Ìjọba Eko fèsì sí ẹ̀sùn tí obìnrin kan fi kan ilé ìwòsàn Randle nínú fídíò tó gba orí ayélujára

Oríṣun àwòrán, Kafayat Oshodi/TikTok
Ni ibẹrẹ ọsẹ yii ni fidio obinrin kan bẹrẹ gba ori ayelujara eyi to fa oniruuru awuyewuye lori ayelujara.
Ninu fidio naa ni obinrin kan ti fẹsun kan pe wọn pe oun ni owurọ ọjọ naa pe o rẹ ọmọ oun lati ibi iṣẹ ti oun si sare lọ pade wọn nile iwosan ijọba ti wọn gbe ọmọ naa lọ.
O ni nigba ti oun de ile iwosan naa, wọn sọ fun oun pe ọmọ oun nilo lati ṣe ayẹwo eyi to maa na oun ni ẹgbẹrun mẹtala naira eyi ti oun ṣetan lati sọ fun wọn.
O ni iyalẹnu lo je fun oun nigba ti awọn oṣiṣẹ ile iwosan naa ni awọn ko ni gba ki oun fi kaadi ile ifowopamọ oun tabi fi owo naa ranṣẹ lati ori foonu ayafi ti oun ba san kaaṣi fun wọn.
O sọ pe eyi jẹ iyalenu fun oun gidi nitori oun ko mu owo kankan dani bi wọn ṣe pe oun nipe ijaya ati pe kaadi ile ifowopamọ mẹrin lo wa lọwọ oun, ti gbogbo rẹ si lowo lori.
O fi kun pe awọn oṣiṣẹ naa yari lati gba owo naa ayafi igba ti ohun lọ fi ẹgbẹta naira (N600) gba ẹgbẹrun mẹtala naira (N13,000) ni ọdọ oni POS kan to wa ni ẹgbẹ ile iwosan naa.
Obinrin naa kọminu pe owo gegege ni awọn eeyan n san nile iwosan to jẹ ti ijọba, ti wọn ko si ni ṣe nnkan ti eeyan n fẹ fun lasiko.
"Ẹ wo ibi ti ilu yii n lọ, ki n lọ si ile iwosan gbogbogbo ti ijọba, ki wọn maa sọ fun mi pe awọn ko ni gba ki n fi kaadi ile ifowopamọ san owo, ti eeyan ko ba si san owo naa, wọn ko ni tọju alaisan.
"Nibi ti eeyan ba ti n wa kaaṣi kiri, ẹlomii ti wọn gbe de ibẹ bo ṣe maa ku niyẹn."
Obinrin naa wa pe ijọba ipinlẹ Eko si akiyesi pe ki wọn mojuto ile iwosan naa ki awọn araalu le maa gba itọju to peye ni kete ti wọn ba ti debẹ.
Fidio obinrin yii lọ kaakiri ori ayelujara tawọn eeyan si n pe akiyesi ijọba ipinlẹ Eko pe ki wọn ṣe iwadii lori awọn ẹsun ti obinrin naa fi kan.
Yatọ ọrọ ile iwosan, obinrin naa ti kọkọ sọrọ nipa bi awọn kansu ṣe tilẹkun ṣọọbu rẹ ti wọn ko si jẹ ki ọmọ rẹ mu ohun to nilo lati fi lọ kopa nibi idije kan.
Lẹyin fidio naa ni Kọmiṣanna fun eto ere idaraya atawọn ọdọ ipinle Eko ṣabẹwo si obinrin naa.
Ijọba ipinlẹ Eko fesi
Ijọba ipinlẹ Eko ti wa fesi sawọn ẹsun naa bi ileeṣẹ eto ilera ipinlẹ Eko ṣe ni awọn ti ṣe iwadii lori awọn ẹsun ọhun.
Atẹjade kan ti Kọmiṣanna fun eto ilera ipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayomi fi soju opo X rẹ ṣalaye pe ile iwosan gbogbogbo Randle General Hospital ni iṣẹlẹ naa ti waye.
Abayomi ṣalaye ẹka to n ri si ọrọ iya ati ọmọ iyẹn Mother and Child Centre ni ọmọ obinrin naa ti orukọ rẹ n jẹ Alimat ti kọkọ gba itọju yajoyajo ni ọjọ Kẹrin, oṣu kejọ ọdun 2026.
O ni iwadii awọn fidi rẹ mulẹ pe gbogbo itọju ti ọmọ naa gba lasiko naa lo jẹ labẹ eto to wa fun awọn ọmọ ọwọ ati ohun to niiṣe pẹlu oyun inu atawọn ọmọ ọwọ, ti wọn ko sis an owo kankan.
O fi kun pe ọsẹ kan ni Alimat lo nile iwosan naa ti gbogbo owo ilera to gba si jẹ N75,950 amọ to jẹ pe ọfẹ ni wọn gba itọju naa.
O tẹsiwaju pe lọjọ Ketadinlogbọn oṣu Kẹjọ ni Alimat tun pada si ile iwosan lati tẹsiwaju itọju rẹ ati lati ṣe awọn ayẹwo mii.
Kọmiṣanna naa tun ṣalaye pe ẹka to n ri igbayegbadun awọn eeyan lo san ẹgbẹrun marun-un naira ati ẹgbẹrun mẹtala naira lọjọ Kọkanlelọgbọn, to si jẹ pe ẹgberun mẹwaa naira ni iya ọmọ naa san.
O ni ẹgbẹrun mẹwaa naira nikan ni owo ti obinrin naa na ninu apapọ iye owo ti owo itọju wọn jẹ to si jẹ pe ile iwosan lo san N93,950.
O ni ohun to fa ifanfa laaarin awọn oṣiṣẹ ati obinrin naa da lori ẹgbẹrun mẹtala naira to san fun awọn oni POS.
Ọjọgbọn Abayomi ni ileeṣẹ naa Alimat n beere fun ẹgbẹrun mẹtala naira to ti ṣaaju san lẹyin ti ajọ ẹlẹyinju aanu kan fẹ ba a san owo naa ti wọn si sọ fun pe owo ti wọn ba ti san wọle lati ẹka igbayegbadun ko ṣe e da pada mọ labẹ ofin ile iwosan naa.
O fi kun pe iwadii awọn fidi re mulẹ pe gbogbo ilana to ye lati ri daju pe ọda owo ko da awọn eeyan duro lati gba itọju to peye ni wọn lo fun Alimat nigba ti ọmọ naa wa nile iwosan labẹ eto ijọba to n mojuto awujọ.
O ni awọn eto naa lo wa labẹ eto adojutofo ilera Eko, Lagos State Social Health Insurance Programme atawọn eto mii.
Bakan naa lo fi kun pe ileeṣe eto ilera n gbe gbogbo igbesẹ to yẹ lati mu igbooro ba bi awọn eeyan ṣe n san nile iwosan ijọba.
O bu ẹnu atẹ lu bi wọn ṣe n gbe ọrọ naa lori ayelujara bi ẹni pe awọn oṣiṣẹ ile iwosan naa ko tọju ọmọ nitori owo tabi pe awọn oṣiṣẹ gba owo lọna aitọ nile iwosan ọhun.
Ijọba fi kun pe awọn ni ifarajin lati ri daju pe aisi owo ko da awọn eeyan duro lati gba itọju paapaa awọn iṣẹlẹ to ba je pajawiri lawọn ile iwosan ti ijọba kaakiri ipinlẹ Eko.



























