke tipinlẹ Osun; Babajide Sanwo-Olu tipinlẹ Eko; Seyi Makinde tipinlẹ Oyo ati Dapo Abiodun tipinlẹ Ogun kede ọlude fun gbogbo awọn oniṣẹṣe, iyẹn lọdun 2023.
Awọn ijọba naa, gẹgẹ bi awọn oniṣẹṣe ṣe n beere fun ogunjo, oṣu Kẹjọ ọdọọdun buwọ lu ọjọ naa fun wọn.
Ṣugbọn lọdun yii, ijọba ipinlẹ Ogun, Eko ati Oyo ni wọn kede ọlude fun gbogbo oṣiṣẹ patapata lati ṣayẹyẹ ọdun awọn oniṣẹṣe.




























