Awuyewuye bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí àdó olóró pa ọmọ Nàíjíríà tó n kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó ní Ukraine

Oríṣun àwòrán, Frankfun/Facebook
Kayeefi nla ni ọrọ iku ọdọmọbinrin ẹni ọdun mẹtalelogun (23) to jẹ ọmọ orilẹede Naijiria ati akẹkọọ nipa imọ iṣegun oyinbo, Marian Nnani, ṣi n jẹ fun awọn eeyan titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin.
Bakan naa si ni ọpọ ọmọ Naijiria ti n fi aidunnu wọn han si iku ọdọmọde ọmọ Naijiria to ba ogun lọ ni Ukraine naa
Nnani la gbọ pe o ki aye pe o digboṣe lẹyin to fara kaaṣa ado oloro ti awọn ọmọ ogun orileede Russia ju si ilẹ Ukraine lasiko ikọlu.
Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe lasiko ti Marian n gbaradi fun eto ayẹyẹ ikẹkọọ-jade rẹ ni fasiti imọ iṣegun oyinbo to wa niluu Kharkiv, ni ajalu naa ṣẹlẹ, to si mu ẹmi rẹ lọ lọjọ Aiku to kọja yii.

Oríṣun àwòrán, FNA
Bawo ni iṣẹlẹ yii ṣe waye gan-an?
Ọjọ Aje, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹfa, ọdun 2026 ni ikọ ọmọ ogun Russia ju ado oloro si ilu Kharkiv to wa ni ẹkun Kholodnohirskyi, to si ba ọpọ dukia jẹ, ti awọn eeyan si tun farapa yannayanna.
Gẹgẹ bi ajọ awọn nọọsi nilẹ Afrika, iyẹn Fellow Nurses Africa ti wọn n ṣeto idanilẹkọọ ati iranwọ fawọn nọọsi kaakiri ṣe ṣalaye, wọn ni ọrẹ timọtimọ Mairan, ẹni ti wọn pe ni Fatima Huseynova, ẹni ọdun mẹtalelogun, ku loju ẹsẹ ni tiẹ nibi ikọlu ado oloro ọhun.
Ile iwosan kan to wa lorileede Germany ni iroyin fidi rẹ mulẹ pe Marian pada ku si, ati pe ṣaaju asiko naa ni wọn ti kọkọ tọju rẹ nile iwosan kan to wa niluu Kharkiv.
Awọn alakooso fasiti 'Kharkiv National Medical University', ni wọn kede iroyin iku Marian lọjọ Aiku to kọja, ti wọn si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bi akẹkọọ to jafafa, to si fi ara rẹ jin fun ohun to n ṣe.
Wọn ni latigba ti Marian ti darapọ mọ fasiti wọn lọdun 2020, lo ti ni itara fun imọ iṣegun oyinbo, to si ni oniruuru ẹbun, to fi n mu ara rẹ tẹsiwaju lẹka naa.
Atẹjade ti awọn alakoso naa fi sita fidi rẹ mulẹ, pe oloogbe naa ti kopa ninu awọn eto ẹkọ lagbaaye, lara eyi ti wọn pe ni idanilẹkọọ ni Fasiti Cambridge ti ọdun 2024 ati ti Fasiti Beruni to wa lorileede Turkey lọdun 2025, nibi ti wọn lo ti ni imọ kikun nipa iṣẹ iwadii eto ilera.
''Iku Marian jẹ iranti pe ikọlu Russia ṣi n tẹsiwaju''
"Iku rẹ jẹ iranni-leti miran wi pe ikọlu Russia ṣi n tẹsiwaju,wọn n ṣeku pa awọn araalu kaakiri agbaye ti wọn si wa si lorileede Ukraine lati kẹkọọ, ṣiṣẹ,ati fun itẹsiwaju ọjọ iwaju rere wọn," awọn alaṣẹ Ukraine lo sọ bẹẹ.
Wọn fi kun ọrọ rẹ wọn pe " Fasiti Kharkiv National Medical fi ọrọ ibanikẹdun ranṣẹ si mọlẹbi, ọrẹ ati akẹgbẹ Marian. "A ko le gbagbe ipa ati ilana rẹ ni fasiti wa titi lai."
Ju gbogbo rẹ lọ, iroyin iku Marian ti di awuyewuye ati ariyanjiyan kaakiri ori ayelujara nilẹ Naijiria.
Bi awọn kan ṣe n ba mọlẹbi Marian kẹdun iku rẹ, bẹẹ lawọn miran n da a lẹbi wi pe o yẹ ko ti fi orileede Ukraine silẹ latigba ti ogun to n lọ lọwọ ti bẹrẹ.



























