Bàálù tí Makinde rà kò lè nípa gidi lórí ètò ààbò l'Oyo, torí kìí ṣe irú bàálù t'awọn ẹ̀ṣọ́ elétò ààbò máa ń lò - Adeyi

Ọmọgun ofurufu to de fila duro kọju si Seyi Makinde to wọ ẹwu ati ṣokoto ti o si de fila

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde/X

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 5

Onimọ nipa ọrọ eto aabo kan, Akin Adeyi, ti sọ pe kii ṣe baalu meji ti Gomina Seyi Makinde ra nipinlẹ Oyo lo kan lori ọrọ eto aabo nipinlẹ naa.

Ọgbẹni Adeyi to ti ṣiṣẹ ri pẹlu ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS sọ fun BBC Yoruba wi pe awọn baalu ti Makinde fi owo ilu ra ko le ni ipa gidi lori eto aabo ipinlẹ Oyo tori kii ṣe iru baalu to le wulo fun igbogun ti awọn ọdaran.

Adeyi ni ko si nnkan ti awọn baalu ti ijọba ṣẹṣẹ ra yii fẹ ṣe ju ki o yaworan awọn ọdaran lati oju ofurufu lati mọ ibi ti wọn wa lọ.

O ni ẹrọ ''drone'' tawọn ẹṣọ eleto aabo maa n lo le ṣe awọn nnkan yii kaakiri ipinlẹ Oyo lai nilo baalu.

Onimọ nipa ọrọ eto aabo sọ pe ipinlẹ ko nilo iru baalu yii tori kii ṣe ipinlẹ ti omi ti pọ bii Bayelsa tabi ipinlẹ Rivers.

''O yẹ ki Makinde jokoo pẹlu awọn akọṣẹmọṣẹ lori eto aabo ki o le mọ iru baalu to ba fẹ ra.

Fun apẹẹrẹ, ipinlẹ Osun ra iru ẹlikopita yii, amọ, lẹyin o rẹyin, ẹlikopita tawọn agbaṣẹṣe maa n gbe lọ sibi ti wọn ti n ṣiṣẹ ni wọn pada lọ ra kii ṣe ẹlikopita tawọn ẹṣọ eleto aabo le lo.

Gilaasi lo maa n pọju lara irufẹ awọn baalu yii pẹlu oriṣiiriṣii nnkan elo lo maa n wa lara rẹ.

Nigba to ya ni wọn bẹrẹ sii fi ẹlikopita Osun naa Eko si Ghana, wọn o tiẹ pada ri mọ nigba to ya.

Ọgbọn ka fi ẹran sẹnu ka wa a ti ni gbogbo nnkan tawọn n ṣe yii.

Baalu ti wọn ra ni Oyo naa yoo pada di ''taxi'' bi ti ipinlẹ Oyo ti wọn fi n na Eko si Ghana naa ni.

O yẹ kawọn gomina wa maa ni idanilẹkọọ lori eto aabo ti wọn ba ti wọle ibo gomina tan.

Ko si ipa gidi kankan ti baalu yii le ni tori iru awọn baalu tawọn agbaṣẹṣe maa n gbe lọ sibi ti wọn ti n ṣiṣẹ ni wọn maa n gbe iru baalu yii lọ,'' Adeyi lo sọ bẹẹ.

Onimọ nipa eto aabo sọ pe ko ba dara ki Makinde ra awọn ẹrọ kamẹra tawọn ẹṣọ eleto aabo maa n lo lọ ju baalu to ra.

Lẹ́yìn ọ̀pọ̀ gbas-gbos, ìjọba Oyo tẹ́wọ́gba bàlúù méjì fún ètò àbò

Gomina Seyin Makinde ninu baalu naa

Oríṣun àwòrán, Seyin Makinde

Baalu ti wọn n lo fun eto aabo lati oju ofurufu ti balẹ siluu Ibadan, nipinlẹ Oyo.

Ọkọ ofurufu meji naa wa lara ileri ti gomina ipinlẹ ọhun, Seyi Makinde ṣe faraalu lori eto aabo.

Ṣaaju ni ariyanjiyan ti kọkọ n waye lori ọrọ baalu naa lẹyin ti Makinde ni ọpọlọpọ owo dọla ni ijọba ra baalu ọhun amọ ti araalu ko ri.

Ọrọ ibi ti baalu naa wa tunbọ fẹ loju si lẹyin iṣẹlẹ ijingbe to waye ni Yawota ati Ahoro Esinele.

Awọn araalu kan sọ lasiko naa pe to ba jẹ pe ijọba ti gbe baalu naa wa ni, yoo rọrun lati tete ṣawari awọn akẹkọọ ati olukọ ti agbesunmọmi ji gbe ni ijọba ibilẹ Oriire.

Bẹẹ lawọn mii n sọ pe irọ ni Makinde n pa ati pe o ti ko owo baalu ọhun sapo ara rẹ.

Ṣugbọn laarin gbas-gbos naa ni gomina Makinde ṣeleri pe awọn baalu ọhun yoo balẹ si ipinlẹ Oyo ko to di opin oṣu Keje ọdun 2026 yii.

Seyi Makinde ti mu ileri rẹ ṣẹ

Baalu naa

Oríṣun àwòrán, Seyin Makinde

Wayi o, ninu atẹjade kan ti kọmiṣọna fun iroyin ni ipinlẹ naa, Dotun Oyelade fi lede, o fidi rẹ mulẹ pe awọn baalu ọhun to de siluu Ibadan.

Oyelade ni pẹlu bi baalu naa ṣe balẹ siluu Ibadan, o n fi han pe Seyi Makinde ti mu ọrọ rẹ ṣẹ lori ọrọ awọn baalu naa.

O ni ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ọdun 2026 yii ni ijọba Oyo ra baalu naa lọna ati mu ki eto abo ipinlẹ Oyo ṣe dede.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ọgba ileeṣẹ ọmọ ogun Nigerian Air Force to wa niluu Eko lawọn baalu naa wa nibi ti wọn ti n to wọn pọ ko to gbera lọ siluu Ibadan.

Ọmọ Ọba Oyelade pari ọrọ rẹ pe baalu ọhun yoo wulo lati ṣe iranlọwọ eto aabo fun awọn ikọ eleto aabo, to fi mọ ikọ Amotekun atawọn ileeṣẹ eto aabo mii nipinlẹ Oyo.